< Job 35 >

1 Moreover Elihu proceeded, and said:
Elihu sì wí pe:
2 Dost thou then think this to be right? Thou hast said, “I am more righteous than God.”
“Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé, òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?
3 For thou askest, “What advantage have I? What have I gained, more than if I had sinned?”
Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò jásí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.
4 I will answer thee, And thy companions with thee.
“Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.
5 Look up to the heavens, and see! And behold the clouds, which are high above thee!
Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.
6 If thou sinnest, what doest thou against Him? If thy transgressions be multiplied, what doest thou to him?
Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí? Tàbí bí ìrékọjá rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?
7 If thou art righteous, what dost thou give him? Or what receiveth he at thy hand?
Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?
8 Thy wickedness injureth only a man like thyself, And thy righteousness profiteth only a son of man.
Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ; òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.
9 The oppressed cry out on account of the multitude of wrongs; They cry aloud on account of the arm of the mighty.
“Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe; wọ́n kígbe nípa apá àwọn alágbára.
10 But none saith, “Where is God, my Maker, Who giveth songs in the night;
Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;
11 Who teacheth us more than the beasts of the earth, And maketh us wiser than the birds of heaven?”
tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’
12 There they cry aloud on account of the pride of the wicked; But he giveth no answer.
Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.
13 For God will not hear the vain supplication, Nor will the Almighty regard it;
Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ asán; bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.
14 Much less when thou sayest thou canst not see him: Justice is with him, —only wait thou for him!
Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ń bẹ níwájú rẹ, ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.
15 But now, because he hath not visited in his anger, Nor taken strict note of transgression,
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nítorí tí ìbínú rẹ̀ kò tí fìyà jẹ ni, òun kò ni ka ìwà búburú si?
16 Therefore hath Job opened his mouth rashly, And multiplied words without knowledge.
Nítorí náà ní Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀ lásán ó sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”

< Job 35 >