< Job 23 >
1 Then Job answered and said:
Ìgbà náà ni Jobu sì dáhùn wí pé,
2 Still is my complaint bitter; But my wound is deeper than my groaning.
“Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò; ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi.
3 O that I knew where I might find him! That I might go before his throne!
Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!
4 I would order my cause before him, And fill my mouth with arguments;
Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀, ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.
5 I should know what he would answer me, And understand what he would say to me.
Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá mi lóhùn; òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi.
6 Would he contend with me with his mighty power? No! he would have regard to me.
Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí? Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi.
7 Then would an upright man contend with him, And I should be fully acquitted by my judge.
Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́, níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé.
8 But, behold, I go eastward, and he is not there; And westward, but I cannot perceive him;
“Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú, òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀.
9 To the north, where he worketh, but I cannot behold him; He hideth himself on the south, and I cannot see him.
Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i, ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.
10 But he knoweth the way which is in my heart; When he trieth me, I shall come forth as gold.
Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀, nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.
11 My feet have trodden in his steps; His way I have kept, and have not turned aside from it.
Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀; ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò.
12 I have not neglected the precepts of his lips; Above my own law have I esteemed the words of his mouth.
Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.
13 But he is of one mind, and who can turn him? And what he desireth, that he doeth.
“Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà? Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.
14 He performeth that which is appointed for me; And many such things are in his mind!
Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe; ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.
15 Therefore I am in terror on account of him; When I consider, I am afraid of him.
Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.
16 For God maketh my heart faint; Yea, the Almighty terrifieth me;
Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà, Olódùmarè sì ń dààmú mi.
17 Because I was not taken away before darkness came, And he hath not hidden darkness from mine eyes.
Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.