< Lamentations 4 >
1 How the gold has become dim. How the most pure gold has changed. The stones of the sanctuary are poured out at the head of every street.
Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù, wúrà dídára di àìdán! Òkúta ibi mímọ́ wá túká sí oríta gbogbo òpópó.
2 The precious sons of Zion, comparable to fine gold, How they are regarded as clay jars, the work of the hands of the potter.
Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye, tí wọ́n fi wúrà dídára ṣe wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!
3 Even the jackals offer the breast, they nurse their young ones, but the daughter of my people has become cruel, like the ostriches in the wilderness.
Àwọn ajáko pèsè ọmú wọn fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn bí ògòǹgò ní aginjù.
4 The nursing infant's tongue sticks to the roof of his mouth for thirst. The young children ask for bread, but no one gives to them.
Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn; àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn.
5 Those who ate delicacies are destitute in the streets. Those who were brought up in purple embrace ash heaps.
Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradára di òtòṣì ní òpópó. Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ ni wọ́n sùn ní orí òkìtì eérú.
6 For the iniquity of the daughter of my people is greater than the sin of Sodom, which was overthrown in an instant, and no hands were laid on her.
Ìjìyà àwọn ènìyàn mi tóbi ju ti Sodomu lọ, tí a sí ní ipò ní òjijì láìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.
7 Her consecrated ones were purer than snow, whiter than milk; their bodies more ruddy than rubies, their appearance was like lapis lazuli.
Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì, wọ́n sì funfun ju wàrà lọ wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa, ìrísí wọn dàbí safire.
8 They appear darker than soot; they are not known in the streets. Their skin cleaves to their bones; it is withered and has become as dry as a stick.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú; wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó. Ara wọn hun mọ́ egungun; ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.
9 Those who are killed with the sword are better than those who are killed with hunger; those who waste away, pierced through, for lack of the fruits of the field.
Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn ju àwọn tí ìyàn pa; tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò fún àìní oúnjẹ láti inú pápá.
10 The hands of the compassionate women have cooked their own children; they were their food in the destruction of the daughter of my people.
Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú ni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹ tí ó di oúnjẹ fún wọn nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.
11 YHWH has accomplished his wrath, he has poured out his fierce anger; he has kindled a fire in Zion, which has devoured its foundations.
Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀; ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde. Ó da iná ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.
12 The kings of the earth did not believe, neither all the inhabitants of the world, that the adversary or the enemy would enter into the gates of Jerusalem.
Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́, tàbí àwọn ènìyàn ayé, wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ odi ìlú Jerusalẹmu.
13 It is because of the sins of her prophets, and the iniquities of her priests, that have shed the blood of the just in the midst of her.
Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì àti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà, tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàrín rẹ̀.
14 They wander as blind men in the streets, they are polluted with blood, so that men can't touch their garments.
Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó bí ọkùnrin tí ó fọ́jú. Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.
15 "Go away." they cried to them, "Unclean. Away, away. Do not touch." When they fled away and wandered, men said among the nations, "They shall not live here anymore."
“Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn. “Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!” Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé, “Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”
16 YHWH himself has scattered them; he will no more regard them. They did not respect the priests, they did not favor the elders.
Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀; kò sí bojútó wọn mọ́. Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́, àti àánú fún àwọn àgbàgbà.
17 Our eyes still fail, looking in vain for our help. In our watching we have watched for a nation that could not save.
Síwájú sí i, ojú wa kùnà fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán; láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.
18 They hunt our steps, so that we can't go in our streets. Our end is near, our days are fulfilled; for our end has come.
Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri, àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́. Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye nítorí òpin wa ti dé.
19 Our pursuers were swifter than the eagles of the sky. They chased us on the mountains, they lay in wait for us in the wilderness.
Àwọn tí ń lé wa yára ju idì ojú ọ̀run lọ; wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkè wọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní aginjù.
20 The breath of our nostrils, the anointed of YHWH, was taken in their pits; of whom we said, "Under his shadow we can live among the nations."
Ẹni àmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa, ni wọ́n fi tàkúté wọn mú. Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.
21 Rejoice and be glad, daughter of Edom, that dwell in the land of Uz. The cup shall pass through to you also; you will get drunk, and shall make yourself naked.
Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Edomu, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Usi. Ṣùgbọ́n, a ó gbé ago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú; ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòhò.
22 The punishment of your iniquity is accomplished, daughter of Zion; he will no more carry you away into captivity. He will visit your iniquity, daughter of Edom; he will uncover your sins.
Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin; kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yà yóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.