< Job 4 >
1 Then Eliphaz the Temanite answered,
Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani dáhùn wí pé,
2 "If someone ventures to talk with you, will you be grieved? But who can withhold himself from speaking?
“Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́? Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ?
3 Look, you have instructed many, you have strengthened the weak hands.
Kíyèsi i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.
4 Your words have supported him who was falling, You have made firm the feeble knees.
Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró, ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.
5 But now it is come to you, and you faint. It touches you, and you are troubled.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́; ara rẹ kò lélẹ̀.
6 Isn't your piety your confidence? Isn't the integrity of your ways your hope?
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?
7 "Remember, now, whoever perished, being innocent? Or where were the upright cut off?
“Èmi bẹ̀ ọ́ rántí, ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀? Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí?
8 According to what I have seen, those who plow iniquity, and sow trouble, reap the same.
Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.
9 By the breath of God they perish. By the blast of his anger are they consumed.
Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé, nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.
10 The roaring of the lion, and the voice of the fierce lion, the teeth of the young lions, are broken.
Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnnìún àti eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún ní a ká.
11 The old lion perishes for lack of prey. The cubs of the lioness are scattered abroad.
Kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ, àwọn ẹgbọrọ kìnnìún sísanra ni a túká kiri.
12 "Now a thing was secretly brought to me. My ear received a whisper of it.
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí a fi ohun àṣírí kan hàn fún mi, etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀.
13 In thoughts from the visions of the night, when deep sleep falls on men,
Ní ìrò inú lójú ìran òru, nígbà tí oorun èjìká kùn ènìyàn.
14 fear came on me, and trembling, which made all my bones shake.
Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrì tí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé.
15 Then a spirit passed before my face. The hair of my flesh stood up.
Nígbà náà ni ẹ̀mí kan kọjá lọ ní iwájú mi, irun ara mi dìde dúró ṣánṣán.
16 It stood still, but I couldn't discern its appearance. A form was before my eyes. Silence, then I heard a voice, saying,
Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀, àwòrán kan hàn níwájú mi, ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé,
17 'Shall mortal man be more just than God? Shall a man be more pure than his Maker?
‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run, ènìyàn ha le mọ́ ju ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?
18 Look, he puts no trust in his servants. He charges his angels with error.
Kíyèsi i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, nínú àwọn angẹli rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀.
19 How much more, those who dwell in houses of clay, whose foundation is in the dust, who are crushed before the moth.
Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀, ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀ tí yóò di rírun kòkòrò.
20 Between morning and evening they are destroyed. They perish forever without any regarding it.
A pa wọ́n run láàrín òwúrọ̀ àti àṣálẹ́ wọ́n sì parun títí láé, láìrí ẹni kà á sí.
21 Isn't their tent cord plucked up within them? They die, and that without wisdom.'
A kò ha ké okùn iye wọ́n kúrò bí? Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’