< Job 11 >

1 Then Zophar, the Naamathite, answered,
Ìgbà náà ni Sofari, ará Naama, dáhùn, ó sì wí pé,
2 "Shouldn't the multitude of words be answered? Should a man full of talk be justified?
“A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀? A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?
3 Should your boastings make men hold their peace? When you mock, shall no man make you ashamed?
Ṣé àmọ̀tán rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí? Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?
4 For you say, 'My doctrine is pure. I am clean in your eyes.'
Ìwọ sá à ti wí fún Ọlọ́run pé, ‘Ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní ojú rẹ.’
5 But oh that God would speak, and open his lips against you,
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀, kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ
6 that he would show you the secrets of wisdom. For true wisdom has two sides. Know therefore that God exacts of you less than your iniquity deserves.
kí ó sì fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ, nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.
7 "Can you fathom the mystery of God? Or can you probe the limits of Shaddai?
“Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí? Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olódùmarè dé bi?
8 They are high as heaven. What can you do? They are deeper than Sheol. What can you know? (Sheol h7585)
Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe? Ó jìn ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀? (Sheol h7585)
9 Its measure is longer than the earth, and broader than the sea.
Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ, ó sì ní ibú ju òkun lọ.
10 If he passes by, or confines, or convenes a court, then who can oppose him?
“Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sé ọnà tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdájọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?
11 For he knows false men. He sees iniquity also, even though he doesn't consider it.
Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn; àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?
12 An empty-headed man becomes wise when a man is born as a wild donkey's colt.
Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn.
13 "If you set your heart aright, stretch out your hands toward him.
“Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un, tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,
14 If iniquity is in your hand, put it far away. Do not let unrighteousness dwell in your tents.
bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ,
15 Surely then you shall lift up your face without spot; Yes, you shall be steadfast, and shall not fear:
nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù.
16 for you shall forget your misery. You shall remember it as waters that are passed away.
Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ; ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ.
17 Life shall be clearer than the noonday. Though there is darkness, it shall be as the morning.
Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ, bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.
18 You shall be secure, because there is hope. Yes, you shall search, and shall take your rest in safety.
Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà; àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
19 Also you shall lie down, and none shall make you afraid. Yes, many shall court your favor.
Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́, àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ.
20 But the eyes of the wicked shall fail. They shall have no way to flee. Their hope shall be the giving up of the spirit."
Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo; gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n, ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”

< Job 11 >