< 2 Timothy 2 >

1 You therefore, my child, be strengthened in the grace that is in Christ Jesus.
Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu.
2 The things which you have heard from me among many witnesses, commit the same to faithful people, who will be able to teach others also.
Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòtítọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.
3 You therefore must share in hardship, as a good soldier of Christ Jesus.
Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi.
4 No soldier on duty entangles himself in the affairs of life, that he may please him who enrolled him as a soldier.
Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn.
5 Also, if anyone competes in athletics, he is not crowned unless he has competed by the rules.
Ní ọ̀nà kan náà, bí ẹnikẹ́ni bá sì ń díje bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà
6 The farmers who labor must be the first to get a share of the crops.
Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso.
7 Consider what I say, for the Lord will give you understanding in all things.
Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo.
8 Remember Jesus Christ, risen from the dead, a descendant of David, according to my Good News,
Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi.
9 in which I suffer hardship to the point of chains as a criminal. But God's word is not chained.
Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
10 Therefore I endure all things for the chosen ones' sake, that they also may obtain the salvation which is in Christ Jesus with everlasting glory. (aiōnios g166)
Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé. (aiōnios g166)
11 This saying is faithful: "For if we died with him, we will also live with him.
Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bi àwa bá bá a kú, àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.
12 If we endure, we will also reign with him. If we deny him, he also will deny us.
Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jẹ ọba. Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa.
13 If we are faithless, he remains faithful, for he cannot deny himself."
Bí àwa kò bá gbàgbọ́, òun dúró ni olóòtítọ́, nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.
14 Remind them of these things, charging them in the presence of God, not to wrangle about words, to no profit, to the subverting of those who hear.
Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́.
15 Do your best to present yourself approved by God, a worker who does not need to be ashamed, properly handling the word of truth.
Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ.
16 But shun empty chatter, for they will proceed further in ungodliness,
Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí tiwọn máa síwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run.
17 and their word will consume like gangrene, of whom is Hymenaeus and Philetus;
Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀; nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Filetu wà;
18 who have erred concerning the truth, saying that the resurrection is already past, and overthrowing the faith of some.
àwọn ẹni tí ó ti ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú.
19 However God's firm foundation stands, having this seal, "The Lord knows those who are his," and, "Let every one who names the name of the Lord depart from unrighteousness."
Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, “Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúrò nínú àìṣòdodo.”
20 Now in a large house there are not only vessels of gold and of silver, but also of wood and of clay. Some are for honor, and some for dishonor.
Ṣùgbọ́n nínú ilé ńlá, kì í ṣe kìkì ohun èlò wúrà àti ti fàdákà nìkan ni ń bẹ, ṣùgbọ́n ti igi àti amọ̀ pẹ̀lú; àti òmíràn sí ọlá, àti òmíràn sí àìlọ́lá.
21 If anyone therefore purges himself from these, he will be a vessel for honor, sanctified, and suitable for the master's use, prepared for every good work.
Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.
22 Flee from youthful lusts; but pursue righteousness, faith, love, and peace with those who call on the Lord out of a pure heart.
Máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èwe, sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá.
23 But refuse foolish and ignorant questionings, knowing that they generate strife.
Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní ẹ̀kọ́ nínú ni kí o kọ̀, bí o ti mọ̀ pe wọn máa dá ìjà sílẹ̀.
24 The Lord's servant must not quarrel, but be gentle towards all, able to teach, patient,
Ìránṣẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, àti onísùúrù.
25 in gentleness correcting those who oppose him: perhaps God may give them repentance leading to a full knowledge of the truth,
Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrètí pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtítọ́,
26 and they may recover themselves out of the devil's snare, having been taken captive by him to his will.
wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdẹ̀kùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

< 2 Timothy 2 >