< Ezekiel 45 >

1 "'Moreover, when you shall divide by lot the land for inheritance, you shall offer an offering to the LORD, a holy portion of the land; the length shall be the length of eight and one eighth miles, and the breadth shall be six and a half miles. It shall be holy in all its border all around.
“‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ibi mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú; gbogbo agbègbè rẹ̀ yíká ni yóò jẹ́ mímọ́.
2 Of this there shall be for the holy place eight hundred sixty-one feet three inches in length by eight hundred sixty-one feet three inches in breadth, square all around; and eighty-six feet two inches for its suburbs all around.
Lára inú èyí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta yóò jẹ́ ti ibi mímọ́ ní gígùn, pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ní ìbú, ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yíká, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún gbangba rẹ̀ yíká.
3 Of this measure you shall measure a length of twenty-five thousand, and a breadth of ten thousand: and in it shall be the sanctuary, which is most holy.
Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ìbú. Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa yóò wà, ìyẹn Ibi Mímọ́ Jùlọ.
4 It is a holy portion of the land; it shall be for the priests, the ministers of the sanctuary, who come near to minister to the LORD; and it shall be a place for their houses, and a holy place for the sanctuary.
Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa.
5 Eight and one eighth miles in length, and three and one quarter miles in breadth, shall be to the Levites, the ministers of the house. It will be their possession for cities to live in.
Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ìbú yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.
6 "'You shall appoint the possession of the city one and two-thirds miles broad, and eight and one eighth miles, long, side by side with the offering of the holy portion: it shall be for the whole house of Israel.
“‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Israẹli.
7 "'Whatever is for the prince shall be on the one side and on the other side of the holy offering and of the possession of the city, in front of the holy offering and in front of the possession of the city, on the west side westward, and on the east side eastward; and in length answerable to one of the portions, from the west border to the east border.
“‘Àwọn ọmọ-aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbègbè tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú. Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn láti apá ìwọ̀-oòrùn àti si ìlà-oòrùn, láti apá ìlà-oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀-oòrùn sí ààlà ìlà-oòrùn, ti ìṣe déédé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà.
8 In the land it shall be to him for a possession in Israel: and my princes shall no more oppress my people; but they shall give the land to the house of Israel according to their tribes.'
Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Israẹli. Àwọn ọmọ-aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Israẹli gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.
9 "Thus says the LORD: 'Let it suffice you, princes of Israel: remove violence and spoil, and execute justice and righteousness; dispossessing my people, says the LORD.
“‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí.
10 You shall have just balances, and a just ephah, and a just bath.
Kí ẹ̀yin kì ó lo òsùwọ̀n tó tọ́ àti efa títọ́ àti bati títọ́.
11 The ephah and the bath shall be of one measure, that the bath may contain the tenth part of a homer, and the ephah the tenth part of a homer: its measure shall be after the homer.
Efa àti bati gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bati tí ó gba ìdámẹ́wàá homeri, àti efa ìdámẹ́wàá homeri: Homeri ni kí ó jẹ́ òsùwọ̀n tí ẹ̀yin yóò lò fún méjèèjì.
12 The shekel shall be twenty gerahs. Twenty shekels plus twenty-five shekels plus fifteen shekels shall be your mina.
Ṣékélì ní kí o gba ogún gera. Ogún ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yóò jẹ́ mina kan.
13 "'This is the offering that you shall offer: the sixth part of an ephah from a homer of wheat; and you shall give the sixth part of an ephah from a homer of barley;
“‘Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí ẹ gbọdọ̀ ṣe: efa kẹfà láti inú homeri ọkà kọ̀ọ̀kan àti efa kẹfà láti inú homeri barle kọ̀ọ̀kan.
14 and the set portion of oil, of the bath of oil, the tenth part of a bath out of the cor, which is ten baths, even a homer; (for ten baths are a homer; )
Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bati wọ́n, ni ìdámẹ́wàá bati láti inú kórì (èyí tí ó gba ìdámẹ́wàá bati tàbí homeri kan, fún ìdámẹ́wàá bati jẹ́ bákan náà sì homeri kan).
15 and one lamb of the flock, out of two hundred, from the well-watered pastures of Israel—for a meal offering, and for a burnt offering, and for peace offerings, to make atonement for them, says the LORD.
Bákan náà ni ọ̀dọ́-àgùntàn kan láti inú agbo ẹran, láti inú igba, láti inú pápá oko tútù Israẹli, fún ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti fún ọrẹ ẹbọ sísun, àti fún ọrẹ ẹbọ ìdúpẹ́ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Olódùmarè wí.
16 All the people of the land shall give to this offering for the prince in Israel.
Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ-aládé ni Israẹli.
17 It shall be the prince's part to give the burnt offerings, and the meal offerings, and the drink offerings, in the feasts, and on the new moons, and on the Sabbaths, in all the appointed feasts of the house of Israel: he shall prepare the sin offering, and the meal offering, and the burnt offering, and the peace offerings, to make atonement for the house of Israel.
Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ-aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àsè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ́ ìsinmi ni gbogbo àjọ̀dún tí a yàn ní ilé Israẹli. Òun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Israẹli.
18 "'Thus says the LORD: In the first month, in the first day of the month, you shall take a young bull without blemish; and you shall cleanse the sanctuary.
“‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́.
19 The priest shall take of the blood of the sin offering, and put it on the door posts of the house, and on the four corners of the ledge of the altar, and on the posts of the gate of the inner court.
Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ìlẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú.
20 So you shall do on the seventh day of the month for everyone who errs, and for him who is simple: so you shall make atonement for the house.
Ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ọjọ́ keje oṣù fún àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá tàbí nínú àìmọ̀kan; nítorí náà, ìwọ yóò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ilé Ọlọ́run.
21 "'In the first month, in the fourteenth day of the month, you shall have the Passover, a feast of seven days; unleavened bread shall be eaten.
“‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àsè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà.
22 On that day shall the prince prepare for himself and for all the people of the land a bull for a sin offering.
Ní ọjọ́ náà ní ọmọ-aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà.
23 The seven days of the feast he shall prepare a burnt offering to the LORD, seven bulls and seven rams without blemish daily the seven days; and a male goat daily for a sin offering.
Ní ojoojúmọ́ ni àárín ọjọ́ méje àsè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
24 He shall prepare a meal offering, an ephah for a bull, and an ephah for a ram, and a hin of oil to an ephah.
Òun yóò sì pèsè efa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Efa kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti efa kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hínì òróró kan fún efa kan.
25 In the seventh month, in the fifteenth day of the month, in the feast, shall he do the like the seven days; according to the sin offering, according to the burnt offering, and according to the meal offering, and according to the oil.'
“‘Láàrín ọjọ́ méje àsè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, òun yóò tún pèsè ohun kan náà fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ, àti fún òróró.

< Ezekiel 45 >