< Psalms 80 >
1 [For the Chief Musician. To the tune of "The Lilies of the Covenant." A Psalm by Asaph.] Hear us, Shepherd of Israel, you who lead Joseph like a flock, you who sit above the cherubim, shine forth.
Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì Ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu. Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli; ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran. Ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
2 Before Ephraim and Benjamin and Manasseh, stir up your might. Come to save us.
níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase. Ru agbára rẹ̀ sókè; wá fún ìgbàlà wa.
3 Restore us, God. Cause your face to shine, and we will be saved.
Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run; jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí a bá à lè gbà wá là.
4 LORD God of hosts, How long will you be angry against the prayer of your people?
Olúwa Ọlọ́run alágbára, ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
5 You have fed them with the bread of tears, and given them tears to drink in large measure.
Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
6 You make us a source of contention to our neighbors. Our enemies have mocked us.
Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
7 Restore us, God of hosts. Cause your face to shine, and we will be saved.
Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára; jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa, kí a ba à lè gbà wá là.
8 You brought a vine out of Egypt. You drove out the nations, and planted it.
Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti; ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
9 You cleared the ground for it. It took deep root, and filled the land.
Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un, ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀ ó sì kún ilẹ̀ náà.
10 The mountains were covered with its shadow. Its boughs were like God's cedars.
A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
11 It sent out its branches to the sea, Its shoots to the River.
O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun, ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
12 Why have you broken down its walls, so that all those who pass by the way pluck it?
Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀ tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
13 The boar out of the wood ravages it. The wild animals of the field feed on it.
Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́ àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
14 Return, we beg you, God of hosts. Look down from heaven, and see, and visit this vine,
Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára! Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó! Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
15 the stock which your right hand planted, the branch that you made strong for yourself.
gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn, àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
16 It's burned with fire. It's cut down. They perish at your rebuke.
A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún; ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.
17 Let your hand be on the man of your right hand, on the son of man whom you made strong for yourself.
Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18 So we will not turn away from you. Revive us, and we will call on your name.
Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ; mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
19 Restore us, LORD God of hosts. Cause your face to shine, and we will be saved.
Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára; kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí á ba à lè gbà wá là.