< Nehemiah 12 >
1 Now these are the priests and the Levites who went up with Zerubbabel the son of Shealtiel, and Jeshua: Seraiah, Jeremiah, Ezra,
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tí ó bá Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua padà: Seraiah, Jeremiah, Esra,
2 Amariah, Malluch, Hattush,
Amariah, Malluki, Hattusi,
3 Shecaniah, Rehum, Meremoth,
Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti,
4 Iddo, Ginnethon, Abijah,
Iddo, Ginetoni, Abijah,
5 Mijamin, Maadiah, Bilgah,
Mijamini, Moadiah, Bilgah,
6 Shemaiah, and Joiarib, Jedaiah.
Ṣemaiah, Joiaribu, Jedaiah,
7 Sallu, Amok, Hilkiah, Jedaiah. These were the chiefs of the priests and of their brothers in the days of Jeshua.
Sallu, Amoki, Hilkiah, àti Jedaiah. Wọ̀nyí ni olórí àwọn àlùfáà àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn ní ìgbà ayé e Jeṣua.
8 Moreover the Levites: Jeshua, Binnui, Kadmiel, Sherebiah, Judah, and Mattaniah, who was over the thanksgiving, he and his brothers.
Àwọn ọmọ Lefi ni Jeṣua, Binnui, Kadmieli, Ṣerebiah, Juda àti Mattaniah ẹni tí òun pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ni wọn ṣe àkóso orin ìdúpẹ́.
9 Also Bakbukiah and Unni, their brothers, were over against them according to their offices.
Bakbukiah àti Unni, àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró sí òdìkejì wọn nínú ìsìn.
10 Jeshua became the father of Joiakim, and Joiakim became the father of Eliashib, and Eliashib became the father of Joiada,
Jeṣua ni baba Joiakimu, Joiakimu ni baba Eliaṣibu, Eliaṣibu ni baba Joiada,
11 and Joiada became the father of Jonathan, and Jonathan became the father of Jaddua.
Joiada ni baba Jonatani, Jonatani sì ni baba Jaddua.
12 In the days of Joiakim were priests, heads of ancestral houses: of Seraiah, Meraiah; of Jeremiah, Hananiah;
Ní ìgbé ayé Joiakimu, wọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn àlùfáà: ti ìdílé Seraiah, Meraiah; ti ìdílé Jeremiah, Hananiah;
13 of Ezra, Meshullam; of Amariah, Jehohanan;
ti ìdílé Esra, Meṣullamu; ti ìdílé Amariah, Jehohanani;
14 of Malluch, Jonathan; of Shecaniah, Joseph;
ti ìdílé Malluki, Jonatani; ti ìdílé Ṣekaniah, Josẹfu;
15 of Harim, Adna; of Meremoth, Helkai;
ti ìdílé Harimu, Adna; ti ìdílé Meraioti Helikai;
16 of Iddo, Zechariah; of Ginnethon, Meshullam;
ti ìdílé Iddo, Sekariah; ti ìdílé Ginetoni, Meṣullamu;
17 of Abijah, Zikri; of Minjamin, of Moadiah, Piltai;
ti ìdílé Abijah, Sikri; ti ìdílé Miniamini àti ti ìdílé Moadiah, Piltai;
18 of Bilgah, Shammua; of Shemaiah, Jehonathan;
ti ìdílé Bilgah, Ṣammua; ti ìdílé Ṣemaiah, Jehonatani;
19 and of Joiarib, Mattenai; of Jedaiah, Uzzi;
ti ìdílé Joiaribu, Mattenai; ti ìdílé Jedaiah, Ussi;
20 of Sallu, Kallai; of Amok, Eber;
ti ìdílé Sallu, Kallai; ti ìdílé Amoki, Eberi;
21 of Hilkiah, Hashabiah; of Jedaiah, Nethanel.
ti ìdílé Hilkiah, Haṣabiah; ti ìdílé Jedaiah, Netaneli.
22 As for the Levites, in the days of Eliashib, Joiada, and Johanan, and Jaddua, there were recorded the heads of ancestral houses; also the priests, in the reign of Daryavesh the Persian.
Àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Lefi ní ìgbà ayé Eliaṣibu, Joiada, Johanani àti Jaddua, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dariusi ará Persia.
23 The sons of Levi, heads of ancestral houses, were written in the scroll of the chronicles, even until the days of Johanan the son of Eliashib.
Àwọn olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Lefi títí di àkókò Johanani ọmọ Eliaṣibu ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn.
24 The chiefs of the Levites: Hashabiah, Sherebiah, and Jeshua the son of Kadmiel, with their brothers over against them, to praise and give thanks, according to the commandment of David the man of God, watch next to watch.
Àti àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi ni Haṣabiah, Ṣerebiah, Jeṣua ọmọ Kadmieli, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojú wọn láti fi ìyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi ènìyàn Ọlọ́run.
25 Mattaniah, and Bakbukiah, Obadiah, Meshullam, Talmon, Akkub, were gatekeepers keeping the watch at the storehouses of the gates.
Mattaniah, Bakbukiah, Obadiah, Meṣullamu, Talmoni àti Akkubu ni aṣọ́nà tí wọ́n ń sọ yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ní ẹnu-ọ̀nà.
26 These were in the days of Joiakim the son of Jeshua, the son of Jozadak, and in the days of Nehemiah the governor, and of Ezra the priest the scribe.
Wọ́n ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìgbà ayé e Joiakimu ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, àti ní ọjọ́ ọ Nehemiah baálẹ̀ àti ní ọjọ́ Esra àlùfáà àti akọ̀wé.
27 At the dedication of the wall of Jerusalem they sought the Levites out of all their places, to bring them to Jerusalem, to keep the dedication with gladness, both with giving thanks, and with singing, with cymbals, stringed instruments, and with harps.
Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jerusalẹmu a mú àwọn ọmọ Lefi jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin kimbali, haapu àti ohun èlò orin olókùn.
28 The sons of the singers gathered themselves together, both out of the plain around Jerusalem, and from the villages of the Netophathites;
A kó àwọn akọrin náà jọ papọ̀ láti àwọn ìletò tí ó yí Jerusalẹmu náà ká—láti àwọn abúlé Netofa,
29 also from Beth Gilgal, and out of the fields of Geba and Azmaveth: for the singers had built them villages around Jerusalem.
láti Beti-Gilgali, àti láti àwọn agbègbè Geba àti Asmafeti, nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ìletò fúnra wọn ní agbègbè Jerusalẹmu.
30 The priests and the Levites purified themselves; and they purified the people, and the gates, and the wall.
Nígbà tí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ya àwọn ènìyàn sí mímọ́, àti ẹnu ibodè àti odi pẹ̀lú.
31 Then I brought up the leaders of Judah onto the wall, and appointed two great companies who gave thanks and went in procession. One went on the right hand on the wall toward the Dung Gate;
Mo sì tún yan àwọn olórí Juda láti gun orí odi náà. Mo sì tún yan àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì láti dúpẹ́. Àwọn kan yóò gòkè odi lọ sí apá ọ̀tún sí ọ̀nà ibodè Ààtàn.
32 and after them went Hoshaiah, and half of the leaders of Judah,
Hoṣaiah àti ìdajì àwọn olórí Juda tẹ̀lé wọn,
33 and Azariah, Ezra, and Meshullam,
àwọn wọ̀nyí náà sì lọ pẹ̀lú wọn, Asariah, Esra, Meṣullamu,
34 Judah, and Benjamin, and Shemaiah, and Jeremiah,
Juda, Benjamini, Ṣemaiah, Jeremiah,
35 and certain of the priests' sons with trumpets: Zechariah the son of Jonathan, the son of Shemaiah, the son of Mattaniah, the son of Micaiah, the son of Zakkur, the son of Asaph;
pẹ̀lú àwọn àlùfáà díẹ̀ pẹ̀lú ìpè, pẹ̀lú u Sekariah ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mikaiah, ọmọ Sakkuri, ọmọ Asafu,
36 and his brothers, Shemaiah, and Azarel, Milalai, Gilalai, Maai, Nethanel, and Judah, Hanani, with the musical instruments of David the man of God; and Ezra the scribe was before them.
àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Ṣemaiah, Asareeli, Milalai, Gilalai, Maai, Netaneli, Juda àti Hanani—pẹ̀lú ohun èlò orin bí àṣẹ Dafidi ènìyàn Ọlọ́run. Esra akọ̀wé ni ó ṣáájú wọn bí wọ́n ti ń tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́.
37 By the Fountain Gate, and straight before them, they went up by the stairs of the City of David, at the ascent of the wall, above the house of David, even to the Water Gate eastward.
Ní ẹnu ibodè orísun wọ́n ti ń lọ tààrà sí ọ̀nà ní orí àtẹ̀gùn ìlú Dafidi ní orí òkè tí ó kángun sí odi, wọ́n sì gba ẹ̀gbẹ́ ilé Dafidi kọjá títí dé ẹnu ibodè omi ní ìhà ìlà-oòrùn.
38 The other company of those who gave thanks went to meet them, and I after them, with the half of the people, on the wall, above the Tower of the Ovens, to the Broad Wall,
Àwọn ẹgbẹ́ akọrin kejì gba ọ̀nà òdìkejì lọ. Mo tẹ̀lé wọn ní orí odi, pẹ̀lú ìdajì àwọn ènìyàn, kọjá ilé ìṣọ́ ìléru lọ sí odi fífẹ̀,
39 and above the Ephraim Gate, and by the Jeshanah Gate, and by the Fish Gate, and the Tower of Hananel, and the Tower of the Hundred, and as far as the Sheep Gate. And they stood still in the Gate of the Guard.
kọjá ẹnu ibodè Efraimu ibodè Jeṣana, ẹnu ibodè ẹja, ilé ìṣọ́ Hananeli àti ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn-ún, títí dé ẹnu ibodè àgùntàn. Wọ́n sì dúró ní ibodè ìṣọ́.
40 So stood the two companies of those who gave thanks in God's house, and I, and the half of the rulers with me;
Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè,
41 and the priests, Eliakim, Maaseiah, Miniamin, Micaiah, Elioenai, Zechariah, and Hananiah, with trumpets;
àti àwọn àlùfáà Eliakimu, Maaseiah, Miniamini, Mikaiah, Elioenai, Sekariah àti Hananiah pẹ̀lú àwọn ìpè wọn.
42 and Maaseiah, and Shemaiah, and Eleazar, and Uzzi, and Jehohanan, and Malchijah, and Elam, and Ezer. The singers sang loud, with Jezrahiah their overseer.
Àti pẹ̀lú Maaseiah, Ṣemaiah, Eleasari àti Ussi, àti Jehohanani, àti Malkiah, àti Elamu, àti Eseri. Àwọn akọrin kọrin sókè ní abẹ́ alábojútó Jesrahiah.
43 They offered great sacrifices that day, and rejoiced; for God had made them rejoice with great joy; and the women also and the children rejoiced: so that the joy of Jerusalem was heard even afar off.
Ní ọjọ́ náà wọ́n rú ẹbọ ńlá, wọ́n ṣe àjọyọ̀ nítorí Ọlọ́run ti fún wọn ní ayọ̀ ńlá. Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sì yọ̀ pẹ̀lú. A lè gbọ́ ariwo ayọ̀ tí ó jáde láti Jerusalẹmu ní jìnnà réré.
44 On that day men were appointed over the storerooms, for the contributions, the first fruits, and the tithes, to gather into them from the fields of the cities the portions appointed by the law for the priests and Levites, for Judah rejoiced over the priests and the Levites who ministered.
Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìṣúra fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìṣúra, ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, nítorí inú àwọn ará a Juda yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́.
45 They performed the duty of their God, and the duty of the purification, and so did the singers and the gatekeepers, according to the commandment of David, and of Solomon his son.
Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Dafidi àti Solomoni ọmọ rẹ̀ ti pàṣẹ fún wọn.
46 For long ago in the days of David and Asaph there were directors of the singers and songs of praise and thanksgiving to God.
Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn ní ìgbà Dafidi àti Asafu, ni àwọn atọ́nisọ́nà ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.
47 All Israel in the days of Zerubbabel, and in the days of Nehemiah, gave the portions of the singers and the gatekeepers, as every day required: and they set apart that which was for the Levites; and the Levites set apart that which was for the sons of Aaron.
Nítorí náà ní ìgbà ayé Serubbabeli àti Nehemiah, gbogbo Israẹli ni ó ń dá ìpín lójoojúmọ́ fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà. Wọ́n sì tún yan ìpín mìíràn sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi tókù, àwọn ọmọ Lefi náà tún ya ìpín ti àwọn ọmọ Aaroni sọ́tọ̀ fún wọn.