< Revelation 14 >
1 And I looked, and lo, there was the Lamb standing on Mount Zion, and with were a hundred and forty and four thousand who had his name and his Father’s name written on their foreheads.
Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.
2 And I heard a voice from heaven like the voice of many waters, and the voice of a great thunder; and I heard the voice of harpers harping on their harps.
Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá, mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù.
3 They were singing a new song before the throne, and before the four Living Creatures and the Elders; and none can learn that song, except the one hundred and forty and four thousand, who had been redeemed from the earth.
Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ náà, àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin n nì àti àwọn àgbà náà, kò sì ṣí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá.
4 These are they who were not defiled with women; for they are celibates. They follow the Lamb wherever he goes. They have been redeemed from among men to be the first-fruits unto God and the Lamb.
Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí, nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.
5 No lie was ever found on their lips; they are spotless.
A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.
6 Then I saw another angel who was flying in mid-heaven. He had an eternal evangel, to evangelize all the dwellers on the earth, of every nation and tribe and tongue and people. (aiōnios )
Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìyìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. (aiōnios )
7 And he cried with a loud voice. "Fear God and give him glory, Because the hour of his judgment is come. And worship Him who made the heavens and the earth And the sea and springs of waters."
Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”
8 Then a second angel followed, crying, "Fallen, fallen is Babylon the Great, Who has made all the nations drink the wine Of the frenzy of her fornication."
Angẹli mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “o ṣubú, Babeli ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”
9 And another angel, a third, followed them, crying with a mighty voice. "Whoever worships the beast and his image, And receives a brand on his forehead or on his hand,
Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀.
10 He also shall drink of the wine of the wrath of God, Poured out unmixed in the cup of his anger; And he shall be tormented with fire and brimstone In the presence of the holy angels, And in the presence of the Lamb,
Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn.
11 And the smoke of their torment ascends forever and ever; And they have no rest day or night, Who worship the beast and his image, And all who receive the brand of his name." (aiōn )
Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.” (aiōn )
12 Here is the endurance of the saints, those who keep the commandments of God, and the faith of Jesus.
Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.
13 And I heard a voice from heaven, saying, "Write, Blessed are the dead that die in the Lord from henceforth! Yea, says the Spirit, that they may rest from their labors, For their deeds do follow them."
Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.” Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”
14 And I looked, and lo, a white cloud; and on the cloud I saw One sitting like to a son of man, with a golden crown on his head, and a sharp sickle in his hand.
Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀.
15 And another angel came out of the temple, shouting with a loud voice to him who sat on the cloud. "Thrust in your sickle, and reap; for the time to reap is come. The harvest of the earth is overripe."
Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.”
16 And he who sat on the cloud thrust in his sickle upon the earth; and the earth was reaped.
Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.
17 And another angel came out of the temple which is in heaven, and he, too, had a sharp sickle.
Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan.
18 And another angel came from the altar, the angel who has power over fire, and he called with a loud voice to the one who had the sharp sickle, saying, "Thrust in your sharp sickle, And gather the clusters of the vine of the earth, For its grapes are fully ripe."
Angẹli mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ́ àwọn ìdì àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.”
19 So the angel thrust his sickle into the earth and gathered the clusters of the vine of the earth, and threw them into the winepress, the great winepress of the wrath of God.
Angẹli náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ̀ ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntí, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run.
20 And the winepress was trodden outside the city, and blood gushed out of the winepress, even to the bridles of the horses, as far as two hundred miles.
A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀.