< 2 Corinthians 3 >
1 Am I beginning again to "recommend" myself? Or do I need, as some do, letters of commendation either to you or from you?
Àwa ha tún bẹ̀rẹ̀ láti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí láti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe?
2 You are my letter, written on my heart, known and read by all men.
Ẹ̀yin fúnra yín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà.
3 Since all can see that you are a letter of Christ transcribed by men, written not with ink, but with the Spirit of the living God, not on tablets of stone, but on human hearts as tablets.
Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran.
4 Such confidence I have through Christ before God.
Irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni àwa ní nípasẹ̀ Kristi sọ́dọ̀ Ọlọ́run,
5 Not that I am sufficient in myself to reach any conclusion in my own wisdom; but my sufficiency is from God.
kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ àwa tìkára wa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà,
6 It is he who has also made me sufficient as a minister of a new covenant; not of a letter but of a spirit; for the letter kills, but the spirit makes alive.
Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.
7 If, however, the administration of death, written with letters and engraved on stones, began in glory, so that the children of Israel could not gaze steadily on the face of Moses, because of the glory of his face - a glory even then fading -
Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ);
8 how much more shall the ministry of the Spirit abide in glory?
yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù?
9 For if the ministry of condemnation had glory, far more is the ministry of righteousness radiant in glory.
Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.
10 Indeed that which once was glorious has lost its glory, because of the glory which surpasses it.
Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ.
11 For if that which was fading came in glory, far more will that which ever abides be glorious.
Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!
12 Therefore, cherishing such a hope, I use great freedom of speech.
Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀.
13 I do not do as Moses did, who used to cover his face with a veil to keep the children of Israel from beholding the passing of a fading glory.
Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ.
14 Nay, their minds were made dull; for to this very day, at the public reading of the Old Testament, the same veil rests thereon, because it is not revealed to them that in Christ the veil is taken away.
Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò.
15 Yes, to this very day, whenever Moses is read, a veil lies on their hearts;
Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkígbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn.
16 but when their heart turns to our Lord the veil is stripped away.
Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò.
17 (The Lord means the Spirit, and where the Spirit of the Lord abides there is freedom.)
Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà.
18 And we all, with unveiled faces, reflecting like a mirror the glory of the Lord, are ourselves continually being transformed into the same likeness, from glory to glory, as by the Lord, the Spirit.
Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.