< Zechariah 7 >
1 And it comes to pass, in the fourth year of Darius the king, a word of YHWH has been to Zechariah, in the fourth of the ninth month, in Chisleu.
Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekariah wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kisleu tí ń ṣe oṣù kẹsànán.
2 And Beth-El sends Sherezer and Regem-Melech, and its men, to appease the face of YHWH,
Nígbà tí wọ́n ènìyàn Beteli rán Ṣareseri àti Regemmeleki, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojúrere Olúwa.
3 speaking to the priests who [are] at the house of YHWH of Hosts, and to the prophets, saying, “Do I weep in the fifth month—being separated—as I have done these so many years?”
Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?”
4 And there is a word of YHWH of Hosts to me, saying,
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé,
5 “Speak to all the people of the land, and to the priests, saying,
“Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùn-ún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin ha ń gbààwẹ̀ yín fún?
6 When you fasted with mourning in the fifth and in the seventh [months]—even these seventy years—did you keep the fast [to] Me? And when you eat, and when you drink, is it not you who are eating, and you who are drinking?
Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí?
7 Are [these] not the words that YHWH proclaimed by the hand of the former prophets, in Jerusalem’s being inhabited, and [in] safety, and its cities around it, and the south and the plain—abiding?”
Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti Olúwa ti kígbe láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jerusalẹmu, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’”
8 And there is a word of YHWH to Zechariah, saying,
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekariah wá, wí pé,
9 “Thus spoke YHWH of Hosts, saying, Judge [with] true judgment, And do kindness and mercy with one another.
“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀.
10 And do not oppress widow, and fatherless, Sojourner, and poor, And you do not devise the calamity of one another in your heart.
Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’
11 And they refuse to attend, And they give a stubborn shoulder, And their ears are made heavy against hearing.
“Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́.
12 And their heart they have made adamant, Against hearing the Law, and the words, That YHWH of Hosts sent by His Spirit, By the hand of the former prophets, And there is great wrath from YHWH of Hosts.
Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
13 And it comes to pass, as He called, And they have not listened, So they call, and I do not listen,” said YHWH of Hosts.
“‘Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
14 “And I toss them on all the nations, That they have not known, The land has been desolate behind them, Of any passing by and turning back, And they set a desirable land for a desolation!”
‘Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀. Ilẹ̀ náà sì dahoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjá tàbí kí ó padà bọ̀, wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dahoro.’”