< Job 37 >
1 “Also, my heart trembles at this, And it moves from its place.
“Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú, ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.
2 Listen diligently to the trembling of His voice, Indeed, the sound goes forth from His mouth.
Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀, àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.
3 He directs it under the whole heavens, And its light [is] over the skirts of the earth.
Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo, mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.
4 A voice roars after it—He thunders with the voice of His excellence, And He does not hold them back, When His voice is heard.
Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù; ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá. Òhun kì yóò sì dá àrá dúró, nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.
5 God thunders with His voice wonderfully, Doing great things and we do not know.
Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu; ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.
6 For He says to snow: Be [on] the earth. And the small rain and great rain of His power.
Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’ àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’
7 Into the hand of every man he seals, For the knowledge by all men of His work.
Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀, ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
8 And the beast enters into [its] lair, And it continues in its habitations.
Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ, wọn a sì wà ni ipò wọn.
9 From the inner chamber comes a windstorm, And from scatterings winds—cold,
Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.
10 From the breath of God is frost given, And the breadth of waters is constricted,
Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni, ibú omi á sì súnkì.
11 Indeed, by filling He presses out a cloud, [and] His light scatters a cloud.
Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo, a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
12 And it is turning itself around by His counsels, For their doing all He commands them, On the face of the habitable earth.
Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀, kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
13 Whether for a rod, or for His land, Or for kindness—He causes it to come.
Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀, tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
14 Hear this, O Job, Stand and consider the wonders of God.
“Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí; dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.
15 Do you know when God places them, And caused the light of His cloud to shine?
Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀, tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?
16 Do you know the balancings of a cloud? The wonders of the Perfect in knowledge?
Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
17 How your garments [are] warm, In the quieting of the earth from the south?
Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná, nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.
18 You have made an expanse with Him For the clouds—strong as a hard mirror!
Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin, tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?
19 Let us know what we say to Him, We do not set in array because of darkness.
“Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un; nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.
20 Is it declared to Him that I speak? If a man has spoken, surely he is swallowed up.
A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀? Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?
21 And now, they have not seen the light, It [is] bright in the clouds, And the wind has passed by and cleanses them.
Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀, ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.
22 It comes from the golden north, Fearful splendor [is] beside God.
Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá; lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.
23 The Mighty! We have not found Him out, High in power and judgment, He does not answer! And abundant in righteousness,
Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá; nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.
24 Therefore men fear Him, He does not see any of the wise of heart.”
Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀, òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”