< Job 20 >
1 And Zophar the Naamathite answers and says:
Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé,
2 “Therefore my thoughts cause me to answer, And because of my sensations in me.
“Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn, àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.
3 I hear the discipline of my shame, And the spirit of my understanding causes me to answer:
Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye mi sì dá mi lóhùn.
4 Have you known this from antiquity? Since the placing of man on earth?
“Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé,
5 That the singing of the wicked [is] short, And the joy of the profane for a moment,
pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?
6 Though his excellence goes up to the heavens, He strikes his head against a cloud—
Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, ti orí rẹ̀ sì kan àwọsánmọ̀;
7 He perishes as his own dung forever, His beholders say, Where [is] he?
ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’
8 He flees as a dream, and they do not find him, And he is driven away as a vision of the night,
Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i, àní a ó lé e lọ bi ìran òru.
9 The eye has not seen him, and does not add. And his place does not behold him again.
Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.
10 His sons oppress the poor, And his hands give back his wealth.
Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.
11 His bones have been full of his youth, and it lies down with him on the dust.
Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.
12 Though he sweetens evil in his mouth, hides it under his tongue,
“Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀, bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,
13 has pity on it, and does not forsake it, and keeps it back in the midst of his palate,
bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,
14 his food is turned in his bowels, the bitterness of cobras [is] in his heart.
ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà, ó jásí òróró paramọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;
15 He has swallowed wealth, and vomits it. God drives it out from his belly.
Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde; Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.
16 He sucks [the] gall of cobras, the tongue of a viper slays him.
Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú; ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.
17 He does not look on streams, Flowing of brooks of honey and butter.
Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.
18 He is giving back [what] he labored for, and does not consume [it]; As a bulwark [is] his exchange, and he does not exult.
Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.
19 For he oppressed—he forsook the poor, He has taken a house away violently, And he does not build it.
Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti pẹ̀yìndà si wọ́n; nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.
20 For he has not known ease in his belly. With his desirable thing he does not deliver himself.
“Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.
21 There is not a remnant to his food, Therefore his good does not stay.
Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀; nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.
22 In the fullness of his sufficiency he is constricted. Every perverse hand meets him.
Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a; àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí.
23 It comes to pass, at the filling of his belly, He sends forth against him The fierceness of His anger, Indeed, He rains on him in his eating.
Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun, Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́, yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.
24 He flees from an iron weapon, A bow of bronze passes through him.
Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn; ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.
25 One has drawn, And it comes out from the body, And a glittering weapon proceeds from his gall. Terrors [are] on him.
O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára; idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá. Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀;
26 All darkness is hid for his treasures, A fire not blown consumes him, The remnant is broken in his tent.
òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀. Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.
27 The heavens reveal his iniquity, And earth is raising itself against him.
Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn, ayé yóò sì dìde dúró sí i.
28 The increase of his house is removed, Poured forth in a day of His anger.
Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.
29 This [is] the portion of a wicked man from God. And an inheritance appointed him by God.”
Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”