< Isaiah 46 >

1 Bel has bowed down, Nebo is stooping, Their idols have been for the beast and for livestock, Your burdens are loaded, a burden to the weary.
Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀; àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù. Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di àjàgà sí wọn lọ́rùn, ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.
2 They have stooped, they have bowed together, They have not been able to deliver the burden, And have gone into captivity themselves.
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀; wọn kò lè gba ẹrù náà, àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.
3 “Listen to Me, O house of Jacob, And all the remnant of Israel, Who are borne from the belly, Who are carried from the womb,
“Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu, gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli, ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún, tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.
4 Even to old age, I [am] He, and to grey hairs I carry, I made, and I bear, indeed, I carry and deliver.
Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín, Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró. Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ; Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.
5 To whom do you liken Me, and make equal? And compare Me, that we may be like?
“Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba? Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi tí àwa yóò jọ fi ara wé ara?
6 They are pouring out gold from a bag, And they weigh silver on the beam, They hire a refiner, and he makes it a god, They fall down, indeed, they bow themselves.
Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn wọ́n sì wọn fàdákà lórí òsùwọ̀n; wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà, wọn sì tẹríba láti sìn ín.
7 They lift him up on the shoulder, They carry him, and cause him to rest in his place, And he stands, he does not move from his place, Indeed, one cries to him, and he does not answer, He does not save him from his adversity.
Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí. Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà. Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn; òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.
8 Remember this, and show yourselves men, Turn [it] back, O transgressors, to the heart.
“Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ, fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.
9 Remember former things of old, For I [am] Mighty, and there is none else, God—and there is none like Me.
Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́; Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn; Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi.
10 Declaring the latter end from the beginning, And from of old that which has not been done, Saying, My counsel stands, And all My delight I do.
Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá. Mo wí pé, Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
11 Calling a ravenous bird from the east, The man of My counsel from a far land, Indeed, I have spoken, indeed, I bring it in, I have formed [it], indeed, I do it.
Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá; láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ. Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ; èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.
12 Listen to Me, you mighty in heart, Who are far from righteousness.
Gbọ́ tèmi, ẹ̀yin alágídí ọkàn, ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo.
13 I have brought My righteousness near, It is not far off, And My salvation—it does not linger, And I have given salvation in Zion, For Israel My glory!”
Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí, kò tilẹ̀ jìnnà rárá; àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró. Èmi yóò fún Sioni ní ìgbàlà ògo mi fún Israẹli.

< Isaiah 46 >