< Ezekiel 35 >

1 And there is a word of YHWH to me, saying,
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2 “Son of man, set your face against Mount Seir, and prophesy against it,
“Ọmọ ènìyàn kọjú sí òkè Seiri; sọtẹ́lẹ̀ sí i,
3 and you have said to it, Thus said Lord YHWH: Behold, I [am] against you, O Mount Seir, And have stretched out My hand against you, And made you a desolation and an astonishment.
kí o sì sọ wí pé, ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmí lòdì sí ọ, òkè Seiri, Èmi yóò sì na ọwọ́ mi síta ní ìlòdì sí ọ, èmi yóò sì mú kí ó di ahoro.
4 I make your cities a ruin, and you are a desolation, And you have known that I [am] YHWH.
Èmi yóò pa àwọn ìlú rẹ run, ìwọ yóò sì di ahoro. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
5 Because of your having continuous enmity, And you saw the sons of Israel, By the hands of the sword, In the time of their calamity, In the time of the iniquity of the end:
“‘Nítorí ìwọ dá ààbò bo ọ̀tẹ̀ àtayébáyé, tí ìwọ sì fi Israẹli lé idà lọ́wọ́, ní àsìkò ìdààmú wọn, ní àsìkò tí ìjìyà wọn dé góńgó,
6 Therefore, [as] I live—a declaration of Lord YHWH, Surely I appoint you for blood, And blood pursues you, If you have not hated blood, Blood also pursues you.
nítorí náà bi mo ti wà láààyè, ni Olúwa Olódùmarè wí, èmi yóò fi ọ kalẹ̀ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. Níwọ́n ìgbà tí ìwọ kò ti kórìíra ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ.
7 And I have given Mount Seir for a desolation and an astonishment, And have cut off from it him who is passing over and him who is returning,
Èmi yóò mú kí òkè Seiri di ahoro; ọ̀fọ̀ gbogbo àwọn tí ó ń lọ tí ó ń bọ̀ ní èmi yóò gé kúrò lára rẹ.
8 And filled his mountains with his wounded, Your hills, and your valleys, and all your streams, The pierced of the sword fall into them.
Èmi yóò fi àwọn tí a pa kún orí òkè rẹ, àwọn tí a fi idà pa yóò ṣubú ní orí òkè rẹ, àti ní àárín àwọn òkè rẹ.
9 I make you continuous desolations, And your cities do not return, And you have known that I [am] YHWH.
Èmi yóò mú kí ó di ahoro títí láé, kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
10 Because of your saying: The two nations and the two lands are mine, and we have possessed it, And YHWH has been there;
“‘Nítorí tí ìwọ sọ pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀ méjì wọ̀nyí yóò jẹ́ tiwa, àwa yóò sì gbà wọ́n ní ìní,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, Èmi Olúwa wà níbẹ̀,
11 Therefore, [as] I live—a declaration of Lord YHWH, And I have done according to your anger, And according to your envy, With which you have worked, Because of your hatred against them, And I have been known among them when I judge you.
nítorí náà níwọ̀n ìgbà tí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, èmi yóò hùwà sí ọ ní ìbámu pẹ̀lú ìbínú àti owú tí o fihàn nínú ìkórìíra rẹ sí wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ní àárín wọn, nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ rẹ.
12 And you have known that I [am] YHWH, I have heard all your despisings that you have spoken Against mountains of Israel, saying, A desolation—they were given to us for food.
Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti gbọ́ gbogbo ohun ẹ̀gàn tí ìwọ ti sọ lòdì sí àwọn òkè Israẹli náà. Ìwọ wí pé, “A sọ wọ́n di ahoro, a sì fi wọ́n fún wa láti run.”
13 And you magnify yourselves against Me with your mouth, And have made your words abundant against Me; I have heard.
Ìwọ lérí sí mi, ó sì sọ̀rọ̀ lòdì sí mí láìsí ìdádúró, èmi sì gbọ́ ọ.
14 Thus said Lord YHWH: According to the rejoicing of the whole land, I make a desolation of you.
Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí gbogbo ayé bá ń yọ̀, èmi yóò mú kí ó di ahoro.
15 According to your joy at the inheritance of the house of Israel because of desolation, So I do to you—you are a desolation, O Mount Seir, and all Edom—all of it, And they have known that I [am] YHWH!”
Nítorí pé ìwọ ń yọ̀ nígbà tí ìní ilé Israẹli di ahoro, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yóò ṣe hùwà sí ọ. Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ òkè Seiri, ìwọ àti gbogbo ará Edomu. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’”

< Ezekiel 35 >