< 2 Samuel 7 >

1 And it comes to pass, when the king sat in his house, and YHWH has given rest to him all around, from all his enemies,
Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.
2 that the king says to Nathan the prophet, “Now see, I am dwelling in a house of cedars, but the Ark of God is dwelling in the midst of the curtain.”
Ọba sì wí fún Natani wòlíì pé, “Sá wò ó, èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kedari kọ́, ṣùgbọ́n àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.”
3 And Nathan says to the king, “All that [is] in your heart—go, do, for YHWH [is] with you.”
Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
4 And it comes to pass in that night, that the word of YHWH is to Nathan, saying,
Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Natani wá pé,
5 “Go, and you have said to My servant, to David, Thus said YHWH: Do you build for Me a house for My dwelling in?
“Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé.
6 For I have not dwelt in a house even from the day of My bringing up the sons of Israel out of Egypt, even to this day, and am walking up and down in a tent and in a dwelling place.
Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Israẹli gòkè ti ilẹ̀ Ejibiti wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi.
7 During all [the time] that I have walked up and down among all the sons of Israel, have I spoken a word with one of the tribes of Israel, which I commanded to feed my people Israel, saying, Why have you not built a house of cedars for Me?
Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Israẹli, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kedari kọ́ ilé fún mi.”’
8 And now, thus you say to My servant, to David, Thus said YHWH of Hosts: I have taken you from the pasture, from after the flock, to be leader over My people, over Israel;
“Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli.
9 and I am with you wherever you have gone, and I cut off all your enemies from your presence, and have made a great name for you, as the name of the great ones who [are] in the earth,
Èmi sì wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ ń lọ, èmi sá à gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, èmi sì ti sọ orúkọ rẹ di ńlá, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá tí ó wà ní ayé.
10 and I have appointed a place for My people, for Israel, and have planted it, and it has dwelt in its place, and it is not troubled anymore, and the sons of perverseness do not add to afflict it anymore, as in the beginning,
Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó tiwọn, wọn kì yóò sì sípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójúmọ́, bí ìgbà àtijọ́.
11 even from the day that I appointed judges over My people Israel; and I have given rest to you from all your enemies, and YHWH has declared to you that YHWH makes a house for you.
Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ. “‘Olúwa sì wí fún ọ pé Olúwa yóò kọ ilé kan fún ọ.
12 When your days are full, and you have lain with your fathers, then I have raised up your seed after you which goes out from your bowels, and have established his kingdom;
Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀.
13 he builds a house for My Name, and I have established the throne of his kingdom for all time.
Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé.
14 I am to him for a father, and he is to Me for a son; whom in his dealing perversely I have even reproved with a rod of men, and with strokes of the sons of Adam,
Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn.
15 and My kindness does not turn aside from him, as I turned it aside from Saul, whom I turned aside from before you,
Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Saulu, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ.
16 and your house and your kingdom [are] steadfast before you for all time, your throne is established for all time.”
A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé, a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’”
17 According to all these words, and according to all this vision, so spoke Nathan to David.
Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìran yìí, bẹ́ẹ̀ ni Natani sì sọ fún Dafidi.
18 And King David comes in and sits before YHWH, and says, “Who [am] I, Lord YHWH? And what [is] my house, that You have brought me here?
Dafidi ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí?
19 And yet this [is] little in Your eyes, Lord YHWH, and You also speak concerning the house of Your servant far off; and this [is] the law of the man, Lord YHWH.
Nǹkan kékeré ni èyí sá à jásí lójú rẹ, Olúwa Olódùmarè; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí ha ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Olódùmarè?
20 And what does David add more to speak to You? And You, You have known Your servant, Lord YHWH.
“Àti kín ní ó tún kù tí Dafidi ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, Olúwa Olódùmarè mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ.
21 Because of Your word, and according to Your heart, You have done all this greatness, to cause Your servant to know [it].
Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀.
22 Therefore You have been great, YHWH God, for there is none like You, and there is no God except You, according to all that we have heard with our ears.
“Ìwọ sì tóbi, Olúwa Olódùmarè! Kò sì sí ẹni tí ó dàbí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́.
23 And who [is] as Your people, as Israel—one nation in the earth, whom God has gone to redeem for a people for Himself, and to make for Himself a name—and to do for Yourself the greatness—even fearful things for Your land, at the presence of Your people, whom You have redeemed for Yourself out of Egypt—[among the] nations and their gods?
Orílẹ̀-èdè kan wo ni ó sì ń bẹ ní ayé tí ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli, àwọn tí Ọlọ́run lọ rà padà láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ̀, àti láti sọ wọ́n ní orúkọ, àti láti ṣe nǹkan ńlá fún un yín, àti nǹkan ìyanu fún ilé rẹ̀, níwájú àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ ti rà padà fún ara rẹ láti Ejibiti wá, àní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn.
24 Indeed, You establish Your people Israel for Yourself, for a people for Yourself for all time, and You, YHWH, have been to them for God.
Ìwọ sì fi ìdí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli kalẹ̀ fún ara rẹ láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ títí láé; ìwọ Olúwa sì wá di Ọlọ́run fún wọn.
25 And now, YHWH God, the word which You have spoken concerning Your servant, and concerning his house, establish for all time, and do as You have spoken.
“Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí.
26 And Your Name is great for all time, saying, YHWH of Hosts [is] God over Israel, and the house of Your servant David is established before You,
Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Israẹli!’ Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dafidi ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ.
27 for You, YHWH of Hosts, God of Israel, have uncovered the ear of Your servant, saying, I build a house for you, therefore Your servant has found his heart to pray this prayer to You.
“Nítorí pé ìwọ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli ti sọ létí ìránṣẹ́ rẹ, pé, ‘Èmí ó kọ́ ilé kan fún ọ.’ Nítorí náà ni ìránṣẹ́ rẹ sì ṣe ní i lọ́kàn rẹ̀ láti gbàdúrà yìí sí ọ.
28 And now, Lord YHWH, You [are] God Himself, and Your words are truth, and You speak this goodness to Your servant,
Ǹjẹ́, Olúwa Olódùmarè, ìwọ ni Ọlọ́run náà, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì jásí òtítọ́, ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ nǹkan rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ.
29 and now, begin and bless the house of Your servant, to be before You for all time, for You, Lord YHWH, have spoken, and by Your blessing the house of Your servant is blessed for all time.”
Ǹjẹ́, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bùkún ìdílé ìránṣẹ́ rẹ, kí ó wà títí láé níwájú rẹ, nítorí ìwọ, Olúwa Olódùmarè, ni ó ti sọ ọ́: sì jẹ́ kí ìbùkún wà ní ìdílé ìránṣẹ́ rẹ títí láé, nípasẹ̀ ìbùkún rẹ.”

< 2 Samuel 7 >