< Numbers 5 >

1 And the Lord spoke unto Moses, saying,
Olúwa sọ fún Mose pé,
2 Command the children of Israel, that they send out of the camp every leper, and every one that hath an issue, and whosoever is defiled by the dead:
“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.
3 Both male and female shall ye send out, to without the camp shall ye send them; that they defile not their camps, in the midst whereof I dwell.
Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má ba à ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrín wọn.”
4 And the children of Israel did so, and they sent them out to without the camp: as the Lord had spoken unto Moses, so did the children of Israel.
Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.
5 And the Lord spoke unto Moses, saying,
Olúwa sọ fún Mose pé,
6 Speak unto the children of Israel, If any man or woman commit any sin against a fellow-man, thereby doing a trespass against the Lord, and this person thus become guilty:
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa, ẹni náà jẹ̀bi.
7 Then shall they confess their sin which they have committed; and he shall make restitution for his trespass with the principal thereof, and its fifth part shall he add thereto, and give it unto him against whom he hath trespassed.
Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí òun jẹ̀bi rẹ̀.
8 But if the man have no kinsman to whom restitution could be made for the trespass, then shall the trespass which is restored unto the Lord, belong to the priest; besides the ram of the atonement, whereby an atonement shall be made for him.
Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó súnmọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà.
9 And every offering of all the holy things of the children of Israel, which they bring unto the priest, shall be his.
Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀.
10 And every man's hallowed things shall be his: whatsoever any man giveth to the priest, shall belong to him.
Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ti òun nìkan, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’”
11 And the Lord spoke unto Moses, saying,
Olúwa sọ fún Mose wí pé,
12 Speak unto the children of Israel, and say unto them, If the wife of any man go aside, and commit a trespass against him,
“Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé, ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìṣòótọ́ sí i,
13 And a man lie with her carnally, and it be hidden from the eyes of her husband, because she hath been secretly defiled; and there be no witness against her, and she have not been detected and in the fact;
nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lòpọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà).
14 And the spirit of jealousy come over him, and he be jealous of his wife, and she have been defiled; or the spirit of jealousy come over him, and he be jealous of his wife, and she have not been defiled:
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ dé bi pé ó ń funra sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́,
15 Then shall the man bring his wife unto the priest, and he shall bring her offering for her, the tenth part of an ephah of barley-meal; he shall not pour any oil upon it, nor put any frankincense thereupon; for it is a meat-offering of jealousy, a meat-offering of memorial, bringing iniquity to remembrance.
nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n efa ìyẹ̀fun barle. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.
16 And the priest shall bring her near, and place her before the Lord;
“‘Àlùfáà yóò sì mú un wá síwájú Olúwa.
17 And the priest shall take holy water in an earthen vessel; and of the dust that is on the floor of the tabernacle the priest shall take, and put it into the water;
Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀.
18 And the priest shall place the woman before the Lord, and uncover the woman's head, and put upon her hands the meat-offering of memorial, it is the meat-offering of jealousy; and in the hand of the priest shall be the bitter waters that bring the curse.
Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lé e lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnra rẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́.
19 And the priest shall charge her by an oath, and he shall say unto the woman, If no man have lain with thee, and if thou hast not gone aside to uncleanness behind thy husband: then be thou free from these bitter waters that bring the curse.
Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní ṣe ọ́ níbi.
20 But if thou hast gone aside behind thy husband, and if thou hast been defiled, and some man have lain with thee besides thy husband: —
Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í ṣe ọkọ rẹ bá ọ lòpọ̀,”
21 And the priest shall charge the woman with an oath of imprecation, and the priest shall say unto the woman, The Lord then make thee a curse and an oath among thy people, when the Lord doth cause thy thigh to fall away, and thy belly to swell;
nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé, “Kí Olúwa sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrín àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ̀ sì wú.
22 And these waters that bring the curse shall go into thy bowels, to cause the belly to swell, and the thigh to fall away; and the woman shall say, Amen, amen.
Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹrà dànù.” “‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”
23 And the priest shall write these curses on a roll, and he shall blot them out with the bitter waters.
“‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé kíká, yóò sì sìn ín sínú omi kíkorò náà.
24 And he shall cause the woman to drink the bitter waters that bring the curse: and the waters that bring the curse shall enter into her for bitterness.
Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi.
25 And the priest shall take out of the woman's hand the meat-offering of jealousy, and he shall wave the meat-offering before the Lord, and bring it near to the altar:
Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ owú náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í síwájú Olúwa, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ.
26 And the priest shall take a handful from the meat-offering, as its memorial, and burn it upon the altar, and after that shall he cause the woman to drink the water.
Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi.
27 And when he hath made her drink the water, then shall it come to pass, if she have been defiled, and have committed a trespass against her husband, that the waters that bring the curse shall enter into her, for bitterness, and her belly shall swell, and her thigh shall fall away; and the woman shall become a curse among her people.
Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
28 And if the woman have not been defiled, but be clean: then shall she remain unharmed, and she shall conceive seed.
Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ.
29 This is the law of jealousies, when a woman goeth aside behind her husband, and hath been defiled;
“‘Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe a ṣe má ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́,
30 Or when the spirit of jealousy cometh over him, and he be jealous of his wife; and he shall place the woman before the Lord, and the priest shall do unto her altogether according to this law.
tàbí nígbà tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkùnrin kan nítorí pé ó funra sí ìyàwó rẹ̀. Àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí fún un.
31 And the man shall be guiltless from iniquity; but this woman shall bear her iniquity.
Ara ọkọ rẹ̀ mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ṣùgbọ́n obìnrin náà yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’”

< Numbers 5 >