< Ezra 5 >
1 Then prophesied Haggai the prophet, and Zechariah the son of 'Iddo, the prophets, unto the Jews that were in Judah and Jerusalem, in the name of the God of Israel, concerning them.
Nígbà náà wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, láti ìran Iddo, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Juda àti Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọ́run Israẹli tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn.
2 Then rose up Zerubbabel the son of Shealthiel, and Jeshua' the son of Jozadak, and began to build the house of God which is in Jerusalem; and with them were the prophets of God helping them.
Nígbà náà Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua ọmọ Josadaki gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́.
3 At this same time came to them Thathnai, the governor on this side of the river, and Shethar-bozenai, and their companions, and thus they said unto them, “Who hath given you an order to build this house, and to complete these walls?”
Ní àkókò náà Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹgbẹgbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?”
4 Then said we unto them after this manner, what are the names of the men that erect this building.
Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?”
5 But the eye of their God was upon the elders of the Jews, so that they did not stop them, till the matter came to Darius; and they then returned an answer by letter concerning this.
Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbàgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró títí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dariusi kí wọ́n sì gba èsì tí àkọsílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6 A copy of the letter which Thathnai, the governor on this side of the river, and Shethar-bozenai, and his companions, the Apharsachites, who were on this side of the river, sent unto king Darius.
Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tatenai, olórí agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbègbè Eufurate, fi ránṣẹ́ sí ọba Dariusi.
7 They sent a report unto him, and thus was it written therein: Unto king Darius be all peace.
Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé, Sí ọba Dariusi, Àlàáfíà fún un yín.
8 Be it known unto the king, that we went into the province of Judah, to the house of the great God, which they are building with heavy stones, and timber is laid in the walls, and this work is urged with speed, and it prospereth in their hands.
Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Juda, sí tẹmpili Ọlọ́run tí ó tóbi. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńlá ńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsimi, ó sì ń ní ìtẹ̀síwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.
9 Then asked we these elders, and after this manner said we unto them, Who hath given you the order to build this house, and to complete these walls?
A bi àwọn àgbàgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé Olúwa yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?”
10 Also their names did we ask of them, to let thee know them, that we might write down the names of the men that are at their head.
A sì tún béèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn sílẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n.
11 And in this manner did they return us answer, saying, We are the servants of the God of heaven and earth, and we build the house that was built before this many years, and a great king of Israel built and completed it.
Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa: “Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹmpili ilé Olúwa tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Israẹli kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀.
12 But since our fathers had provoked the God of heaven unto wrath, he gave them up into the hand of Nebuchadnezzar the king of Babylon, the Chaldean, and he destroyed this house, and carried the people as exiles into Babylon.
Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadnessari ti Kaldea, ọba Babeli lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹmpili Olúwa yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Babeli.
13 However, in the first year of Cyrus the king of Babylon, king Cyrus gave an order to build this house of God.
“Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Kirusi ọba Babeli, ọba Kirusi pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́.
14 And also the vessels of gold and silver of the house of God, which Nebuchadnezzar had taken out of the temple that was in Jerusalem, and brought into the temple of Babylon, these did king Cyrus take out of the temple of Babylon, and gave them unto one, Sheshbazzar by name, whom he had appointed as governor;
Òun tilẹ̀ kò jáde láti inú tẹmpili ní Babeli fàdákà àti ohun èlò wúrà ilé Ọlọ́run, èyí tí Nebukadnessari kó láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu wá sí inú tẹmpili ní Babeli. Ọba Kirusi kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣeṣbassari, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i baálẹ̀,
15 And he said unto him, Take these vessels, go, carry them into the temple which is in Jerusalem, and let the house of God be built on its site.
ó sì sọ fún un pé, ‘Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.’
16 Then came this same Sheshbazzar, [and] laid the foundation of the house of God which is in Jerusalem; and from that time even until now they have been building it, but it is not yet finished.
“Nígbà náà ni Ṣeṣbassari náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jerusalẹmu lélẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsinsin yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.”
17 And now, if it seem good to the king, let search be made in the king's treasure-house, which is there at Babylon, whether it be so, that an order was given by king Cyrus to build this house of God at Jerusalem, and let the king send to us his pleasure concerning this matter.
Nísinsin yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Babeli láti rí bí ọba Kirusi fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jerusalẹmu. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.