< Song of Songs 7 >

1 Your steps are beautiful in shoes, O daughter of the prince: the joints of [your] thighs are like chains, the work of the craftsman.
Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà. Ìwọ ọmọbìnrin ọba! Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́ iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
2 Your navel is [as] a turned bowl, not lacking liquor; your belly is [as] a heap of wheat set about with lilies.
Ìdodo rẹ rí bí àwo tí kì í ṣe aláìní ọtí, ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama tí a fi lílì yíká.
3 Your two breasts are as two twin fawns.
Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
4 Your neck is as an ivory tower; your eyes are as pools in Esebon, by the gates of the daughter of many: your nose is as the tower of Libanus, looking toward Damascus.
Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni tí ó kọ ojú sí Damasku.
5 Your head upon you is as Carmel, and the curls of your hair like scarlet; the king is bound in the galleries.
Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká, bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.
6 How beautiful are you, and how sweet are you, [my] love!
Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?
7 This is your greatness in your delights: you were made like a palm tree, and your breasts to cluster.
Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ, àti ọmú rẹ bí ìdì èso àjàrà.
8 I said, I will go up to the palm tree, I will take hold of its high boughs: and now shall your breasts be as clusters of the vine, and the smell of your nose of apples;
Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ, èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú.” Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà, àti èémí imú rẹ bí i ápù.
9 and your throat as good wine, going well with my kinsman, suiting my lips and teeth.
Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ. Olólùfẹ́ Tí ó kúnná tí ó sì dùn, tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.
10 I am my kinsman's, and his desire is toward me.
Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe, èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.
11 Come, my kinsman, let us go forth into the field; let us lodge in the villages.
Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá, jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò.
12 Let us go early into the vineyards; let us see if the vine has flowered, [if] the blossoms have appeared, if the pomegranates have blossomed; there will I give you my breasts.
Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù láti wo bí àjàrà rúwé bí ìtànná àjàrà bá là. Àti bí pomegiranate bá ti rudi, níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13 The mandrakes have given a smell, and at our doors [are] all kinds of choice fruits, new and old. O my kinsman, I have kept [them] for you.
Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jáde ní ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso, èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́ tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.

< Song of Songs 7 >