< Deuteronomy 28 >
1 AND it shall come to pass, if thou shalt hearken diligently unto the voice of the Lord thy God, to observe and to do all his commandments which I command thee this day, that the Lord thy God will set thee on high above all nations of the earth:
Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ.
2 And all these blessings shall come on thee, and overtake thee, if thou shalt hearken unto the voice of the Lord thy God.
Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
3 Blessed shalt thou be in the city, and blessed shalt thou be in the field.
Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.
4 Blessed shall be the fruit of thy body, and the fruit of thy ground, and the fruit of thy cattle, the increase of thy kine, and the flocks of thy sheep.
Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
5 Blessed shall be thy basket and thy store.
Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.
6 Blessed shalt thou be when thou comest in, and blessed shalt thou be when thou goest out.
Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
7 The Lord shall cause thine enemies that rise up against thee to be smitten before thy face: they shall come out against thee one way, and flee before thee seven ways.
Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.
8 The Lord shall command the blessing upon thee in thy storehouses, and in all that thou settest thine hand unto; and he shall bless thee in the land which the Lord thy God giveth thee.
Olúwa yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.
9 The Lord shall establish thee an holy people unto himself, as he hath sworn unto thee, if thou shalt keep the commandments of the Lord thy God, and walk in his ways.
Olúwa yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
10 And all people of the earth shall see that thou art called by the name of the Lord; and they shall be afraid of thee.
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé yóò rí i pé a pè ọ́ ní orúkọ Olúwa, wọn yóò sì bẹ̀rù rẹ.
11 And the Lord shall make thee plenteous in goods, in the fruit of thy body, and in the fruit of thy cattle, and in the fruit of thy ground, in the land which the Lord sware unto thy fathers to give thee.
Olúwa yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ.
12 The Lord shall open unto thee his good treasure, the heaven to give the rain unto thy land in his season, and to bless all the work of thine hand: and thou shalt lend unto many nations, and thou shalt not borrow.
Olúwa yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan.
13 And the Lord shall make thee the head, and not the tail; and thou shalt be above only, and thou shalt not be beneath; if that thou hearken unto the commandments of the Lord thy God, which I command thee this day, to observe and to do them:
Olúwa yóò fi ọ́ ṣe orí, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ìrù. Bí o bá fi etí sílẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ tí mo fi fún ọ kí o sì máa rọra tẹ̀lé wọn, ìwọ yóò máa wà lókè, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò wà ní ìsàlẹ̀ láé.
14 And thou shalt not go aside from any of the words which I command thee this day, to the right hand, or to the left, to go after other gods to serve them.
Má ṣe yà sọ́tùn tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n.
15 But it shall come to pass, if thou wilt not hearken unto the voice of the Lord thy God, to observe to do all his commandments and his statutes which I command thee this day; that all these curses shall come upon thee, and overtake thee:
Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ.
16 Cursed shalt thou be in the city, and cursed shalt thou be in the field.
Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.
17 Cursed shall be thy basket and thy store.
Ègún ni fún agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.
18 Cursed shall be the fruit of thy body, and the fruit of thy land, the increase of thy kine, and the flocks of thy sheep.
Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
19 Cursed shalt thou be when thou comest in, and cursed shalt thou be when thou goest out.
Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
20 The Lord shall send upon thee cursing, vexation, and rebuke, in all that thou settest thine hand unto for to do, until thou be destroyed, and until thou perish quickly; because of the wickedness of thy doings, whereby thou hast forsaken me.
Olúwa yóò rán ègún sórí rẹ, rúdurùdu àti ìfibú nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ rẹ lé, títí ìwọ yóò fi parun àti wá sí ìparun lójijì nítorí búburú tí o ti ṣe ní kíkọ̀ mi sílẹ̀.
21 The Lord shall make the pestilence cleave unto thee, until he have consumed thee from off the land, whither thou goest to possess it.
Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn bá ọ jà títí tí yóò fi pa ọ́ run kúrò ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
22 The Lord shall smite thee with a consumption, and with a fever, and with an inflammation, and with an extreme burning, and with the sword, and with blasting, and with mildew; and they shall pursue thee until thou perish.
Olúwa yóò kọlù ọ́ pẹ̀lú ààrùn ìgbẹ́, pẹ̀lú ibà àti àìsàn wíwú, pẹ̀lú ìjóni ńlá àti idà, pẹ̀lú ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù tí yóò yọ ọ́ lẹ́nu títí ìwọ yóò fi parun.
23 And thy heaven that is over thy head shall be brass, and the earth that is under thee shall be iron.
Ojú ọ̀run tí ó wà lórí rẹ yóò jẹ́ idẹ, ilẹ̀ tí ń bẹ níṣàlẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ irin.
24 The Lord shall make the rain of thy land powder and dust: from heaven shall it come down upon thee, until thou be destroyed.
Olúwa yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eruku àti ẹ̀tù; láti ọ̀run ni yóò ti máa sọ̀kalẹ̀ sí ọ, títí tí ìwọ yóò fi run.
25 The Lord shall cause thee to be smitten before thine enemies: thou shalt go out one way against them, and flee seven ways before them: and shalt be removed into all the kingdoms of the earth.
Olúwa yóò fi ọ́ gégùn ún láti ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Ìwọ yóò tọ̀ wọ́n wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá fún wọn ní ọ̀nà méje, ìwọ yóò sì padà di ohun ìbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba lórí ayé.
26 And thy carcase shall be meat unto all fowls of the air, and unto the beasts of the earth, and no man shall fray them away.
Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò.
27 The Lord will smite thee with the botch of Egypt, and with the emerods, and with the scab, and with the itch, whereof thou canst not be healed.
Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Ejibiti àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra.
28 The Lord shall smite thee with madness, and blindness, and astonishment of heart:
Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà.
29 And thou shalt grope at noonday, as the blind gropeth in darkness, and thou shalt not prosper in thy ways: and thou shalt be only oppressed and spoiled evermore, and no man shall save thee.
Ní ọ̀sán gangan ìwọ yóò fi ọwọ́ tálẹ̀ kiri bí ọkùnrin afọ́jú nínú òkùnkùn ìwọ kì yóò ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe, ojoojúmọ́ ni wọn yóò máa ni ọ́ lára àti jà ọ́ ní olè, tí kò sì ní í sí ẹnìkan láti gbà ọ́.
30 Thou shalt betroth a wife, and another man shall lie with her: thou shalt build an house, and thou shalt not dwell therein: thou shalt plant a vineyard, and shalt not gather the grapes thereof.
Ìwọ yóò gba ògo láti fẹ́ obìnrin kan ṣùgbọ́n ẹlòmíràn yóò gbà á yóò sì tẹ́ ẹ́ ní ògo. Ìwọ yóò kọ́ ilé, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò gbé ibẹ̀. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kò tilẹ̀ ní gbádùn èso rẹ.
31 Thine ox shall be slain before thine eyes, and thou shalt not eat thereof: thine ass shall be violently taken away from before thy face, and shall not be restored to thee: thy sheep shall be given unto thine enemies, and thou shalt have none to rescue them.
Màlúù rẹ yóò di pípa níwájú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò jẹ nǹkan kan nínú rẹ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ yóò sì di mímú pẹ̀lú agbára kúrò lọ́dọ̀ rẹ, a kì yóò sì da padà. Àgùntàn rẹ yóò di mímú fún àwọn ọ̀tá rẹ, ẹnìkankan kò sì ní gbà á.
32 Thy sons and thy daughters shall be given unto another people, and thine eyes shall look, and fail with longing for them all the day long: and there shall be no might in thine hand.
Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ yóò di mímú fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ìwọ yóò sì fi ojú rẹ ṣọ́nà dúró dè wọ́n láti ọjọ́ dé ọjọ́, ìwọ yóò sì jẹ́ aláìlágbára láti gbé ọwọ́.
33 The fruit of thy land, and all thy labours, shall a nation which thou knowest not eat up; and thou shalt be only oppressed and crushed alway:
Èso ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ làálàá rẹ ni orílẹ̀-èdè mìíràn tí ìwọ kò mọ̀ yóò sì jẹ, ìwọ yóò jẹ́ kìkì ẹni ìnilára àti ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
34 So that thou shalt be mad for the sight of thine eyes which thou shalt see.
Ìran tí ojú rẹ yóò rí, yóò sọ ọ́ di òmùgọ̀.
35 The Lord shall smite thee in the knees, and in the legs, with a sore botch that cannot be healed, from the sole of thy foot unto the top of thy head.
Olúwa yóò lu eékún àti ẹsẹ̀ rẹ pẹ̀lú oówo dídùn tí kò le san tán láti àtẹ̀lé méjèèjì rẹ lọ sí òkè orí rẹ.
36 The Lord shall bring thee, and thy king which thou shalt set over thee, unto a nation which neither thou nor thy fathers have known; and there shalt thou serve other gods, wood and stone.
Olúwa yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lórí rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbí ti àwọn baba rẹ kò mọ̀. Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta.
37 And thou shalt become an astonishment, a proverb, and a byword, among all nations whither the Lord shall lead thee.
Ìwọ yóò di ẹni ìyanu, àti ẹni òwe, àti ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tí Olúwa yóò darí rẹ sí.
38 Thou shalt carry much seed out into the field, and shalt gather but little in; for the locust shall consume it.
Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ ẹ́ run.
39 Thou shalt plant vineyards, and dress them, but shalt neither drink of the wine, nor gather the grapes; for the worms shall eat them.
Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ̀ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èso jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run.
40 Thou shalt have olive trees throughout all thy coasts, but thou shalt not anoint thyself with the oil; for thine olive shall cast his fruit.
Ìwọ yóò ní igi olifi jákèjádò ilẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò ní lo òróró náà, nítorí olifi náà yóò rẹ̀ dànù.
41 Thou shalt beget sons and daughters, but thou shalt not enjoy them; for they shall go into captivity.
Ìwọ yóò ní àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣùgbọ́n ìwọ kò nípa wọ́n mọ́, nítorí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.
42 All thy trees and fruit of thy land shall the locust consume.
Ọ̀wọ́ eṣú yóò gba gbogbo àwọn igi rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ.
43 The stranger that is within thee shall get up above thee very high; and thou shalt come down very low.
Àjèjì tí ń gbé láàrín rẹ yóò gbé sókè gíga jù ọ́ lọ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò máa di ìrẹ̀sílẹ̀.
44 He shall lend to thee, and thou shalt not lend to him: he shall be the head, and thou shalt be the tail.
Yóò yà ọ́, ṣùgbọ́n o kì yóò yà á, òun ni yóò jẹ́ orí, ìwọ yóò jẹ́ ìrù.
45 Moreover all these curses shall come upon thee, and shall pursue thee, and overtake thee, till thou be destroyed; because thou hearkenedst not unto the voice of the Lord thy God, to keep his commandments and his statutes which he commanded thee:
Gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsi àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ.
46 And they shall be upon thee for a sign and for a wonder, and upon thy seed for ever.
Wọn yóò jẹ́ àmì àti ìyanu fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ títí láé.
47 Because thou servedst not the Lord thy God with joyfulness, and with gladness of heart, for the abundance of all things;
Nítorí ìwọ kò sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ní ayọ̀ àti inú dídùn ní àkókò àlàáfíà.
48 Therefore shalt thou serve thine enemies which the Lord shall send against thee, in hunger, and in thirst, and in nakedness, and in want of all things: and he shall put a yoke of iron upon thy neck, until he have destroyed thee.
Nítorí náà nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú ìhòhò àti àìní búburú, ìwọ yóò sin àwọn ọ̀tá à rẹ tí Olúwa rán sí ọ. Yóò sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́.
49 The Lord shall bring a nation against thee from far, from the end of the earth, as swift as the eagle flieth; a nation whose tongue thou shalt not understand;
Olúwa yóò mú àwọn orílẹ̀-èdè wá sí ọ láti ọ̀nà jíjìn, bí òpin ayé, bí idì ti ń bẹ́ láti orí òkè sílẹ̀, orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè wọn.
50 A nation of fierce countenance, which shall not regard the person of the old, nor shew favour to the young:
Orílẹ̀-èdè tí ó rorò tí kò ní ojúrere fún àgbà tàbí àánú fún ọmọdé.
51 And he shall eat the fruit of thy cattle, and the fruit of thy land, until thou be destroyed: which also shall not leave thee either corn, wine, or oil, or the increase of thy kine, or flocks of thy sheep, until he have destroyed thee.
Wọn yóò jẹ ohun ọ̀sìn rẹ run àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ títí tí ìwọ yóò fi parun. Wọn kì yóò fi hóró irúgbìn kan fún ọ, wáìnì tuntun tàbí òróró, tàbí agbo ẹran màlúù rẹ kankan tàbí ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn rẹ títí ìwọ yóò fi run.
52 And he shall besiege thee in all thy gates, until thy high and fenced walls come down, wherein thou trustedst, throughout all thy land: and he shall besiege thee in all thy gates throughout all thy land, which the Lord thy God hath given thee.
Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ.
53 And thou shalt eat the fruit of thine own body, the flesh of thy sons and of thy daughters, which the Lord thy God hath given thee, in the siege, and in the straitness, wherewith thine enemies shall distress thee:
Ìwọ ó sì jẹ èso ọmọ inú rẹ̀, ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ti àwọn ọmọ rẹ obìnrin tí Olúwa Ọlọ́run ti fi fún ọ; nínú ìdótì náà àti nínú ìhámọ́ náà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò há ọ mọ́.
54 So that the man that is tender among you, and very delicate, his eye shall be evil toward his brother, and toward the wife of his bosom, and toward the remnant of his children which he shall leave:
Ọkùnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, ojú rẹ̀ yóò korò sí arákùnrin rẹ̀ àti sí aya oókan àyà rẹ̀, àti sí ìyókù ọmọ rẹ̀ tí òun jẹ kù.
55 So that he will not give to any of them of the flesh of his children whom he shall eat: because he hath nothing left him in the siege, and in the straitness, wherewith thine enemies shall distress thee in all thy gates.
Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fún ẹnikẹ́ni nínú ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ń jẹ, nítorí kò sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún un nínú ìdótì náà àti ìhámọ́, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ gbogbo.
56 The tender and delicate woman among you, which would not adventure to set the sole of her foot upon the ground for delicateness and tenderness, her eye shall be evil toward the husband of her bosom, and toward her son, and toward her daughter,
Obìnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, tí kò jẹ́ dáṣà láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ ẹ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí ìkẹ́ra àti ìwà ẹlẹgẹ́, ojú u rẹ̀ yóò korò sí ọkọ oókan àyà rẹ̀, àti sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin,
57 And toward her young one that cometh out from between her feet, and toward her children which she shall bear: for she shall eat them for want of all things secretly in the siege and straitness, wherewith thine enemy shall distress thee in thy gates.
àti sí ọmọ rẹ̀ tí ó ti agbede-méjì ẹsẹ̀ rẹ̀ jáde, àti sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí yóò bí. Nítorí òun ó jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí àìní ohunkóhun nínú ìdótì àti ìhámọ́ náà, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ.
58 If thou wilt not observe to do all the words of this law that are written in this book, that thou mayest fear this glorious and fearful name, THE LORD THY GOD;
Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bu ọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára: orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ,
59 Then the Lord will make thy plagues wonderful, and the plagues of thy seed, even great plagues, and of long continuance, and sore sicknesses, and of long continuance.
Olúwa yóò sọ ìyọnu rẹ di ìyanu, àti ìyọnu irú-ọmọ ọ̀ rẹ, àní àwọn ìyọnu ńlá èyí tí yóò pẹ́, àti ààrùn búburú èyí tí yóò pẹ́.
60 Moreover he will bring upon thee all the diseases of Egypt, which thou wast afraid of; and they shall cleave unto thee.
Olúwa yóò mú gbogbo ààrùn Ejibiti tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá padà bá ọ, wọn yóò sì lẹ̀ mọ́ ọ.
61 Also every sickness, and every plague, which is not written in the book of this law, them will the Lord bring upon thee, until thou be destroyed.
Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ìwé òfin yìí wá sórí rẹ, títí ìwọ yóò fi run.
62 And ye shall be left few in number, whereas ye were as the stars of heaven for multitude; because thou wouldest not obey the voice of the Lord thy God.
Ìwọ tí ó dàbí àìmoye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò ṣẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
63 And it shall come to pass, that as the Lord rejoiced over you to do you good, and to multiply you; so the Lord will rejoice over you to destroy you, and to bring you to nought; and ye shall be plucked from off the land whither thou goest to possess it.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
64 And the Lord shall scatter thee among all people, from the one end of the earth even unto the other; and there thou shalt serve other gods, which neither thou nor thy fathers have known, even wood and stone.
Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀.
65 And among these nations shalt thou find no ease, neither shall the sole of thy foot have rest: but the Lord shall give thee there a trembling heart, and failing of eyes, and sorrow of mind:
Ìwọ kì yóò sinmi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà, kò sí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti fún ọ ní ọkàn ìnàngà, àárẹ̀ ojú, àti àìnírètí àyà.
66 And thy life shall hang in doubt before thee; and thou shalt fear day and night, and shalt have none assurance of thy life:
Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rùbojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ.
67 In the morning thou shalt say, Would God it were even! and at even thou shalt say, Would God it were morning! for the fear of thine heart wherewith thou shalt fear, and for the sight of thine eyes which thou shalt see.
Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, “Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ nìkan ni!” Nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí.
68 And the Lord shall bring thee into Egypt again with ships, by the way whereof I spake unto thee, Thou shalt see it no more again: and there ye shall be sold unto your enemies for bondmen and bondwomen, and no man shall buy you.
Olúwa yóò rán ọ padà nínú ọkọ̀ sí Ejibiti sí ìrìnàjò tí mo ní ìwọ kì yóò lọ mọ́. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò tún fi ara rẹ fún àwọn ọ̀tá à rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò rà ọ́.