< Proverbs 9 >

1 Wisdom has built her house, she has hewn out her seven pillars:
Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀, ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
2 She has killed her beasts; she has mingled her wine; she has also furnished her table.
ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà. Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
3 She has sent forth her maidens: she cries on the highest places of the city,
ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè, láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
4 Whoever is simple, let him turn in here: as for him that wants understanding, she says to him,
“Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!” Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé,
5 Come, eat of my bread, and drink of the wine which I have mingled.
“Wá, ẹ wá jẹ́ oúnjẹ mi sì mu wáìnì tí mo ti pò.
6 Forsake the foolish, and live; and go in the way of understanding.
Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè; rìn ní ọ̀nà òye.
7 He that reproves a scorner gets to himself shame: and he that rebukes a wicked man gets himself a blot.
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
8 Reprove not a scorner, lest he hate you: rebuke a wise man, and he will love you.
Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
9 Give instruction to a wise man, and he will be yet wiser: teach a just man, and he will increase in learning.
kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.
10 The fear of the LORD is the beginning of wisdom: and the knowledge of the holy is understanding.
“Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ nípa Ẹni Mímọ́ ni òye.
11 For by me your days shall be multiplied, and the years of your life shall be increased.
Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
12 If you be wise, you shall be wise for yourself: but if you scorn, you alone shall bear it.
Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè: bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
13 A foolish woman is clamorous: she is simple, and knows nothing.
Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo; ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.
14 For she sits at the door of her house, on a seat in the high places of the city,
Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,
15 To call passengers who go right on their ways:
ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
16 Whoever is simple, let him turn in here: and as for him that wants understanding, she says to him,
“Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!” Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
17 Stolen waters are sweet, and bread eaten in secret is pleasant.
“Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”
18 But he knows not that the dead are there; and that her guests are in the depths of hell. (Sheol h7585)
Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀, pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú. (Sheol h7585)

< Proverbs 9 >