< Proverbs 18 >
1 Through desire a man, having separated himself, seeks and intermeddles with all wisdom.
Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀; ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.
2 A fool has no delight in understanding, but that his heart may discover itself.
Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.
3 When the wicked comes, then comes also contempt, and with ignominy reproach.
Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé, nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.
4 The words of a man’s mouth are as deep waters, and the wellspring of wisdom as a flowing brook.
Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn, ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.
5 It is not good to accept the person of the wicked, to overthrow the righteous in judgment.
Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.
6 A fool’s lips enter into contention, and his mouth calls for strokes.
Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.
7 A fool’s mouth is his destruction, and his lips are the snare of his soul.
Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́, ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.
8 The words of a talebearer are as wounds, and they go down into the innermost parts of the belly.
Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn; wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
9 He also that is slothful in his work is brother to him that is a great waster.
Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀ arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.
10 The name of the LORD is a strong tower: the righteous runs into it, and is safe.
Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni; olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
11 The rich man’s wealth is his strong city, and as an high wall in his own conceit.
Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn; wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.
12 Before destruction the heart of man is haughty, and before honor is humility.
Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga, ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
13 He that answers a matter before he hears it, it is folly and shame to him.
Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́, èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
14 The spirit of a man will sustain his infirmity; but a wounded spirit who can bear?
Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn, ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.
15 The heart of the prudent gets knowledge; and the ear of the wise seeks knowledge.
Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀; etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.
16 A man’s gift makes room for him, and brings him before great men.
Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.
17 He that is first in his own cause seems just; but his neighbor comes and searches him.
Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre, títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo.
18 The lot causes contentions to cease, and parts between the mighty.
Ìbò dídì máa ń parí ìjà a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.
19 A brother offended is harder to be won than a strong city: and their contentions are like the bars of a castle.
Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ, ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.
20 A man’s belly shall be satisfied with the fruit of his mouth; and with the increase of his lips shall he be filled.
Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó; láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.
21 Death and life are in the power of the tongue: and they that love it shall eat the fruit thereof.
Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn, àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.
22 Whoever finds a wife finds a good thing, and obtains favor of the LORD.
Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere, o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.
23 The poor uses entreaties; but the rich answers roughly.
Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.
24 A man that has friends must show himself friendly: and there is a friend that sticks closer than a brother.
Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.