< Psalms 48 >
1 A Song; a Psalm of the sons of Korah. Great is the LORD, and highly to be praised, in the city of our God, His holy mountain,
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.
2 Fair in situation, the joy of the whole earth; even mount Zion, the uttermost parts of the north, the city of the great King.
Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀, ayọ̀ gbogbo ayé, òkè Sioni, ní ìhà àríwá ní ìlú ọba ńlá.
3 God in her palaces hath made Himself known for a stronghold.
Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀; ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.
4 For, lo, the kings assembled themselves, they came onward together.
Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀, wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
5 They saw, straightway they were amazed; they were affrighted, they hasted away.
Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n, a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ.
6 Trembling took hold of them there, pangs, as of a woman in travail.
Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀, ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
7 With the east wind Thou breakest the ships of Tarshish.
Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi, wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
8 As we have heard, so have we seen in the city of the LORD of hosts, in the city of our God — God establish it for ever. (Selah)
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa rí, ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ìlú Ọlọ́run wa, Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. (Sela)
9 We have thought on Thy lovingkindness, O God, in the midst of Thy temple.
Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run, àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10 As is Thy name, O God, so is Thy praise unto the ends of the earth; Thy right hand is full of righteousness.
Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run, ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé, ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11 Let mount Zion be glad, let the daughters of Judah rejoice, because of Thy judgments.
Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀ kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn nítorí ìdájọ́ rẹ.
12 Walk about Zion, and go round about her; count the towers thereof.
Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀, ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13 Mark ye well her ramparts, traverse her palaces; that ye may tell it to the generation following.
Kíyèsi odi rẹ̀, kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀ kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.
14 For such is God, our God, for ever and ever; He will guide us eternally.
Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé, Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.