< Psalms 22 >
1 For the Leader; upon Aijeleth ha-Shahar. A Psalm of David. My God, my God, why hast Thou forsaken me, and art far from my help at the words of my cry?
Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi?
2 O my God, I call by day, but Thou answerest not; and at night, and there is no surcease for me.
Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́.
3 Yet Thou art holy, O Thou that art enthroned upon the praises of Israel.
Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ; ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.
4 In Thee did our fathers trust; they trusted, and Thou didst deliver them.
Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ; wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.
5 Unto Thee they cried, and escaped; in Thee did they trust, and were not ashamed.
Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.
6 But I am a worm, and no man; a reproach of men, and despised of the people.
Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn; mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn.
7 All they that see me laugh me to scorn; they shoot out the lip, they shake the head:
Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.
8 'Let him commit himself unto the LORD! let Him rescue him; let Him deliver him, seeing He delighteth in him.'
“Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa; jẹ́ kí Olúwa gbà á là. Jẹ́ kí ó gbà á là, nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”
9 For Thou art He that took me out of the womb; Thou madest me trust when I was upon my mother's breasts.
Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú; ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.
10 Upon Thee I have been cast from my birth; Thou art my God from my mother's womb.
Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá, nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.
11 Be not far from me; for trouble is near; for there is none to help.
Má ṣe jìnnà sí mi, nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.
12 Many bulls have encompassed me; strong bulls of Bashan have beset me round.
Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká; àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
13 They open wide their mouth against me, as a ravening and a roaring lion.
Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri, tí ń ké ramúramù.
14 I am poured out like water, and all my bones are out of joint; my heart is become like wax; it is melted in mine inmost parts.
A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀. Ọkàn mi sì dàbí i ìda; tí ó yọ́ láàrín inú mi.
15 My strength is dried up like a potsherd; and my tongue cleaveth to my throat; and Thou layest me in the dust of death.
Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi; ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú. ()
16 For dogs have encompassed me; a company of evil-doers have inclosed me; like a lion, they are at my hands and my feet.
Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀.
17 I may count all my bones; they look and gloat over me.
Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi; àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.
18 They part my garments among them, and for my vesture do they cast lots.
Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.
19 But Thou, O LORD, be not far off; O Thou my strength, hasten to help me.
Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi. Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
20 Deliver my soul from the sword; mine only one from the power of the dog.
Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà, àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
21 Save me from the lion's mouth; yea, from the horns of the wild-oxen do Thou answer me.
Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún; kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.
22 I will declare Thy name unto my brethren; in the midst of the congregation will I praise Thee.
Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi; nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
23 'Ye that fear the LORD, praise Him; all ye the seed of Jacob, glorify Him; and stand in awe of Him, all ye the seed of Israel.
Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín! Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un! Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
24 For He hath not despised nor abhorred the lowliness of the poor; neither hath He hid His face from him; but when he cried unto Him, He heard.'
Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra ìpọ́njú àwọn tí a ni lára; kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.
25 From Thee cometh my praise in the great congregation; I will pay my vows before them that fear Him.
Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá; ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26 Let the humble eat and be satisfied; let them praise the LORD that seek after Him; may your heart be quickened for ever!
tálákà yóò jẹ yóò sì yó; àwọn tí n wá Olúwa yóò yin jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!
27 All the ends of the earth shall remember and turn unto the LORD; and all the kindreds of the nations shall worship before Thee.
Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí wọn yóò sì yípadà sí Olúwa, àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28 For the kingdom is the LORD'S; and He is the ruler over the nations.
nítorí ìjọba ni ti Olúwa. Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
29 All the fat ones of the earth shall eat and worship; all they that go down to the dust shall kneel before Him, even he that cannot keep his soul alive.
Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn; gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀ àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
30 A seed shall serve him; it shall be told of the Lord unto the next generation.
Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín; a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa.
31 They shall come and shall declare His righteousness unto a people that shall be born, that He hath done it.
Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí, wí pé, òun ni ó ṣe èyí.