< Psalms 10 >
1 Why standest Thou afar off, O LORD? Why hidest Thou Thyself in times of trouble?
Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré? Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?
2 Through the pride of the wicked the poor is hotly pursued, they are taken in the devices that they have imagined.
Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera, ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
3 For the wicked boasteth of his heart's desire, and the covetous vaunteth himself, though he contemn the LORD.
Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀; Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa.
4 The wicked, in the pride of his countenance, saith: 'He will not require'; all his thoughts are: 'There is no God.'
Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀; kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀.
5 His ways prosper at all times; Thy judgments are far above out of his sight; as for all his adversaries, he puffeth at them.
Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo; òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i; òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
6 He saith in his heart: 'I shall not be moved, I who to all generations shall not be in adversity.'
O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí. Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”
7 His mouth is full of cursing and deceit and oppression; under his tongue is mischief and iniquity.
Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ; wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
8 He sitteth in the lurking-places of the villages; in secret places doth he slay the innocent; his eyes are on the watch for the helpless.
Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò. Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀. Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
9 He lieth in wait in a secret place as a lion in his lair, he lieth in wait to catch the poor; he doth catch the poor, when he draweth him up in his net.
Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí; Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
10 He croucheth, he boweth down, and the helpless fall into his mighty claws.
Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀; kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
11 He hath said in his heart: 'God hath forgotten; He hideth His face; He will never see.'
Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé; Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”
12 Arise, O LORD; O God, lift up Thy hand; forget not the humble.
Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run. Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
13 Wherefore doth the wicked contemn God, and say in his heart: 'Thou wilt not require'?
Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run? Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀, “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?
14 Thou hast seen; for Thou beholdest trouble and vexation, to requite them with Thy hand; unto Thee the helpless committeth himself; Thou hast been the helper of the fatherless.
Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora; Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ. Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ; Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
15 Break Thou the arm of the wicked; and as for the evil man, search out his wickedness, till none be found.
Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi; pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀ tí a kò le è rí.
16 The LORD is King for ever and ever; the nations are perished out of His land.
Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé; àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.
17 LORD, Thou hast heard the desire of the humble: Thou wilt direct their heart, Thou wilt cause Thine ear to attend;
Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára; Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,
18 To right the fatherless and the oppressed, that man who is of the earth may be terrible no more.
láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára, kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé, kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.