< 2 Chronicles 27 >

1 Jotham was twenty and five years old when he began to reign; and he reigned sixteen years in Jerusalem; and his mother's name was Jerushah the daughter of Zadok.
Jotamu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku.
2 And he did that which was right in the eyes of the LORD, according to all that his father Uzziah had done; howbeit he entered not into the temple of the LORD. And the people did yet corruptly.
Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé Olúwa. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn.
3 He built the upper gate of the house of the LORD, and on the wall of Ophel he built much.
Jotamu sì kọ́ ẹnu-ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ofeli.
4 Moreover he built cities in the hill-country of Judah, and in the forest he built castles and towers.
Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Juda òkè àti nínú igbó àti ilé ìṣọ́, ó mọ ilé odi.
5 He fought also with the king of the children of Ammon, and prevailed against them. And the children of Ammon gave him the same year a hundred talents of silver, and ten thousand measures of wheat, and ten thousand of barley. So much did the children of Ammon render unto him, in the second year also, and in the third.
Jotamu sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ammoni ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ammoni wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá òsùwọ̀n alikama àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá barle. Àwọn ará Ammoni gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.
6 So Jotham became mighty, because he ordered his ways before the LORD his God.
Jotamu sì di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà tó tọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
7 Now the rest of the acts of Jotham, and all his wars, and his ways, behold, they are written in the book of the kings of Israel and Judah.
Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jotamu, pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ pẹ̀lú ohun mìíràn tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti ti Juda.
8 He was five and twenty years old when he began to reign, and reigned sixteen years in Jerusalem.
Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún.
9 And Jotham slept with his fathers, and they buried him in the city of David; and Ahaz his son reigned in his stead.
Jotamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

< 2 Chronicles 27 >