< Matthew 14 >

1 AT that time Herod the tetrarch heard the report of Jesus,
Ní àkókò náà ni Herodu ọba tetrarki gbọ́ nípa òkìkí Jesu,
2 and said unto his servants, This is John the Baptist; he is risen from the dead, and therefore miracles are wrought by him.
ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Johanu onítẹ̀bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”
3 For Herod having seized John, had bound him, and put him in prison, for the sake of Herodias, the wife of Philip his brother.
Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀,
4 For John said unto him, It is unlawful for thee to have her.
nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.”
5 And though he wished to kill him, he was afraid of the multitude, for they held him as a prophet.
Herodu fẹ́ pa Johanu, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.
6 But when Herod’s birth-day was kept, the daughter of Herodias danced in the circle, and pleased Herod:
Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi.
7 so that with an oath he promised to give her whatever she should ask.
Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún.
8 And she, being previously urged on by her mother, said, Give me here, in a spacious dish, the head of John the Baptist.
Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”.
9 And the king was grieved: but for his oath’s sake, and on account of those who were with him, he commanded it to be given her.
Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́.
10 And he sent, and beheaded John in the prison.
Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú.
11 And his head was brought on a large dish, and was given to the young lady: and she brought it to her mother.
A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwopọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ.
12 And his disciples came and took the body, and buried it, and they came and told Jesus.
Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jesu.
13 And when Jesus heard it, he withdrew from thence in a vessel into a desert place apart: and when the multitudes heard it, they followed him on foot from the cities.
Nígbà tí Jesu gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi kọ́lọ́fín kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn.
14 And when Jesus was come forth, he saw a great multitude, and was moved with compassion towards them, and healed their sick.
Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.
15 But when evening was come, his disciples came unto him, saying, The place is desert, and the day is far advanced; send the multitude away, that they may go into the villages, and buy themselves provisions.
Nígbà ti ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.”
16 But Jesus said unto them, They need not depart: give ye them to eat.
Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”
17 And they said unto him, We have nothing here except five loaves and two fishes.
Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”
18 Then he said, Bring them hither to me.
Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.”
19 And he commanded the multitude to sit down on the grass, and taking the five loaves and the two fishes, looking up to heaven, he blessed them, and brake, and gave the loaves to the disciples, and the disciples to the multitude.
Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn.
20 And they did all eat, and were filled: and they took up the superabundance of the fragments, twelve baskets full.
Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá.
21 And they who had eaten, were about five thousand men, besides women and children.
Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.
22 And immediately Jesus compelled his disciples to go on board the vessel, and pass before him to the other side, while he dismissed the people.
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn.
23 And when he had sent away the multitude, he went up into a mountain apart to pray: and when evening came, he was there alone.
Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnra rẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀,
24 But the vessel was already in the midst of the sea, tossed with the waves: for the wind was contrary.
ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.
25 Then at the fourth watch of the night came Jesus unto them, walking on the sea.
Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi.
26 And when the disciples saw him walking on the sea, they were greatly agitated, saying, It is his apparition. And they cried out with terror.
Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni,” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.
27 And immediately Jesus spake to them, saying, Be of good courage: it is I; be not terrified.
Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”
28 Then Peter answering, said, Lord, if it be thou, command me to come unto thee upon the waters.
Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”
29 And he said, Come. And descending from the vessel, Peter walked upon the waters to come to Jesus.
Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.” Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu.
30 But seeing the wind boisterous, he was afraid; and beginning to sink in the deep, he cried out, saying, Lord save me.
Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”
31 Then immediately Jesus stretching out his hand, laid hold on him, and said to him, O thou of little faith, wherefore dost thou doubt?
Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”
32 And when they came aboard the vessel, the wind ceased.
Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́.
33 And they who were in the vessel, came and worshipped him, saying, Truly thou art the Son of God.
Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”
34 And passing over, they came to the land of Gennesareth.
Nígbà tí wọn rékọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti.
35 And when the men of that place knew him, they sent into all that neighbourhood, and brought to him all that had illnesses:
Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá.
36 and they besought him that they might only touch the fringe of his garment: and as many as touched it were cured.
Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.

< Matthew 14 >