< Zechariah 11 >
1 Open your doors, Lebanon, so that fire can burn up your cedars!
Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lebanoni, kí iná bá lè jẹ igi kedari rẹ run.
2 Weep, juniper, because the cedar has fallen, the majestic trees are ruined! Weep, oaks of Bashan, for the thick forest has been cut down!
Hu, igi junifa; nítorí igi kedari ṣubú, nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́: hu, ẹ̀yin igi óákù tí Baṣani, nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀.
3 Listen to the howls of the shepherds, for their pastureland is destroyed. Listen to the roars of the young lions, for their Jordan habitat is ruined.
Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn; ògo wọn bàjẹ́; gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún nítorí ògo Jordani bàjẹ́.
4 This is what the Lord my God says: Become a shepherd of the flock marked for slaughter.
Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́ ẹran àbọ́pa.
5 Those who buy them kill them and don't feel guilty; those who sell them say, “Praise the Lord! Now I'm rich!” Even their shepherds don't care about them.
Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún Olúwa, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn.
6 For I will no longer care about the people of the Land, declares the Lord. I am going to make them victims of each other, and of the king. They will devastate the earth and I won't help anyone get away from them.
Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni Olúwa wí, “Ṣí kíyèsi í, èmi yóò fi olúkúlùkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.”
7 So I became a shepherd of the flock marked for slaughter by the sheep merchants. Then I took two staffs, one named Grace, the other named Union, and I shepherded the flock.
Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì sọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran náà.
8 In one month I dismissed three shepherds. I became impatient with them, and they also hated me.
Olùṣọ́-àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan. Ọkàn mi sì kórìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kórìíra mi.
9 Then I said, “I will not be your shepherd. If the sheep die, they die. Let those that are to perish, perish. Let those who are left eat each other!”
Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.”
10 Then I took my staff called Grace and broke it, breaking the agreement I had made with all the peoples.
Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ si méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mú mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá.
11 It was broken on that day, and the sheep merchants who were watching me knew that it was a message from the Lord.
Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran náà tí ó dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni.
12 I told them, “If you want to pay me my wages, then do so. If not, then don't.” So they paid me my wages—thirty pieces of silver.
Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi.
13 And the Lord said to me, “Throw the money to the treasury,” this measly sum they thought I was worth! So I took the thirty pieces of silver and threw it into the treasury of the Lord's Temple.
Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa.
14 Then I broke my second staff called Union, breaking the family union between Judah and Israel.
Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrín Juda àti láàrín Israẹli.
15 The Lord told me, Get the things you use as a shepherd, a useless shepherd.
Olúwa sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun èlò aṣiwèrè olùṣọ́-àgùntàn kan sọ́dọ̀ rẹ̀.
16 For I am placing a shepherd in charge of the land who won't care for those who are dying, or look for the lost, or heal the injured, or feed the healthy. Instead he will eat the meat from the fattest sheep. He even tears their hooves off.
Nítorí Èmi o gbé Olùṣọ́-àgùntàn kan dìde ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyí tí ó ni ọ̀rá, àwọn èyí tiwọn fi èékánná wọn ya ara wọn pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
17 What disaster is coming to this useless shepherd who abandons the flock! The sword will strike his arm and his right eye. His arm will wither away and his right eye will become completely blind.
“Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn asán náà, tí ó fi ọ̀wọ́ ẹran sílẹ̀! Idà yóò gé apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀: apá rẹ̀ yóò gbẹ pátápátá, ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátápátá!”