< Revelation 7 >
1 Then I saw four angels standing at the four corners of the earth holding back the earth's four winds to prevent any wind from blowing on the earth, or over the sea, or against any tree.
Lẹ́yìn èyí ni mo rí angẹli mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí Òkun, tàbí sára igikígi.
2 I watched another angel rise up from the east, holding the seal of the living God. He shouted in a loud voice to the four angels who had been given the power to damage the earth and the sea,
Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára,
3 “Don't hurt the earth or the sea or the trees until we have placed a seal on the foreheads of God's true followers!”
wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.”
4 I was told the number of those who were sealed: one hundred and forty-four thousand. Those who were sealed came from every tribe of the children of Israel:
Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si, àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá.
5 twelve thousand from the tribe of Judah, twelve thousand from the tribe of Reuben, twelve thousand from the tribe of Gad,
Láti inú ẹ̀yà Juda a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà. Láti inú ẹ̀yà Reubeni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà. Láti inú ẹ̀yà Gadi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.
6 twelve thousand from the tribe of Asher, twelve thousand from the tribe of Naphtali, twelve thousand from the tribe of Manasseh,
Láti inú ẹ̀yà Aṣeri a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà. Láti inú ẹ̀yà Naftali a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà. Láti inú ẹ̀yà Manase a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.
7 twelve thousand from the tribe of Simeon, twelve thousand from the tribe of Levi, twelve thousand from the tribe of Issachar,
Láti inú ẹ̀yà Simeoni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà. Láti inú ẹ̀yà Lefi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà. Láti inú ẹ̀yà Isakari a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.
8 twelve thousand from the tribe of Zebulun, twelve thousand from the tribe of Joseph, twelve thousand from the tribe of Benjamin.
Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà. Láti inú ẹ̀yà Josẹfu a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà. Láti inú ẹ̀yà Benjamini a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.
9 After this I looked and saw a great crowd that nobody could count, made up of every nation, tribe, people and language. They were standing in front of the throne and the Lamb, dressed in white robes, with palm branches in their hands.
Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn.
10 They gave a loud shout, “Salvation is from our God who sits on the throne, and from the Lamb.”
Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé: “Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá tí o jókòó lórí ìtẹ́, àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!”
11 All the angels surrounding the throne, and the elders and the four living creatures, fell down on their faces before the throne, worshipping God.
Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run.
12 “Amen!” they said. “Blessing, glory, wisdom, gratitude, honor, power, and strength, be to God for ever and ever. Amen.” (aiōn )
Wí pe: “Àmín! Ìbùkún, àti ògo, àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá, àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé! Àmín!” (aiōn )
13 One of the elders spoke to me and asked, “Who are those who are dressed in white robes, and where have they come from?”
Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”
14 I replied, “My Lord, you know the answer.” He told me, “These are the ones who have passed through great persecution. They washed their robes, making them white through the blood of the Lamb.
Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.” Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà.
15 That's why they can stand in front of God's throne, and they serve him day and night in his Temple. The one who sits on the throne will protect them with his presence.
Nítorí náà ni, “wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀; ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si síji bò wọn.
16 They will never be hungry ever again, or thirsty; the sun will not beat down on them and they will not suffer scorching heat,
Ebi kì yóò pa wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́; bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn tàbí oorukóoru kan.
17 because the Lamb who is at the center of the throne will be their shepherd, and will lead them to springs of living water, and God will wipe away every tear from their eyes.”
Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn, ‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè.’ ‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’”