< Matthew 7 >

1 Don't judge others, so that you won't be judged.
“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́.
2 For whatever standard you use to judge others will be used to judge you, and whatever measurement you use to measure others will be used to measure you.
Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òsùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín.
3 Why do you see the speck that's in your brother's eye? Don't you notice the plank that's in your own eye?
“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ?
4 How can you say to your brother, ‘Let me take out that speck from your eye’ when you have a plank in your own eye?
Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ.
5 You're being hypocritical! First get rid of the plank that's in your own eye. Then you'll be able to see clearly to take out the speck from your brother's eye.
Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.
6 Don't give dogs what's holy. Don't throw your pearls to pigs. That way the pigs won't trample them underfoot, and the dogs won't turn and attack you.
“Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ.
7 Ask, and it will be given to you; seek, and you will find; knock, and the door will be opened for you.
“Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín.
8 Everyone who asks, receives; everyone who seeks, finds; and everyone who knocks has the door opened for them.
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún.
9 Would any of you give your son a stone if he asked for bread?
“Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un?
10 Or if he asked for fish, would you give him a snake?
Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò?
11 So if even you who are evil know to give good things to your children, how much more will your heavenly Father give good things to those who ask him.
Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?
12 Treat others the way you want them to treat you. This sums up the law and the prophets.
Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì.
13 Enter by the narrow entrance. For the entrance is wide, and the way is broad that leads to destruction, and many travel that way.
“Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé.
14 But the entrance is narrow, and the way is difficult that leads to life, and only a few find it.
Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.
15 Watch out for false prophets who come wearing sheep's clothing, but who on the inside are vicious wolves.
“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n.
16 You can recognize them by their fruits. Do people harvest grapes from thorn bushes, or figs from thistles?
Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú?
17 So every good tree produces good fruit, while a bad tree produces bad fruit.
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú.
18 A good tree can't produce bad fruit, and a bad tree can't produce good fruit.
Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere.
19 Every tree that doesn't produce good fruit is chopped down and thrown into the fire.
Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná.
20 So you'll recognize them by their fruits.
Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.
21 Not everyone who calls me ‘Lord, Lord’ will enter the kingdom of heaven—only those who do the will of my Father in heaven.
“Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.
22 Many will say to me at the Day of Judgment, ‘Lord, Lord, didn't we prophesy in your name and drive out demons in your name, and perform many miracles in your name?’
Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’
23 Then I will tell them, ‘I never knew you. Leave me, you people who practice wickedness!’
Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
24 Everyone that hears the words I say, and follows them, is like a wise man who built his house on solid rock.
“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta.
25 The rain poured down, and the floods rose, and the winds blew hard against the house, but it didn't fall down, because its foundations were on solid rock.
Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.
26 Everyone that hears the words I say, and doesn't follow them, is like a foolish man who built his house on the sand.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn.
27 The rain poured down, and the floods rose, and the winds blew hard against the house, and it fell down—it totally collapsed.”
Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”
28 When Jesus finished explaining these things, the crowds were amazed at his teaching,
Nígbà tí Jesu sì parí sísọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀,
29 for he taught like someone with authority, and not like their religious teachers.
nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí i ti olùkọ́ òfin wọn.

< Matthew 7 >