< Judges 20 >

1 All the Israelites from Dan to Beersheba, including the land of Gilead, went and gathered at Mizpah before the Lord. The assembly was united in purpose.
Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti Dani dé Beerṣeba, àti láti ilẹ̀ Gileadi jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ síwájú Olúwa ni Mispa.
2 The leaders of all the people of every Israelite tribe took their assigned positions in the assembled army of God's people, four hundred thousand soldiers armed with swords.
Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli dúró ní ipò wọn ní àpéjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn.
3 The tribe of Benjamin found out that the Israelites had assembled at Mizpah. The Israelites asked, “Tell us, how could such an evil act have happened?”
(Àwọn ẹ̀yà Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ọmọ Israẹli yòókù ti gòkè lọ sí Mispa.) Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.”
4 The Levite, the husband of the woman who had been murdered, explained, “I and my concubine came to spend the night at the town of Gibeah in the territory of Benjamin.
Ará Lefi náà, ọkọ obìnrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gibeah ti àwọn ará Benjamini láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀.
5 The leaders of Gibeah came to attack me at night. They surrounded the house, intending to kill me. They raped my concubine and she died.
Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gibeah lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú.
6 I took my concubine and cut her into pieces, and I sent these pieces of her to every part of the country that had been given to Israel, because those men had done something shameful and disgusting in Israel.
Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbègbè ìní Israẹli kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Israẹli.
7 So all of you Israelites have to decide here and now what you're going to do about it!”
Nísinsin yìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.”
8 Everyone stood up and unitedly declared, “None of us are going home to our tents! None of us are going home to our houses!
Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀.
9 This is what we're going to do to Gilboah: we will attack it with our forces chosen by lot.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò ṣe sí Gibeah ní yìí. Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa.
10 We'll take ten men from a hundred from all the Israelite tribes, then a hundred from a thousand, then a thousand from ten thousand, to arrange food for the army, so when the troops reach Gibeah in Benjamin, they can pay them back for all these disgusting things they've done in Israel.”
A yóò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli àti ọgọ́rùn-ún láti inú ẹgbẹ̀rún kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ-ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gibeah ti àwọn ará Benjamini, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Israẹli.”
11 All the men of Israel were in agreement and gathered to attack the town.
Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli parapọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà.
12 The Israelite tribes also sent men throughout the territory of Benjamin, asking the people, “What are you doing about this terrible evil that has taken place among you?
Àwọn ẹ̀yà Israẹli rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Benjamini wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín yín?
13 Hand over these wicked men so we can execute them and get rid of this evil from Israel!” But the Benjamites refused to listen to what their fellow Israelites had to say.
Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gibeah yìí wá fún wa, kí àwa lé pa, kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Israẹli.” Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Benjamini kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Israẹli.
14 They left their towns and assembled at Gibeah to go and fight the other Israelites.
Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gibeah láti bá àwọn ọmọ Israẹli jà.
15 That day a total of twenty-six thousand men armed with swords were called up from the towns of Benjamin, in addition to the seven hundred seasoned warriors from Gibeah.
Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àwọn ará Benjamini kó ẹgbàá mẹ́tàlá àwọn ọmọ-ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gibeah.
16 Making up part of this army were seven hundred experienced soldiers who used their left hands. All of them could fire a slingshot and not miss by even a hair's breadth.
Ní àárín àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára dé bi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàsé (wọ́n jẹ́ atamọ́tàsé).
17 The Israelite army (excluding Benjamin) numbered four hundred thousand seasoned warriors, all armed with swords.
Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.
18 The Israelites went to Bethel and asked God, “Which ones of us should be the first to go and fight the Benjamites?” “Judah is to go first,” the Lord replied.
Àwọn ọmọ Israẹli lọ sí Beteli, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Benjamini láti bá wọn jà?” Olúwa dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.”
19 The next morning the Israelites left and set up their camp near Gibeah.
Àwọn ọmọ Israẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti Gibeah (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gibeah).
20 Then they marched out for battle with the army of Benjamin, taking up their positions to attack Gibeah.
Àwọn ọkùnrin Israẹli jáde lọ láti bá àwọn ará Benjamini jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gibeah.
21 But the Benjamites came out of Gibeah and slaughtered twenty-two thousand Israelites on the battlefield that day.
Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti Gibeah wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli ní ojú ogun ní ọjọ́ náà.
22 But the Israelites encouraged one other to be confident, and they took up the same positions they had on the first day.
Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Israẹli mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́.
23 The Israelites went and cried before the Lord until the evening and asked, “Should we go and attack the Benjamites again, our relatives?” “Go and attack them,” the Lord replied.
Àwọn ọmọ Israẹli sì lọ wọ́n sọkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Benjamini arákùnrin wa jà?” Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”
24 So the second day they advanced to attack the army of Benjamin.
Àwọn ọmọ Israẹli sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Benjamini ní ọjọ́ kejì.
25 However, Benjamites came out of Gibeah once more and slaughtered eighteen thousand Israelites, all armed with swords.
Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Benjamini jáde sí wọn láti Gibeah, láti dojúkọ wọn, wọ́n pa ẹgbàá mẹ́sàn ọkùnrin Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.
26 Then all the Israelites and all their army went to Bethel, and sat crying there before the Lord. That day they fasted until evening and gave burnt offerings and friendship offerings to the Lord.
Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Beteli, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sọkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa.
27 The Israelites asked the Lord what to do. At that time the Ark of God's Agreement was kept there.
Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wà níbẹ̀,
28 Phinehas, son of Eleazar and grandson of Aaron, was the priest. The Israelites asked the Lord, “Should go and we fight again against our relatives from Benjamin, or not?” “Yes, go! Tomorrow I will hand them over to you,” the Lord replied.
Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Benjamini arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?” Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”
29 Then the Israelites set up an ambush around Gibeah.
Àwọn ọmọ Israẹli sì yàn àwọn ènìyàn tí ó sá pamọ́ yí Gibeah ká.
30 On the third day they took up the same positions they had as before.
Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ Benjamini lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí Gibeah bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí.
31 The Benjamites came out to attack them and were lured away from the town as they began to kill Israelites as they had before. Some thirty Israelites died on the battlefield and along the roads, the one that goes towards Bethel and the other that goes back towards Gibeah.
Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ Israẹli sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí Beteli àti èkejì sí Gibeah.
32 “We're defeating them, just like before,” the Benjamites shouted. But the Israelites said, “Let's run away from them and lure them away from the town towards the roads.”
Nígbà tí àwọn Benjamini ń wí pé, “Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú,” àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà.”
33 The main army of Israelites left where they were and took up positions at Baal-tamar, while those in the ambush west of Gibeah charged out to attack from where they had been hiding.
Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Baali-Tamari, àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí wọ́n sá pamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀-oòrùn Gibeah.
34 Ten thousand seasoned Israelite warriors attacked Gibeah, and the fighting was so intense the Benjamites didn't realize they were on the brink of disaster.
Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn àṣàyàn ológun àwọn ọmọ Israẹli gbógun ti Gibeah láti iwájú ogun náà le gidigidi dé bí i pé àwọn ẹ̀yà Benjamini kò funra pé ìparun wà nítòsí.
35 So the Lord defeated Benjamin before Israel. That day the Israelites killed twenty-five thousand one hundred Benjamites, all armed with swords.
Olúwa ṣẹ́gun Benjamini níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbàá méjìlá ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ọkùnrin Benjamini, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun.
36 The Benjamites saw that they were defeated. The Israelites had fallen back before the Benjamites because they were confident the ambush they had put in place near Gibeah would be successful.
Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn. Àwọn ọkùnrin Israẹli fàsẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Benjamini nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gibeah.
37 The men from the ambush raced to attack the town, and they killed everyone in it.
Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gibeah, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà.
38 The agreement was that they would send up a great cloud of smoke to show the town had fallen.
Àwọn ọkùnrin Israẹli àti àwọn tí o ba ní ibùba sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó ba ní ibùba fi èéfín ṣe ìkùùkuu ńlá láti inú ìlú náà,
39 The Israelite army turned to attack the Benjamites, who had already killed about thirty Israelites. The Benjamites were saying, “We're completely defeating them, just like the first battle!”
nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli yípadà, wọ́n sá gun. Àwọn ọmọ Benjamini sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó to ọgbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.”
40 However, when the Israelites saw the columns of smoke rising heavenwards to form a great cloud over the whole of the town,
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkùùkuu èéfín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Benjamini yípadà wọ́n sì rí èéfín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run.
41 they turned on their enemies. The Benjamites were horrified when they saw it and realized they were doomed.
Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Benjamini nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu.
42 They turned and ran from the Israelites towards the desert, but the battle caught up with them, and the Israelites also killed those who left the towns on the way.
Wọ́n sì sá níwájú àwọn ọmọ Israẹli sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀.
43 Chasing after the Benjamites, the Israelites surrounded them, easily overtaking them east of Gibeah.
Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Benjamini ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbègbè ìlà-oòrùn Gibeah.
44 Eighteen thousand Benjamites were killed, all of them courageous warriors.
Ẹgbàá mẹ́sàn àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun.
45 Some of the Benjamites that were left ran towards Pomegranate Rock in the desert, and the Israelites killed another five thousand men on the way. They chased another group of Benjamites as far as Gidom and killed another thousand.
Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sálọ sí apá ijù lọ sí ọ̀nà àpáta Rimoni ni àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Benjamini títí dé Gidomu, wọ́n sì tún bi ẹgbẹ̀rún méjì ọkùnrin ṣubú.
46 So that day twenty-five thousand Benjamite were killed, all armed with swords and all courageous warriors.
Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún jagunjagun Benjamini tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun.
47 There were six hundred who ran away to Pomegranate Rock in the desert and they stayed there four months.
Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rimoni, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin.
48 The Israelites went back into the territory of the Benjamites, and going from town to town, they killed everything: people, animals, everything they found. Then they burned down every town on their way.
Àwọn ọkùnrin Israẹli sì padà sí àwọn ìlú Benjamini wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.

< Judges 20 >