< Job 27 >
1 Job began to speak again.
Pẹ̀lúpẹ̀lú Jobu sì tún sọkún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé,
2 “I promise you—as God lives, who has denied me justice, the Almighty, who has made my life bitter,
“Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ, àti Olódùmarè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́,
3 for as long as I have life, while the breath of God remains in my nostrils—
níwọ́n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínú mi, àti tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ nínú ihò imú mi.
4 my lips will never speak lies, my tongue will never be dishonest.
Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké, bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
5 I will never agree that you are right; I will insist on my innocence until the day I die.
Kí a má rí i pé èmi ń dá yín láre; títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.
6 I'm convinced I'm right and will never give up believing this; my conscience will not condemn me as long as I live.
Òdodo mi ni èmi dìímú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́; àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi.
7 May my enemy become like the wicked; may those who oppose me become like those who do evil.
“Kí ọ̀tá mi kí ó dàbí ènìyàn búburú, àti ẹni tí ń dìde sí mi kí ó dàbí ẹni aláìṣòdodo.
8 For what hope do those who reject God have when he cuts them down, when God brings their lives to an end?
Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè, nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde?
9 When times of trouble come to them, will God hear their cry for help?
Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀, nígbà tí ìpọ́njú bá dé sí i?
10 Do they have a good relationship with the Almighty? Can they call on God at any time?
Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè? Òun ha lé máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo?
11 Let me explain God's power to you. I will not keep anything back that the Almighty has planned.
“Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run: ọ̀nà tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́.
12 If all of you have recognized this, why do you talk such vain nonsense?
Kíyèsi i, gbogbo yín ni ó ti rí i; kín ni ìdí ọ̀rọ̀ asán yín?
13 This is what God provides as the destiny for the wicked, this is the inheritance that the ruthless will receive from the Almighty—
“Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè.
14 even if they have many children, they will experience violent deaths or die of starvation.
Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni; àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ.
15 Those who survive will die from disease, and even their widows will not mourn for them.
Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn: àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn.
16 Even though they pile up silver like dust, and clothes like heaps of clay,
Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀;
17 those who do good will wear the clothes and the innocent will divide the silver among them.
àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó; àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀.
18 They build their houses like a moth; like some flimsy shelter made by a watchman.
Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ, àti bí ahéré tí olùṣọ́ kọ́.
19 They go to bed rich, but never again! For when they wake up, it's all gone.
Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò túnṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ.
20 Waves of panic flood over them; in the night a whirlwind snatches them away.
Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn; ẹ̀fúùfù ńlá jí gbé lọ ní òru.
21 The east wind picks them up and they're gone, carried away from where they were.
Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ; àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.
22 The wind blows at them with full force; they try desperately to escape.
Nítorí pé Olódùmarè yóò kọlù ú, kì yóò sì dá sí; òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.
23 People clap their hands at them and hiss at them wherever they are.
Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí, wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.”