< Hosea 8 >

1 Put a trumpet to your lips! An eagle swoops over the house of the Lord because they have broken my agreement and rebelled against my law.
“Fi ìpè sí ẹnu rẹ! Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú, wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.
2 Israel calls out to me, “Our God, we know you!”
Israẹli kígbe pè mí, ‘Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’
3 But Israel has rejected what is good. An enemy will chase after them.
Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀ ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀.
4 They appointed kings without my consent and chose princes without my knowledge. With their silver and gold they made idols for their own destruction.
Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀. Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe ère fún ara wọn, si ìparun ara wọn.
5 Samaria, I reject this calf idol you have made! My anger burns against them! How long will you be incapable of being good?
Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria! Ìbínú mi ń ru sí wọn: yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?
6 This idol is from Israel! A craftsman made it—it's not God! The calf of Samaria will be broken in pieces!
Israẹli ni wọ́n ti wá! Ère yìí agbẹ́gilére ló ṣe é, àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.
7 Those who sow the wind will reap the whirlwind. The stalk has no head of grain; it will produce no flour. Even if it did produce grain, foreigners would swallow it all up.
“Wọ́n gbin afẹ́fẹ́ wọ́n sì ká ìjì. Igi ọkà kò lórí, kò sì ní mú oúnjẹ wá. Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà àwọn àjèjì ni yóò jẹ.
8 Israel is swallowed up; among the nations they are like something nobody wants.
A ti gbé Israẹli mì, báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè bí ohun èlò tí kò wúlò.
9 They have gone up to Assyria like a donkey wandering alone. Ephraim has hired lovers.
Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri. Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.
10 Even though they have hired allies among the nations, I will gather them together. Then they will writhe under the burden of the great king.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín Orílẹ̀-èdè, Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí. Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.
11 Though Ephraim built many altars to make sin offerings, they instead became altars of sin!
“Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
12 I wrote down for them the many aspects of my law, but they looked on them as foreign.
Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì.
13 They present me with their sacrifices, and they eat the meat, but I the Lord do not accept them. Now he will remember their wickedness, and punish them for their sins. They will return to Egypt.
Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi, wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀, ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn. Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọn yóò padà sí Ejibiti.
14 Israel has forgotten his maker, and built palaces; Judah has built many fortified cities. But I will rain fire down on their cities and burn up their fortresses.
Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀ Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀ Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀ ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”

< Hosea 8 >