< Genesis 5 >

1 This is the record of Adam's descendants. When God created human beings, he made them to be like him.
Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a.
2 He created them male and female, and blessed them. On the day he created them he called them “human.”
Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn.
3 When Adam was 130, he had a son who was like him, made in his image; and he named him Seth.
Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún, ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti.
4 Adam lived another 800 years after Seth was born, and had other sons and daughters.
Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
5 Adam lived a total of 930 years, and then he died.
Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n, ó sì kú.
6 When Seth was 105, he had Enosh.
Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùn-ún ọdún, ó bí Enoṣi.
7 Seth lived another 807 years after Enosh was born, and had other sons and daughters.
Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé méje, ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
8 Seth lived a total of 912 years, and then he died.
Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá, ó sì kú.
9 When Enosh was 90, he had Kenan.
Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Kenani.
10 Enosh lived another 815 years after Kenan was born, and had other sons and daughters.
Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin.
11 Enosh lived a total of 905 years, and then he died.
Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún, ó sì kú.
12 When Kenan was 70, he had Mehalalel.
Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún ni ó bí Mahalaleli.
13 Kenan lived another 840 years after Mehalalel was born, and had other sons and daughters.
Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
14 Kenan lived a total of 910 years, and then he died.
Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́wàá, ó sì kú.
15 When Mahalalel was 65, he had Jared.
Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún ni ó bí Jaredi.
16 After Jared was born, Mahalalel lived another 830 years and had other sons and daughters.
Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
17 Mahalalel lived a total of 895 years, and then he died.
Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún, ó sì kú.
18 When Jared was 162, he had Enoch.
Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ọdún ó lé méjì ni ó bí Enoku.
19 After Enoch was born, Jared lived 800 years and had other sons and daughters.
Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
20 Jared lived a total of 962 years, and then he died.
Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún dín méjìdínlógójì, ó sì kú.
21 When Enoch was 65, he had Methuselah.
Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ọdún ó lé márùn ni ó bí Metusela.
22 He had a close relationship with God. After Methuselah was born, Enoch lived another 300 years and had other sons and daughters.
Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
23 Enoch lived a total of 365 years.
Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irinwó ọdún dín márùndínlógójì.
24 Enoch had such a close relationship with God that he didn't die, he just wasn't there anymore, because God took him.
Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ.
25 When Methuselah was 187, he had Lamech.
Nígbà tí Metusela pé igba ọdún dín mẹ́tàlá ní o bí Lameki.
26 After Lamech was born, Methuselah lived another 782 years and had other sons and daughters.
Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún dín méjìdínlógún, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
27 Methuselah lived a total of 969 years, and then he died.
Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n, ó sì kú.
28 When Lamech was 182, he had a son.
Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án ni ó bí ọmọkùnrin kan.
29 He named him Noah, with the explanation, “He will provide relief for us from all the hard manual labor we need to do in cultivating the ground the Lord has cursed.”
Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Olúwa ti fi gégùn ún.”
30 After Noah was born, Lamech lived another 595 years and had other sons and daughters.
Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ọdún dín márùn-ún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
31 Lamech lived a total of 777 years, and then he died.
Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún dín mẹ́tàlélógún, ó sì kú.
32 Noah was 500 before he had Shem, Ham, and Japheth.
Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

< Genesis 5 >