< Ezra 8 >
1 This is a list of the family leaders and genealogical records of those who came back with me from Babylon during the reign of King Artaxerxes:
Wọ̀nyí ni àwọn olórí ìdílé àti àwọn tí ó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn tì wọn gòkè pẹ̀lú mi láti Babeli ní àkókò ìjọba Artasasta ọba:
2 From the sons of Phinehas, Gershom. From the sons of Ithamar, Daniel. From the sons of David, Hattush,
nínú àwọn ọmọ Finehasi: Gerṣomu; nínú àwọn ọmọ Itamari: Daniẹli; nínú àwọn ọmọ Dafidi: Hattusi,
3 son of Shecaniah. From the sons of Parosh, Zechariah, and with him 150 men were registered.
nínú àwọn ọmọ Ṣekaniah; nínú àwọn ọmọ Paroṣi: Sekariah, àti pé àádọ́jọ ọkùnrin fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ;
4 From the sons of Pahath-moab, Eliehoenai, son of Zerahiah, and with him 200 men.
nínú àwọn ọmọ Pahati-Moabu: Elihoenai ọmọ Serahiah àti àwọn igba ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
5 From the sons of Zattu, Shecaniah, son of Jahaziel, and with him 300 men.
nínú àwọn ọmọ Sattu: Ṣekaniah ọmọ Jahasieli àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
6 From the sons of Adin, Ebed, son of Jonathan, and with him 50 men.
nínú àwọn ọmọ Adini: Ebedi ọmọ Jonatani, àti àádọ́ta ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
7 From the sons of Elam, Jeshaiah, son of Athaliah, and with him 70 men.
nínú àwọn ọmọ Elamu: Jeṣaiah ọmọ Ataliah àwọn àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
8 From the sons of Shephatiah, Zebadiah, son of Michael, and with him 80 men.
nínú àwọn ọmọ Ṣefatia: Sebadiah ọmọ Mikaeli, àti ọgọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
9 From the sons of Joab, Obadiah, son of Jehiel, and with him 218 men.
nínú àwọn ọmọ Joabu: Obadiah ọmọ Jehieli àti ogún ó lé nígba ó dín méjì ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
10 From the sons of Bani, Shelomith, son of Josiphiah, and with him 160 men.
nínú àwọn ọmọ Bani: Ṣelomiti ọmọ Josafiah, àti ọgọ́jọ ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
11 From the sons of Bebai, Zechariah, son of Bebai, and with him 28 men.
nínú àwọn ọmọ Bebai: Sekariah ọmọ Bebai àti ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú rẹ̀;
12 From the sons of Azgad, Johanan, son of Hakkatan, and with him 110 men.
nínú àwọn ọmọ Asgadi: Johanani ọmọ Hakatani, àti àádọ́fà ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
13 From the sons of Adonikam, those who were last, their names being Eliphelet, Jeuel, and Shemaiah, and with them 60 men.
nínú àwọn ọmọ Adonikami: àwọn ti ó gbẹ̀yìn, tì orúkọ wọn ń jẹ́ Elifaleti, Jeieli àti Ṣemaiah, àti ọgọ́ta ọkùnrin pẹ̀lú wọn;
14 From the sons of Bigvai, Uthai and Zaccur, and with them 70 men.
nínú àwọn ọmọ Bigfai: Uttai àti Sakkuri, àti àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú wọn.
15 I gathered the returning exiles together at the Ahava Canal. We camped there for three days while I reviewed who had come—the ordinary people, the priests, and the Levites. I discovered there wasn't a single Levite
Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń sàn lọ sí Ahafa, a pàgọ́ síbẹ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárín àwọn ènìyàn àti àárín àwọn àlùfáà, ń kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.
16 so I sent for Eliezer, Ariel, Shemaiah, Elnathan, Jarib, Elnathan, Nathan, Zechariah, and Meshullam, who were leaders, and for Joiarib and Elnathan, who were men with good insight.
Nígbà náà ni mo pe Elieseri, Arieli, Ṣemaiah, Elnatani, Jaribi, Elnatani, Natani, Sekariah, àti Meṣullamu, tí wọ́n jẹ́ olórí, àti Joiaribu àti Elnatani tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀,
17 I told them to go to Iddo, the leader of the Temple servants at Casiphia, asking him and his relatives to send us ministers for the Temple of our God.
mo sì rán wọn tí àwọn ti àṣẹ sí ọ̀dọ̀ Iddo, tí ó jẹ́ olórí ní ibi ti a ń pè ni Kasifia, mo sì sọ fún wọn ohun tí wọn yóò wí fun Iddo àti àwọn Lefi arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹmpili ní Kasifia pé, kí wọn mú àwọn ìránṣẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ wa fún ilé Ọlọ́run wa.
18 Since our gracious God was with us, they brought us Sherebiah, a man with good insight from the sons of Mahli, son of Levi, son of Israel, together with his sons and brothers, a total of eighteen men;
Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣerebiah wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ìran Mahili, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli, àti àwọn ọmọ Ṣerebiah àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìdínlógún.
19 and Hashabiah, along with Jeshaiah, from the sons of Merari, and his brothers and their sons, a total of twenty men.
Àti Haṣabiah, pẹ̀lú Jeṣaiah láti ìran Merari, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ wọ́n jẹ́ ogún ọkùnrin.
20 In addition they brought 220 of the Temple servants, a group appointed by David and his officials to help the Levites. These were all registered by name.
Wọ́n sì tún mú ogún lé nígba àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili wá—àwọn ènìyàn tí Dafidi àti àwọn ìjòyè rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.
21 At the Ahava Canal I called for a fast so we could confess our sins before God and ask him for a safe journey for us and our children, along with all our possessions.
Níbẹ̀, ní ẹ̀bá odò Ahafa, mo kéde àwẹ̀, kí a ba à le rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, kí a sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrìnàjò àìléwu fún wa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ohun ìní wa.
22 I had been reluctant to ask the king to give us a military escort to protect us from enemies on the way. We had told the king, “Our gracious God takes care of everyone who follows him, but shows his anger against anyone who abandons him.”
Mo tijú láti béèrè lọ́wọ́ ọba fún àwọn jagunjagun orí ilẹ̀, àti ti orí ẹṣin láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ní ọ̀nà wa, nítorí àti sọ fún ọba pé, “Ọwọ́ àánú Ọlọ́run wà ní ara gbogbo ẹni tí ó gbé ojú sókè sí i, ṣùgbọ́n ìbínú ńlá rẹ wà lórí ẹni tó kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”
23 So we fasted and asked God to protect us, and he answered our prayers.
Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa.
24 Then I designated twelve of the leading priests, and Sherebiah, Hashabiah, and ten of their brothers,
Nígbà náà ni mo ya àwọn àlùfáà tó jẹ́ aṣáájú méjìlá sọ́tọ̀, pẹ̀lú Ṣerebiah, Haṣabiah àti mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn,
25 and I weighed out and handed them the donations of silver and gold, and the items that the king, his counselors, his leaders, and all the people of Israel there had given for the Temple of our God.
mo sì fi òsùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba, àti ti àwọn ìgbìmọ̀, àti ti àwọn ìjòyè, àti ti gbogbo ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀, tí wọ́n gbe sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa.
26 I weighed out and placed in their hands 650 talents of silver, silver Temple items weighing 100 talents, 100 talents of gold,
Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀ta lé láàádọ́ta tálẹ́ǹtì fàdákà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà,
27 20 gold bowls worth 1,000 darics, and two articles of highly-polished bronze, as valuable as gold.
ogún ago wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún dariki, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí bí i wúrà.
28 I told them, “You are set apart for the Lord, and these Temple items are too. The silver and gold are a voluntary offering to the Lord, the God of your forefathers.
Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohun èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa. Fàdákà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín.
29 You are to guard them and keep them safe until you hand them over, weighing them before the high priests, the Levites and the family leaders in Israel at Jerusalem, in the treasury rooms within the Lord's Temple.”
Ẹ máa tọ́jú wọn dáradára títí ẹ̀yin yóò fi fi òsùwọ̀n wọ̀n wọ́n jáde kúrò ni ilé Olúwa ni Jerusalẹmu ní iwájú àwọn aṣáájú, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti ní iwájú olórí ìdílé gbogbo ni Israẹli.”
30 The priests and Levites took responsibility for the silver and gold and the Temple items that had been weighed out to be brought to the Temple of our God in Jerusalem.
Nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi gba fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ́ tí a ti wọ̀n jáde fún kíkó lọ sí ilé Ọlọ́run wa ní Jerusalẹmu.
31 On the twelfth day of the first month, we left the Ahava Canal to go to Jerusalem, and our God was with us to protect us from enemy ambushes along the way.
Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìn-ín-ní ni a gbéra kúrò ní ẹ̀bá odò Ahafa láti lọ sí Jerusalẹmu. Ọwọ́ Ọlọ́run wa wà lára wa, ó sì dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àti àwọn adigunjalè ní ọ̀nà wa.
32 Eventually we arrived in Jerusalem and rested there for three days.
Bẹ́ẹ̀ ni a gúnlẹ̀ sí Jerusalẹmu, níbi tí a ti sinmi fún ọjọ́ mẹ́ta.
33 On the fourth day the silver and the gold and the Temple items were weighed out in the Temple of our God and handed over to Meremoth, son of Uriah the priest, accompanied by Eleazar, son of Phinehas. Also present were the Levites, Jozabad, son of Jeshua, and Noadiah, son of Binnui.
Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Meremoti ọmọ Uriah lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Eleasari ọmọ Finehasi wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi; Josabadi ọmọ Jeṣua àti Noadiah ọmọ Binnui wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
34 Everything was checked, both by number and weight, and the total weight was written down at the time.
Gbogbo nǹkan ni a kà, tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ní ìgbà náà.
35 Then the exiles who had returned from captivity sacrificed burnt offerings to the God of Israel—twelve bulls for all of Israel, ninety-six rams, seventy-seven lambs, and a sin offering of twelve goats. All were sacrificed as a burnt offering to the Lord.
Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn tí ó ti padà láti ilẹ̀ àjèjì rú ẹbọ sísun sí Ọlọ́run Israẹli: akọ màlúù méjìlá fún gbogbo Israẹli, àgbò mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún, ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin, àti òbúkọ méjìlá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo èyí jẹ́ ẹbọ sísun sí Olúwa.
36 They also delivered the king's decrees to the chief officers of the king and the governors of the province west of the Euphrates, who then provided assistance to the people and to God's Temple.
Wọ́n sì jíṣẹ́ àṣẹ ọba fún àwọn ìjòyè àti àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn àti ilé Ọlọ́run.