< Ezra 4 >

1 The enemies of Judah and Benjamin heard that the exiles were building a Temple to the Lord, the God of Israel.
Nígbà tí àwọn ọ̀tá Juda àti Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ìgbèkùn tí ó padà dé ń kọ́ tẹmpili fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,
2 They came to Zerubbabel and the family leaders and said, “Please let us help you with the building work, for we worship your God like you do. In fact we have been sacrificing to him since the time of Esarhaddon king of Assyria, who brought us here.”
wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Serubbabeli àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé, wọ́n sì wí pé, “Jẹ́ kí a bá a yín kọ́ nítorí pé, bí i tiyín, a ń wá Ọlọ́run yín, a sì ti ń rú ẹbọ sí i láti ìgbà Esarhadoni ọba Asiria, tí ó mú wa wá sí ibi yìí.”
3 But Zerubbabel, Jeshua, and the family leaders of Israel replied, “You can't share with us in building a Temple for our God. Only we can build it for the Lord, the God of Israel. This is what Cyrus the king of Persia has ordered us to do.”
Ṣùgbọ́n Serubbabeli, Jeṣua àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Israẹli dáhùn pé, “Ẹ kò ní ohunkóhun pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa. Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, bí Kirusi, ọba Persia, ti pàṣẹ fún wa.”
4 Then the local people set out to intimidate the people of Judah and make them too scared to go on building.
Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú ọwọ́ àwọn ènìyàn Juda rọ, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n ní ti kíkọ́ ilé náà.
5 They bribed officials to oppose them and to obstruct their plans. This continued during the whole reign of Cyrus king of Persia up until the reign of Darius king of Persia.
Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lòdì sí wọn àti láti sọ ète wọn di asán ní gbogbo àsìkò ìjọba Kirusi ọba Persia àti títí dé ìgbà ìjọba Dariusi ọba Persia.
6 When Ahasuerus became king the local people sent him a written accusation against the people of Judah and Jerusalem.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahaswerusi wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu.
7 During the time of Artaxerxes, king of Persia, Bishlam, Mithredath, Tabeel, and their fellow officers wrote a letter to Artaxerxes. The letter was written in Aramaic and translated from Aramaic.
Àti ní àkókò ìjọba Artasasta ọba Persia, Biṣilami, Mitredati, Tabeli àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Artasasta. A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Aramaiki èdè Aramaiki sì ní a fi kọ ọ́.
8 Rehum the officer in command and Shimshai the scribe wrote a letter to King Artaxerxes condemning Jerusalem stating,
Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé jùmọ̀ kọ́ ìwé láti dojúkọ Jerusalẹmu sí Artasasta ọba báyìí:
9 This comes from Rehum the officer in command, Shimshai the scribe, and fellow officers: the judges and officials and those in charge of Persia, Erech and Babylon, the Elamites of Susa,
Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tókù—àwọn ará Dina, ti Afarsatki, ti Tarpeli, ti Afarsi, Ereki àti Babeli, àwọn ará Elamu ti Susa,
10 and the rest of the people whom the great and noble Ashurbanipal deported and resettled in the towns of Samaria and other places west of the Euphrates.
pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí ẹni ọlá àti ẹni ọ̀wọ̀ Asnappari kó jáde, tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí ìlú Samaria àti níbòmíràn ní agbègbè e Eufurate.
11 The following is a copy of the letter they sent to him. To King Artaxerxes, from your servants, men beyond the River Euphrates:
(Èyí ni ẹ̀dà ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i.) Sí ọba Artasasta, láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin agbègbè Eufurate.
12 Your Majesty should be informed that the Jews who came from you to us have returned to Jerusalem. They are rebuilding that rebellious and wicked city, completing repairs to the walls, and mending its foundations.
Ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn ará Júù tí ó gòkè wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti lọ sí Jerusalẹmu wọ́n sì ń tún ìlú búburú àti ìlú ọlọ̀tẹ̀ ẹ nì kọ́. Wọ́n ń tún àwọn ògiri náà kọ́, wọ́n sì ń tún àwọn ìpìlẹ̀ náà ṣe.
13 Your Majesty should realize that if this city is rebuilt and its walls repaired, they will not pay tax, tribute, or fees, and the king's revenue will suffer.
Síwájú sí i, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù.
14 Now because we are in the king's service and it is not right for us to see Your Majesty disrespected, we are sending this letter so that you can be informed,
Nísinsin yìí níwọ̀n ìgbà tí a ní ojúṣe sí ààfin ọba, kò sì bójúmu fún wa láti rí ìtàbùkù ọba, àwa ń rán iṣẹ́ yìí láti sọ fún ọba,
15 and order a search of the royal archives. You will discover in these records that this is a rebellious city, damaging to kings and countries, having often risen up in revolt in the past. That is what led to this city being destroyed.
kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn aṣíwájú rẹ̀. Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò rí i wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oníwàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́. Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run.
16 We wish to inform Your Majesty that if this city is rebuilt and the walls completed, you will lose this province west of the Euphrates.
A fi dá ọba lójú wí pé tí a bá tún ìlú kọ́ àti ti àwọn ògiri rẹ̀ si di mímọ padà, kì yóò sì ohun ti yóò kù ọ́ kù ní agbègbè Eufurate.
17 The king replied as follows: “To Rehum the commander, Shimshai the scribe, and fellow officers living in Samaria and in other areas west of the Euphrates: Greetings.
Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà. Sí Rehumu balógun, Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí ń gbé ní Samaria àti ní òpópónà Eufurate. Ìkíni.
18 The letter you sent to us has been translated and read to me.
A ti ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi.
19 I ordered a search to be conducted. It was discovered that this city has often risen up in revolt against kings in the past, frequently promoting insurrection and rebellion.
Mo pa àṣẹ, a sì ṣe ìwádìí, nínú ìtàn ọjọ́ pípẹ́ àti ti ìsinsin yìí ti ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba pẹ̀lú, ó sì jẹ́ ibi ìṣọ̀tẹ̀ àti ìrúkèrúdò.
20 Powerful kings have ruled over Jerusalem and throughout the whole area west of the Euphrates, and they received tax, tribute, and fees.
Jerusalẹmu ti ní àwọn ọba alágbára tí ń jẹ ọba lórí gbogbo àwọn agbègbè Eufurate, àti àwọn owó orí, owó òde àti owó ibodè sì ni wọ́n ń san fún wọn.
21 Issue an immediate order for these men to stop work. This city is not to be rebuilt until I authorize it.
Nísinsin yìí pa àṣẹ fún àwọn ọkùnrin yìí láti dá iṣẹ́ dúró, kí a má ṣe tún ìlú náà kọ títí èmi yóò fi pàṣẹ.
22 See that you do not neglect this matter. Why should this problem be allowed to grow and damage royal interests?”
Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe àìkọbi-ara sí ọ̀rọ̀ yìí. Èéṣe tí ìbàjẹ́ yóò fi pọ̀ sí i, sí ìpalára àwọn ọba?
23 As soon as this letter from King Artaxerxes was read to Rehum, Shimshai the scribe, and their fellow officers, they rushed to the Jews in Jerusalem and used their power to forcibly make them stop work.
Ní kété tí a ka ẹ̀dà ìwé ọba Artasasta sí Rehumu àti Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, wọ́n yára lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní Jerusalẹmu pẹ̀lú, wọ́n fi agbára mú wọn láti dáwọ́ dúró.
24 Consequently work on God's Temple in Jerusalem came to a halt. The stoppage continued until the second year of the reign of King Darius of Persia.
Báyìí, iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu wá sí ìdúró jẹ́ẹ́ títí di ọdún kejì ìjọba Dariusi ọba Persia.

< Ezra 4 >