< Ezekiel 10 >
1 I looked up and saw what looked like a throne made of lapis lazuli beyond the expanse, way above the heads of the cherubim.
Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta safire nínú òfúrufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́.
2 Speaking from there the Lord told the man in linen, “Go in between the wheels underneath the cherubim. Collect as many burning coals as you can. Carry them from among the cherubim and scatter them all over the city.” I watched as he went in.
Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárín àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrín kérúbù, kí o sì fọ́n sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lójú mi.
3 The cherubim were standing on the south side of the Temple when the man went in. A cloud filled the inner court.
Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹmpili nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùùkuu sì bo inú àgbàlá.
4 Then the Lord's glory rose up from above the cherubim and moved to the entrance of the Temple. The cloud filled the Temple, and the brightness of the Lord's glory filled the courtyard.
Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹmpili. Ìkùùkuu sì bo inú tẹmpili, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa.
5 The noise made by the cherubim's wings could even be heard in the outer courtyard, and sounded like the voice of God Almighty.
A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà ní ìta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè bá ń sọ̀rọ̀.
6 When the Lord ordered the man in linen, “Go and get some fire from in between the wheels, from among the cherubim,” the man went in and stood beside one of the wheels.
Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, láàrín àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà.
7 Then one of the cherubim reached out and took some of the fire among them. He handed it to the man in linen, who took it and left.
Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ sí ibi iná tó wà láàrín kérúbù yòókù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbà á, ó sì jáde lọ.
8 (All the cherubim had what looked like human hands under their wings.)
(Ohun tó dàbí ọwọ́ ènìyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí.)
9 I saw four wheels next to the cherubim, one wheel beside each cherub. The wheels shone like topaz.
Nígbà tí mo sì wò, kíyèsí i, àwọn kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan; ìrí àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àwọ̀ òkúta berili.
10 All four wheels looked the same, and had a wheel within a wheel, set crossways.
Ní ti ìrísí wọn, gbogbo wọn jọra wọn; ọ̀kọ̀ọ̀kan rí bí ìgbà tí kẹ̀kẹ́ kan wà nínú kẹ̀kẹ́ mìíràn.
11 The cherubim could go in any direction they faced, moving without turning.
Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojúkọ; àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ. Àwọn kérúbù ń lọ sí ibi tí orí dojúkọ láì yà.
12 The whole of their bodies, including their backs, hands, and wings, were covered in eyes, as were all four wheels.
Gbogbo ara wọn àti ẹ̀yìn, ọwọ́ wọn àti ìyẹ́ wọn, àti àwọn kẹ̀kẹ́ kún fún ojú yíkákiri kẹ̀kẹ́, tí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní.
13 I heard the wheels being referred to as “the chariot wheels.”
Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni “kẹ̀kẹ́ àjà.”
14 Each of them had four faces: the first face was a cherub's face, the second a man's face, the third a lion's face, and the fourth an eagle's face.
Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin: ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì.
15 Then the cherubim rose up in the air. They were the beings I'd seen beside the River Kebar.
A gbé àwọn kérúbù sókè. Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò Kebari.
16 When the cherubim moved, the wheels moved alongside them. Even when they opened their wings to take off, the wheels stayed beside them.
Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.
17 When the cherubim stopped, the wheels stopped too. When they took off, the wheels did too, because the spirit of the living creatures was in them.
Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́; bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn.
18 Then the glory of the Lord left the entrance to the Temple and stopped above the cherubim.
Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹmpili, ó sì dúró sórí àwọn kérúbù.
19 As I watched, the cherubim lifted their wings and took off, with the wheels alongside them. They stopped at the entrance of the east gate of the Lord's Temple, and the glory of the God of Israel was above them.
Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lórí wọn.
20 These were the beings I had seen beneath the God of Israel by the River Kebar. I knew that they were cherubim.
Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Israẹli létí odò Kebari, mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n.
21 Each had four faces and four wings and had what looked like human hands under their wings.
Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ mẹ́rin, lábẹ́ ìyẹ́ wọn ni ohun tó jọ ọwọ́ ènìyàn wà.
22 Their faces looked like the faces I had seen by the River Kebar. Each of them moved directly ahead.
Àfiwé ojú àti ìrísí wọn rí bákan náà pẹ̀lú àwọn tí mo rí létí odò Kebari. Olúkúlùkù wọn sì ń lọ sí ọ̀kánkán tààrà.