< Esther 9 >

1 On the thirteenth day of the twelfth month, the month of Adar, the king's order and decree were to be carried out. That day the enemies of the Jews had thought they would crush them, but the exact opposite happened—the Jews crushed their enemies.
Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari, tí ó yẹ kí a mú àṣẹ tí ọba pa wá sí ìmúṣẹ. Ní ọjọ́ yìí ni ọ̀tá àwọn Júù rò pé àwọn yóò borí i wọn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ti yìí padà, àwọn Júù sì na ọwọ́ agbára tó ga lórí àwọn tí ó kórìíra wọn.
2 The Jews gathered in their cities throughout the provinces of King Xerxes to attack those who wanted to destroy them. Nobody could oppose them, because all the other people were afraid of them.
Àwọn Júù péjọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojúkọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tókù ń bẹ̀rù u wọn.
3 All the officials of the provinces, the chief officers, the governors, and the king's officials helped the Jews, because they were afraid of Mordecai.
Gbogbo àwọn ọlọ́lá ìgbèríko, àwọn alákòóso, àwọn baálẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ ọba ran àwọn Júù lọ́wọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù u Mordekai.
4 Mordecai had a great deal of power in the royal palace, and his reputation spread throughout the provinces as his power increased.
Mordekai sì jẹ́ ẹni pàtàkì ní ààfin ọba, òkìkí rẹ̀ sì tàn jákèjádò àwọn ìgbèríko, ó sì ní agbára kún agbára.
5 The Jews attacked their enemies with swords, killing and destroying them, and they did whatever they wanted to their enemies.
Àwọn Júù sì gé gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì run wọ́n, wọ́n sì ṣe ohun tí ó wù wọ́n sí àwọn tí ó kórìíra wọn.
6 In the fortress of Susa, the Jews killed and destroyed five hundred men.
Ní ilé ìṣọ́ ti Susa, àwọn Júù pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin run.
7 This included Parshandatha, Dalphon, Aspatha,
Wọ́n sì tún pa Parṣandata, Dalfoni, Aspata,
8 Poratha, Adalia, Aridatha,
Porata, Adalia, Aridata,
9 Parmashta, Arisai, Aridai, and Vaizatha,
Parmaṣta, Arisai, Aridai àti Faisata.
10 the ten sons of Haman, son of Hammedatha, the enemy of the Jews, but they did not take their possessions.
Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hammedata, ọ̀tá àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn.
11 The same day, when the number of those killed in the fortress of Susa was reported to the king,
Ní ọjọ́ náà gan an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Susa wá fún ọba.
12 he said to Queen Esther, “The Jews have killed and destroyed five hundred men in the fortress of Susa, including Haman's ten sons. Imagine what they've done in the rest of the royal provinces! Now what is it you'd like to ask? It will be given to you. What more do you want? It will be granted.”
Ọba sì sọ fún Esteri ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hamani ní ilé ìṣọ́ Susa run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tókù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.”
13 “If it please Your Majesty,” Esther replied, “allow the Jews in Susa be allowed to do the same tomorrow as they did today, following the decree. Also, let the ten sons of Haman be impaled on poles.”
Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.”
14 The king ordered this to be done. A decree was issued in Susa, and they impaled the bodies of Haman's ten sons.
Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hamani kọ́.
15 On the fourteenth day of the month of Adar, the Jews in Susa gathered together again and killed three hundred men there, but again they did not take their possessions.
Àwọn Júù tí ó wà ní Susa sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Susa, ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn.
16 The other Jews in the king's provinces also gathered to defend themselves and get rid of their enemies. They killed 75,000 who hated them, but did not touch their possessions.
Lákokò yìí, àwọn tókù nínú àwọn Júù tí wọ́n wà ní agbègbè ọba náà tún kó ara wọn jọ láti dáàbò bo ara wọn kí wọn sì sinmi lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn. Wọ́n sì pa ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rin àwọn tí ó kórìíra wọn ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn.
17 This happened on the thirteenth day of the month of Adar, and on the fourteenth day they rested and made it a day of feasting and celebration.
Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Addari, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀.
18 However, the Jews in Susa had gathered to fight on the thirteenth and the fourteenth days of the month. So they rested on the fifteenth day, and made that a day of feasting and celebration.
Àwọn Júù tí ó wà ní Susa, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀.
19 To this day rural Jews, living in the villages, observe the fourteenth day of the month of Adar as a day of celebration and feasting, a holiday when they send gifts to one another.
Nítorí náà ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn.
20 Mordecai recorded these events and sent letters to all the Jews throughout the provinces ruled by King Xerxes, near and far,
Mordekai ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ahaswerusi, tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré,
21 requiring them to celebrate every year the fourteenth and fifteenth days of the month of Adar
láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù Addari ní ọdọọdún.
22 as the time when the Jews rested from their victory over their enemies, and as the month when their sadness was turned into joy and their mourning into a time of celebration. He wrote them to observe the days as days of feasting and joy and giving gifts of food to one another and presents to the poor.
gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní.
23 The Jews agreed to continue what they had already started doing, following what Mordecai had written to them.
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe bí Mordekai ti kọ̀wé sí wọn.
24 For Haman, son of Hammedatha, the Agagite, the enemy of all the Jews, had plotted to destroy the Jews, and had cast “pur” (meaning a “lot”) to crush and destroy them.
Nítorí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá gbogbo àwọn Júù, ti gbèrò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di puri (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìsọdahoro àti ìparun wọn.
25 But when it came to the king's attention, he sent out letters ordering that the evil scheme which Haman had planned against the Jews should rebound on him, and that he and his sons should be impaled on poles.
Ṣùgbọ́n nígbà tí Esteri sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hamani ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí òun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi.
26 (That's why these days are called Purim, from the word Pur.) As a result of all the instructions in Mordecai's letter, and what they'd seen, and what had happened to them,
(Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Purimu, láti ara ọ̀rọ̀ puri). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn,
27 the Jews committed themselves to adopt the practice that they and their descendants and all who join them should not forget to celebrate these two days as set down, and at the right time every year.
àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn.
28 These days were to be remembered and celebrated by every generation, family, province, and city, so that these days of Purim would always be observed among the Jews, and they would not be forgotten by their descendants.
A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kí a sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Purimu wọ̀nyí ní àárín àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrín irú àwọn ọmọ wọn.
29 Then Queen Esther, the daughter of Abihail, wrote a letter, along with Mordecai the Jew, giving in her letter full authority to Mordecai's letter about Purim.
Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ayaba, ọmọbìnrin Abihaili, pẹ̀lú Mordekai ará a Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Purimu yìí múlẹ̀.
30 Letters expressing peace and reassurance were also sent all the Jews in the 127 provinces of the empire of King Xerxes.
Mordekai sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbèríko mẹ́tàdínláàádóje ní ilẹ̀ ọba Ahaswerusi ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́.
31 They established these days of Purim at their given time as Mordecai the Jew and Queen Esther had ordered, committing themselves and their descendants to the times of fasting and mourning.
Láti fi ìdí àwọn ọjọ́ ọ Purimu yìí múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n yàn, gẹ́gẹ́ bí Mordekai ará Juda, àti Esteri ayaba ti pa á láṣẹ fún wọn, àti bí wọ́n ṣe fi lélẹ̀ fún ara wọn àti irú àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àkókò àwẹ̀ àti ẹkún wọn.
32 In this way Esther's decree confirmed these practices regarding Purim, which were entered in the official record.
Àṣẹ Esteri sì fi ìdí ìlànà Purimu wọ̀nyí múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé àkọsílẹ̀.

< Esther 9 >