< Esther 1 >
1 This is an account of what happened during the time of King Xerxes, the Xerxes who ruled over 127 provinces from India to Ethiopia.
Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Ahaswerusi, tí ó jẹ ọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje ìletò bẹ̀rẹ̀ láti India títí ó fi dé Etiopia.
2 At the time King Xerxes was ruling from his royal throne at the fortress in Susa.
Ní àkókò ìgbà náà ọba Ahaswerusi ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Susa,
3 In the third year of his reign he organized a feast for his officials and administrators. The army commanders of Persia and Media, the nobles, and the provincial officials were all there with him.
ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí ológun láti Persia àti Media, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
4 He put on display his wealth and the glory of his kingdom, showing how majestic, splendid, and glorious he was, for 180 days.
Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọláńlá rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko.
5 After that the king gave a feast lasting for seven days for all the people, great and small, who were there in the fortress of Susa in the garden courtyard of the king's pavilion.
Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba ṣe àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa.
6 It was decorated with white and blue cotton curtains tied with cords of fine linen and purple thread on silver rings, held up by marble pillars. Gold and silver couches were placed on a pavement made of purple porphyry, marble, mother-of-pearl, and expensive stones.
Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elése àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mabu. Àwọn ibùsùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mabu, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn.
7 Drinks were served in golden goblets of different kinds, and the royal wine flowed freely because of the king's generosity.
Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí.
8 The king had ruled that there was to be no limit on how much a guest could drink; he had told his servants to give each guest whatever they wanted.
Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ.
9 Queen Vashti also gave a feast for the women in the palace that belonged to King Xerxes.
Ayaba Faṣti náà ṣe àsè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ahaswerusi.
10 On the seventh day of the feast, the king, feeling happy from drinking wine, ordered the seven eunuchs who were his attendants, Mehuman, Biztha, Harbona, Bigtha, Abagtha, Zethar, and Karkas,
Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Mehumani, Bista, Harbona, Bigta àti Abagta, Setari àti Karkasi, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún Ahaswerusi.
11 to bring Queen Vashti to him wearing her royal headdress, so he could show her beauty to the people and officials, for she was very good-looking.
Kí wọn mú ayaba Faṣti wá síwájú rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà.
12 But when the eunuchs delivered the order from the king, Queen Vashti refused to come. The king became extremely angry—he was absolutely furious.
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Faṣti kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidigidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.
13 Then the king spoke with the wise men who would know what to do, for it was the custom for him to ask the opinion of experts in procedures and legal matters.
Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò,
14 Those closest to him were Carshena, Shethar, Admatha, Tarshish, Meres, Marsena, and Memucan. They were the seven nobles of Persia and Media who had frequent meetings with the king and had the highest positions in the kingdom.
àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena àti Memukani, àwọn ọlọ́lá méje ti Persia àti Media tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba.
15 “What does the law say should be done with Queen Vashti?” he asked. “She refused to obey the direct order of King Xerxes as delivered by the eunuchs!”
Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Faṣti gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ahaswerusi tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.”
16 Memucan gave his answer before the king and the nobles, “Queen Vashti hasn't just insulted the king but all the nobles and all the people of all the provinces of King Xerxes.
Memukani sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Faṣti ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba Ahaswerusi.
17 Once it gets out what the queen has done, all wives will despise their husbands, looking down on them and telling them, ‘King Xerxes ordered Queen Vashti brought to him but she didn't come!’
Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obìnrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójú u wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ahaswerusi pàṣẹ pé kí á mú ayaba Faṣti wá síwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá.
18 By the end of the day, the wives of all the nobles throughout Persia and Media who have heard what the queen did will treat their noble husbands with angry contempt!
Ní ọjọ́ yìí gan an ni àwọn ọlọ́lá obìnrin Persia àti ti Media tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà.
19 If it please Your Majesty, issue a royal decree, in accordance with the laws of Persia and Media which cannot be changed, that Vashti is banished from the presence of King Xerxes, and that Your Majesty will give her royal position to another, one who is better than her.
“Nítorí náà, bí ó bá tọ́ lójú ọba, jẹ́ kí ó gbé àṣẹ ọba jáde, kí ó sì jẹ́ kí ó wà ní àkọsílẹ̀ pẹ̀lú òfin Persia àti Media, èyí tí kò le é parẹ́, pé kí Faṣti kí ó má ṣe wá síwájú ọba Ahaswerusi. Kí ọba sì fi oyè ayaba rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ.
20 When Your Majesty's decree is proclaimed throughout your vast empire, all wives will respect their husbands, highborn or lowborn.”
Nígbà náà tí a bá kéde òfin tí ọba ṣe ká gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin ni yóò bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó kéré títí dé ọ̀dọ̀ ẹni ńlá.”
21 This advice looked good to the king and the nobles, so the king did what Memucan had said.
Ìmọ̀ràn yìí sì tẹ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ́rùn, nítorí náà ọba ṣe gẹ́gẹ́ bí Memukani ṣé sọ.
22 He sent letters to all provinces in the empire, in each province's script and language, that every man should rule his own home, and use his own mother tongue.
Ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ọba rẹ̀, ó kọ̀wé sí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, Ó tẹnumọ́ ní èdè oníkálùkù pé kí olúkúlùkù ọkùnrin máa ṣàkóso ilé rẹ̀.