< 1 Samuel 25 >
1 Samuel died. Everyone in Israel gathered to mourn for him, and they buried him at his home in Ramah. David left and went to the Desert of Paran.
Samuẹli sì kú; gbogbo ènìyàn Israẹli sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sọkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama. Dafidi sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Parani.
2 A man from Maon was very wealthy. He had property in Carmel and owned one thousand goats and three thousand sheep. He was in Carmel shearing them.
Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Maoni, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Karmeli; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli.
3 The man's name was Nabal, and his wife's name was Abigail. She was a wise and beautiful woman, but her husband was cruel and treated people badly. He was a descendant of Caleb.
Orúkọ ọkùnrin náà sì ń jẹ́ Nabali, orúkọ aya rẹ̀ ń jẹ́ Abigaili; òun sì jẹ́ olóye obìnrin, àti arẹwà ènìyàn; ṣùgbọ́n òǹrorò àti oníwà búburú ni ọkùnrin; ẹni ìdílé Kalebu ni òun jẹ́.
4 David was in the wilderness, and he heard that Nabal was shearing sheep.
Dafidi sì gbọ́ ní aginjù pé Nabali ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀.
5 So David sent ten of his young men and told them, “Go and see Nabal at Carmel. Greet him in my name, and say hello from me.
Dafidi sì rán ọmọkùnrin mẹ́wàá, Dafidi sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, “Ẹ gòkè lọ sí Karmeli, kí ẹ sì tọ Nabali lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi.
6 Tell him, ‘I wish you a long life! Peace to you and your family, and may everything you do prosper.
Báyìí ni ẹ ó sì wí fún ẹni tí ó wà ni ìrora pé, ‘Àlàáfíà fún ọ! Àlàáfíà fún ohun gbogbo tí ìwọ ní!
7 Now I've heard that you are busy shearing. When your shepherds were with us, we didn't mistreat them, and nothing belonging to them was stolen all the time they were in Carmel.
“‘Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ́run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ. Wò ó, àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pa wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Karmeli.
8 Check with your men and they'll confirm it. Please be kind to my men, especially since we've come on this day of celebration. Please give whatever food you can to us and to your good friend David.’”
Bi àwọn ọmọkùnrin rẹ léèrè, wọn ó sì sọ fún ọ. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí rí ojúrere lọ́dọ̀ rẹ; nítorí pé àwa sá wá ní ọjọ́ àsè: èmi bẹ̀ ọ́ ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà, fi fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àti fún Dafidi ọmọ rẹ.’”
9 David's young men arrived, gave Nabal this message from David, and waited for his reply.
Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì lọ, wọ́n sì sọ fún Nabali gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní orúkọ Dafidi, wọ́n sì sinmi.
10 “Who does this ‘David, son of Jesse’ think he is?” Nabal replied. “Nowadays there are many servants on the run from their masters!
Nabali sì dá àwọn ìránṣẹ́ Dafidi lóhùn pé, “Ta ni ń jẹ́ Dafidi? Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jese? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìránṣẹ́ ni ń bẹ ni ìsinsin yìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀.
11 Why should I take the bread and water I've supplied, and the meat I've slaughtered for my shearers, and hand it over to these strangers? I don't even know where they're from!”
Ǹjẹ́ ki èmi o mú oúnjẹ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pa fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi sì fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá?”
12 So David's men turned around and went back the way they came. When they got back they told David everything Nabal had said.
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì padà, wọ́n sì wá, wọn si rò fún un gẹ́gẹ́ bi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
13 “Everyone, put on your swords!” David ordered. They all put on their swords, and David did too. About four hundred followed David, while two hundred remained behind to guard their gear.
Dafidi sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí olúkúlùkù yín ó di idà rẹ́ mọ́ ìdí,” olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ̀ mọ́ ìdí; àti Dafidi pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀; ìwọ̀n irinwó ọmọkùnrin si gòkè tọ Dafidi lẹ́yìn; igba si jókòó níbi ẹrù.
14 In the meantime one of Nabal's men told Abigail, Nabal's wife, “David sent some messengers from the wilderness to bring greetings to our master, but he only insulted them.
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin Nabali si wí fún Abigaili aya rẹ̀ pé, “Wo o, Dafidi rán oníṣẹ́ láti aginjù wá láti kí olúwa wa; ó sì kanra mọ́ wọn.
15 David's men were always very good to us and they never mistreated us. All the time we were out in the fields with them nothing was stolen from us.
Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà ṣe oore fún wa gidigidi, wọn kò ṣe wá ní ibi kan, ohunkóhun kò nù ni ọwọ́ wa ni gbogbo ọjọ́ ti àwa bá wọn rìn nígbà ti àwa ń bẹ lóko.
16 They were like a protective wall to us, both day and night, during the whole time we were with them looking after the sheep.
Odi ni wọ́n sá à jásí fún wa lọ́sàn án, àti lóru, ni gbogbo ọjọ́ ti a fi bá wọn gbé, tí a n bojútó àwọn àgùntàn.
17 You should know what happened and consider what you should do about it. Disaster is about to strike our master and his whole family, but he's so obnoxious no one can talk sense into him!”
Ǹjẹ́, rò ó wò, kí ìwọ sì mọ èyí ti ìwọ yóò ṣe; nítorí pé a ti gbèrò ibi sí olúwa wa, àti sí gbogbo ilé rẹ̀; òun sì jásí ọmọ Beliali tí a kò le sọ̀rọ̀ fún.”
18 Abigail quickly gathered together two hundred loaves of bread, two skins of wine, five sheep already slaughtered, five seahs of roasted grain, a hundred raisin cakes, and two hundred fig cakes, and then loaded everything on donkeys.
Abigaili sì yára, ó sì mú igbá ìṣù àkàrà àti ìgò ọtí wáìnì méjì, àti àgùntàn márùn-ún, tí a ti ṣè, àti òsùwọ̀n àgbàdo yíyan márùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún ìdì àjàrà, àti igba àkàrà èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì dìwọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
19 She told her men, “Go on ahead. I'll follow you.” But she didn't say anything to her husband Nabal.
Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Máa lọ níwájú mi; wò ó, èmi ń bọ̀ lẹ́yìn yín,” ṣùgbọ́n òun kò wí fún Nabali baálé rẹ̀.
20 As Abigail was riding her donkey through a mountain valley, she saw David and his men descending towards her, and she met them.
Bí o ti gun orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sì ń sọ̀kalẹ̀ sí ibi ìkọ̀kọ̀ òkè náà, wò ó, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ níwájú rẹ̀; òun sì wá pàdé wọn.
21 David had just been complaining, “So much for my protecting everything that belonged to this man in the wilderness! Nothing at all was stolen from him, and yet what does he do? Pay me back evil for good!
Dafidi sì ti wí pé, “Ǹjẹ́ lásán ni èmi ti pa gbogbo èyí tí i ṣe ti eléyìí ní aginjù, ti ohunkóhun kò sì nù nínú gbogbo èyí ti í ṣe tirẹ̀: òun ni ó sì fi ibi san ìre fún mi yìí.
22 May God punish me very severely if I leave even a single one of his men alive by morning!”
Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀tá Dafidi, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.”
23 When Abigail saw David, she quickly got off the donkey, and bowed before him, her face to the ground.
Abigaili sì rí Dafidi, ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú Dafidi, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.
24 Falling at his feet in respect, she said, “Sir, I accept full responsibility for what's happened. Please listen to what I, your servant, have to say.
Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yìí yá mi: kí ó sì jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, sọ̀rọ̀ létí rẹ, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.
25 Please don't concern yourself with this worthless man Nabal. His name means ‘fool,’ and he is really foolish! As for me, your servant, I didn't even see the men you sent.
Olúwa mi, èmi bẹ̀ ọ́ má ka ọkùnrin Beliali yìí sí, àní Nabali. Nítorí pé bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òun náà rí. Nabali ni orúkọ rẹ̀, àìmoye si wà pẹ̀lú rẹ̀; ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò ri àwọn ọmọkùnrin olúwa mi, ti ìwọ rán.
26 Now, sir, as the Lord lives and as you live, the Lord has kept you from shedding blood and from taking your own revenge. Sir, may your enemies and those who want to do you harm be like Nabal.
Ǹjẹ́ olúwa mi, bi Olúwa ti wà láààyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láààyè, bi Olúwa sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gba ẹ̀san; ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀tá rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbèrò ibi sí olúwa mi rí bi i Nabali.
27 Please accept this present that I, your servant, have brought to you, sir, and give it to your men.
Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn.
28 Please forgive any offense that I, your servant, have committed, for the Lord is sure to set up a dynasty for you that will last for a long time, because you, sir, fight the battles of the Lord. Wickedness should not be found in you as long as you live.
“Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ín, nítorí Olúwa yóò sá ṣe ilé òdodo fún olúwa mi, nítorí pé ó ja ogun Olúwa. Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láààyè.
29 If anyone pursues you and tries to kill you, then your life will remain bound up with those the Lord your God looks after, safe in his care. But he will throw away the lives of your enemies like stones from a sling.
Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi nínú ìdì ìyè lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde.
30 So when the Lord has done for you, sir, everything good he promised, and has made you ruler over Israel,
Yóò sì ṣe, Olúwa yóò ṣe sí olúwa mi gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìre tí ó ti wí nípa tirẹ̀, yóò sì yàn ọ́ ni aláṣẹ lórí Israẹli.
31 you won't have feelings of remorse or a guilty conscience over unnecessary bloodshed or of taking your own revenge. And when the Lord has done these good things for you, sir, please remember me, your maidservant.”
Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ́ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gba ẹ̀san fún ara rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí Olúwa ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ!”
32 Then David said to Abigail, “Praise the Lord, the God of Israel, who sent you to meet me today!
Dafidi sì wí fún Abigaili pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi.
33 May you be rewarded for your wise decisions, for preventing me from shedding blood today and taking my own revenge.
Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún sì ni ìwọ, tí ó da mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ mi gba ẹ̀san fún ara mi.
34 On the contrary, as the Lord, the God of Israel, lives, who has kept me from harming you, if you hadn't rushed to meet me, then definitely not a single one of Nabal's men would have been left alive by dawn.”
Nítòótọ́, bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí ń bẹ, tí ó da mi dúró láti pa ọ́ lára bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì wá pàdé mi, nítòótọ́ kì bá tí kù fún Nabali di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀.”
35 David accepted from Abigail what she had brought him, and told her, “You may go home in peace, because I agree with your advice and grant your request.”
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gba nǹkan tí ó mú wá fún un lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Gòkè lọ ni àlàáfíà sí ilé rẹ, wò ó, èmi ti gbọ́ ohùn rẹ, inú mi sì dùn sí ọ.”
36 When Abigail got back home to Nabal, he was in the house, partying like a king. He was feeling very merry, and he was very drunk. So she didn't tell him anything until the morning.
Abigaili sì tọ Nabali wá, sì wò ó, òun sì ṣe àsè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àsè ọba: inú Nabali sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara; òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀: títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀
37 When Nabal had sobered up the next morning, his wife told him what had happened. When he heard what she had to say he had a heart attack and was paralyzed.
Ó sì ṣe; ni òwúrọ̀, nígbà ti ọtí náà si dá tán lójú Nabali, obìnrin rẹ̀ sì ro nǹkan wọ̀nyí fún un, ọkàn rẹ sì kú nínú rẹ̀, òun sì dàbí òkúta.
38 About ten days later the Lord struck Nabal down and he died.
Ó sì ṣe lẹ́yìn ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́wàá, Olúwa lu Nabali, ó sì kú.
39 When David heard that Nabal was dead, he said, “Praise the Lord who has supported me against Nabal's insult and has kept me from doing evil. For the Lord made Nabal's wickedness fall back on himself.” Then David sent a message to Abigail, asking for her to marry him.
Dafidi sì gbọ́ pé Nabali kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbèjà gígàn mi láti ọwọ́ Nabali wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: Olúwa sì yí ìkà Nabali sí orí òun tìkára rẹ̀.” Dafidi sì ránṣẹ́, ó sì ba Abigaili sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀.
40 When David's men arrived at Carmel, they said to Abigail, “David has sent us to you to bring you back to become his wife.”
Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì lọ sọ́dọ̀ Abigaili ni Karmeli, wọn sì sọ fún un pé, “Dafidi rán wá si ọ láti mu ọ ṣe aya rẹ̀.”
41 She stood up, then bowed down low, and said, “I am David's maidservant. I am prepared to serve and to wash the feet of my master's servants.”
Ó sì dìde, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ó jẹ́ ìránṣẹ́ kan láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.”
42 Abigail quickly got on a donkey and, with her five female servants, went back with David's men and became his wife.
Abigaili sì yára, ó sì dìde, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ márùn-ún sì tẹ̀lé e lẹ́yìn; òun sì tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, o sì wá di aya rẹ̀.
43 David had also married Ahinoam of Jezreel. So they both were his wives.
Dafidi sì mú Ahinoamu ará Jesreeli; àwọn méjèèjì sì jẹ́ aya rẹ̀.
44 However, Saul had given his daughter Michal, David's wife, to Paltiel, son of Laish. He was from Gallim.
Ṣùgbọ́n Saulu ti fi Mikali ọmọ rẹ̀ obìnrin aya Dafidi, fún Palti ọmọ Laiṣi tí i ṣe ara Galimu.