< Psalms 62 >
1 Unto the end, for Idithun, a psalm of David. Shall not my soul be subject to God? for from him is my salvation.
Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
2 For he is my God and my saviour: he is my protector, I shall be moved no more.
Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.
3 How long do you rush in upon a man? you all kill, as if you were thrusting down a leaning wall, and a tottering fence.
Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
4 But they have thought to cast away my price; I ran in thirst: they blessed with their mouth, but cursed with their heart.
Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá rẹ̀; inú wọn dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. (Sela)
5 But be thou, O my soul, subject to God: for from him is my patience.
Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
6 For he is my God and my saviour: he is my helper, I shall not be moved.
Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
7 In God is my salvation and my glory: he is the God of my help, and my hope is in God.
Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
8 Trust in him, all ye congregation of people: pour out your hearts before him. God is our helper for ever.
Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn rẹ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.
9 But vain are the sons of men, the sons of men are liars in the balances: that by vanity they may together deceive.
Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n, lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
10 Trust not in iniquity, and cover not robberies: if riches abound, set not your heart upon them.
Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i, má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.
11 God hath spoken once, these two things have I heard, that power belongeth to God,
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo gbọ́ èyí pé, “Ti Ọlọ́run ni agbára,
12 And mercy to thee, O Lord; for thou wilt render to every man according to his works.
pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú; nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.”