< Ecclesiastes 9 >
1 For all this I laid to my heart and [indeed] to investigate all this, that the righteous, and the wise, and their works, are in the hand of God; man knoweth neither love nor hatred: all is before them.
Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olóòtọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bóyá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun.
2 All things [come] alike to all: one event to the righteous and to the wicked, to the good, and to the clean, and to the unclean, to him that sacrificeth and to him that sacrificeth not: as is the good, so is the sinner; he that sweareth, as he that feareth an oath.
Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ. Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rere bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra.
3 This is an evil among all that is done under the sun, that one thing befalleth all: yea, also the heart of the children of men is full of evil, and madness is in their heart while they live; and after that, [they have to go] to the dead.
Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú.
4 For to him that is joined to all the living there is hope; for a living dog is better than a dead lion.
Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!
5 For the living know that they shall die; but the dead know not anything, neither have they any more a reward, for the memory of them is forgotten.
Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan wọn kò ní èrè kankan mọ́, àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.
6 Their love also, and their hatred, and their envy is already perished; neither have they any more for ever a portion in all that is done under the sun.
Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn, àti ìlara wọn ti parẹ́: láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.
7 Go, eat thy bread with joy, and drink thy wine with a merry heart; for God hath already accepted thy works.
Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe.
8 Let thy garments be always white, and let not thy head lack oil.
Máa wọ aṣọ funfun nígbàkígbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo.
9 Enjoy life with the wife whom thou lovest all the days of the life of thy vanity, which he hath given thee under the sun, all the days of thy vanity; for that is thy portion in life, and in thy labour wherein thou art labouring under the sun.
Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn.
10 Whatever thy hand findeth to do, do with thy might; for there is no work, nor device, nor knowledge, nor wisdom, in Sheol, whither thou goest. (Sheol )
Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ. (Sheol )
11 I returned, and saw under the sun, that the race is not to the swift, nor the battle to the strong, neither yet bread to the wise, nor yet riches to the intelligent, nor yet favour to men of knowledge; but time and chance happeneth to them all.
Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn. Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára tàbí ogun fún alágbára, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye tàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀; ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.
12 For man also knoweth not his time: as the fishes that are taken in an evil net, and as the birds that are taken with the snare, like them are the children of men snared in an evil time, when it falleth suddenly upon them.
Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé, gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.
13 This also have I seen as wisdom under the sun, and it was great unto me.
Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn.
14 There was a little city, and few men within it; and there came a great king against it, and encompassed it, and built great bulwarks against it:
Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yí i po, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì sí i.
15 and there was found in it a poor wise man, who by his wisdom delivered the city; but no man remembered that poor man.
Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin tálákà náà.
16 Then said I, Wisdom is better than strength; but the poor man's wisdom is despised, and his words are not heard.
Nítorí náà mo sọ wí pé, “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin tálákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.
17 The words of the wise are heard in quiet more than the cry of him that ruleth among fools.
Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmúṣẹ ju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.
18 Wisdom is better than weapons of war; but one sinner destroyeth much good.
Ọgbọ́n dára ju ohun èlò ogun lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkan tó dẹ́ṣẹ̀ a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.