< 1 Peter 1 >
1 Peter, apostle of Jesus Christ, to [the] sojourners of [the] dispersion of Pontus, Galatia, Cappadocia, Asia, and Bithynia,
Peteru, aposteli Jesu Kristi, Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, tiwọn tú káàkiri sí Pọntu, Galatia, Kappadokia, Asia, àti Bitinia,
2 elect according to [the] foreknowledge of God [the] Father, by sanctification of [the] Spirit, unto [the] obedience and sprinkling of [the] blood of Jesus Christ: Grace to you and peace be multiplied.
àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi: Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín.
3 Blessed [be] the God and Father of our Lord Jesus Christ, who, according to his great mercy, has begotten us again to a living hope through [the] resurrection of Jesus Christ from among [the] dead,
Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú,
4 to an incorruptible and undefiled and unfading inheritance, reserved in [the] heavens for you,
àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin,
5 who are kept guarded by [the] power of God through faith for salvation ready to be revealed in [the] last time.
ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn.
6 Wherein ye exult, for a little while at present, if needed, put to grief by various trials,
Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́.
7 that the proving of your faith, much more precious than of gold which perishes, though it be proved by fire, be found to praise and glory and honour in [the] revelation of Jesus Christ:
Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.
8 whom, having not seen, ye love; on whom [though] not now looking, but believing, ye exult with joy unspeakable and filled with [the] glory,
Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo;
9 receiving the end of your faith, [the] salvation of [your] souls.
ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín.
10 Concerning which salvation prophets, who have prophesied of the grace towards you, sought out and searched out;
Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wọ́n wádìí jinlẹ̀ lẹ́sọ̀ lẹ́sọ̀.
11 searching what, or what manner of time, the Spirit of Christ which [was] in them pointed out, testifying before of the sufferings which [belonged] to Christ, and the glories after these.
Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sá à wo ni Ẹ̀mí Kristi tí ó wà nínú wọ́n ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kristi àti ògo tí yóò tẹ̀lé e.
12 To whom it was revealed, that not to themselves but to you they ministered those things, which have now been announced to you by those who have declared to you the glad tidings by [the] Holy Spirit, sent from heaven, which angels desire to look into.
Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìyìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.
13 Wherefore, having girded up the loins of your mind, [be] sober [and] hope with perfect stedfastness in the grace [which will be] brought to you at [the] revelation of Jesus Christ;
Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.
14 as children of obedience, not conformed to [your] former lusts in your ignorance;
Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́.
15 but as he who has called you is holy, be ye also holy in all [your] conversation;
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́.
16 because it is written, Be ye holy, for I am holy.
Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”
17 And if ye invoke as Father him who, without regard of persons, judges according to the work of each, pass your time of sojourn in fear,
Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù.
18 knowing that ye have been redeemed, not by corruptible [things, as] silver or gold, from your vain conversation handed down from [your] fathers,
Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.
19 but by precious blood, as of a lamb without blemish and without spot, [the blood] of Christ,
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi.
20 foreknown indeed before [the] foundation of [the] world, but who has been manifested at the end of times for your sakes,
Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín.
21 who by him do believe on God, who has raised him from among [the] dead and given him glory, that your faith and hope should be in God.
Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
22 Having purified your souls by obedience to the truth to unfeigned brotherly love, love one another out of a pure heart fervently;
Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá.
23 being born again, not of corruptible seed, but of incorruptible, by [the] living and abiding word of God. (aiōn )
Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró. (aiōn )
24 Because all flesh [is] as grass, and all its glory as [the] flower of grass. The grass has withered and [its] flower has fallen;
Nítorí pé, “Gbogbo ènìyàn dàbí koríko, àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko. Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,
25 but the word of [the] Lord abides for eternity. But this is the word which in the glad tidings [is] preached to you. (aiōn )
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.” Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìnrere tí a wàásù fún yín. (aiōn )