< 1 Kings 9 >
1 And it came to pass when Solomon had completed the building of the house of Jehovah, and the king's house, and all Solomon's desire which he was pleased to do,
Nígbà tí Solomoni sì parí kíkọ́ ilé Olúwa àti ààfin ọba, tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó ń fẹ́ láti ṣe,
2 that Jehovah appeared to Solomon the second time, as he had appeared to him at Gibeon.
Olúwa sì farahàn Solomoni ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gibeoni.
3 And Jehovah said to him, I have heard thy prayer and thy supplication which thou hast made before me: I have hallowed this house, which thou hast built, to put my name there for ever; and mine eyes and my heart shall be there perpetually.
Olúwa sì wí fún un pé, “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ tí ìwọ ti bẹ̀ níwájú mi, mo ti ya ilé yìí sí mímọ́, tí ìwọ ti kọ́, nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. Ojú mi àti ọkàn mi yóò wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.
4 And [as for] thee, if thou wilt walk before me, as David thy father walked, in integrity of heart, and in uprightness, to do according to all that I have commanded thee, [and] wilt keep my statutes and mine ordinances;
“Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dafidi baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́,
5 then will I establish the throne of thy kingdom over Israel for ever, as I promised to David thy father, saying, There shall not fail thee a man upon the throne of Israel.
Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dafidi baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’
6 [But] if ye shall at all turn from following me, ye or your children, and will not keep my commandments, my statutes which I have set before you, but go and serve other gods, and worship them;
“Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,
7 then will I cut off Israel out of the land which I have given them; and the house, which I have hallowed to my name, will I cast out of my sight; and Israel shall be a proverb and a by word among all peoples;
nígbà náà ni èmi yóò ké Israẹli kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Israẹli yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè.
8 and this house, [which] is high, every one that passes by it shall be astonished at, and shall hiss, and they shall say, Why has Jehovah done thus to this land and to this house?
Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’
9 And they shall say, Because they forsook Jehovah their God, who brought forth their fathers out of the land of Egypt, and have attached themselves to other gods, and have worshipped them and served them; therefore has Jehovah brought upon them all this evil.
Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn baba wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti gbá ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn.’”
10 And it came to pass at the end of twenty years, when Solomon had built the two houses, the house of Jehovah and the king's house,
Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Solomoni kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba.
11 Hiram the king of Tyre having furnished Solomon with cedar-trees and cypress-trees, and with gold, according to all his desire, — that then king Solomon gave Hiram twenty cities in the land of Galilee.
Solomoni ọba sì fi ogún ìlú ní Galili fún Hiramu ọba Tire, nítorí tí Hiramu ti bá a wá igi kedari àti igi firi àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀.
12 And Hiram came out from Tyre to see the cities that Solomon had given him; and they did not please him.
Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn.
13 And he said, What cities are these which thou hast given me, my brother? And he called them the land of Cabul to this day.
Ó sì wí pé, “Irú ìlú wo nìwọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi?” Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ Kabulu títí fi di òní yìí.
14 And Hiram had sent to the king one hundred and twenty talents of gold.
Hiramu sì ti fi ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà ránṣẹ́ sí ọba.
15 And this is the account of the levy which king Solomon raised, to build the house of Jehovah, and his own house, and Millo, and the wall of Jerusalem, and Hazor, and Megiddo, and Gezer.
Ìdí àwọn asìnrú ti Solomoni ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkára rẹ̀; Millo, odi Jerusalẹmu, Hasori, Megido àti Geseri.
16 — Pharaoh king of Egypt had gone up and taken Gezer, and burned it with fire, and slain the Canaanites that dwelt in the city, and given it as a dowry to his daughter, Solomon's wife.
Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ.
17 — And Solomon built Gezer, and lower Beth-horon,
Solomoni sì tún Geseri kọ́, àti Beti-Horoni ìsàlẹ̀,
18 and Baalath, and Tadmor in the wilderness, in the land,
àti Baalati àti Tadmori ní aginjù, láàrín rẹ̀,
19 and all the store-cities that Solomon had, and cities for chariots, and cities for the horsemen, and that which Solomon desired to build in Jerusalem, and on Lebanon, and in all the land of his dominion.
àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso.
20 All the people that were left of the Amorites, the Hittites, the Perizzites, the Hivites, and the Jebusites, who were not of the children of Israel,
Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Amori ará Hiti, Peresi, Hifi àti Jebusi, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Israẹli,
21 their children that were left after them in the land, whom the children of Israel were not able utterly to destroy, upon them did Solomon impose a tribute of bondservice until this day.
ìyẹn ni pé àwọn ọmọ wọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò le parun pátápátá, àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ẹrú fún títí di òní yìí.
22 But of the children of Israel did Solomon make no bondmen; but they were men of war, and his servants, and his chiefs, and his captains, and captains of his chariots, and his horsemen.
Ṣùgbọ́n, Solomoni kò fi ẹnìkankan ṣe ẹrú nínú àwọn ọmọ Israẹli; àwọn ni ológun rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.
23 These were the chief superintendents that were over Solomon's work, five hundred and fifty, that ruled over the people that wrought in the work.
Àwọn sì tún ni àwọn olórí olùtọ́jú tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ Solomoni, àádọ́ta dín lẹ́gbẹ̀ta, ní ń ṣe àkóso lórí àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ náà.
24 But Pharaoh's daughter came up out of the city of David to her house which he had built for her: then he built Millo.
Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Farao ti gòkè láti ìlú Dafidi wá sí ààfin tí Solomoni kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Millo.
25 And three times in the year did Solomon offer up burnt-offerings and peace-offerings upon the altar that he had built to Jehovah, and he burned incense upon that which was before Jehovah. So he finished the house.
Nígbà mẹ́ta lọ́dún ni Solomoni ń rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà lórí pẹpẹ tí ó tẹ́ fún Olúwa, ó sì sun tùràrí níwájú Olúwa pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó parí ilé náà.
26 And king Solomon made a fleet of ships in Ezion-Geber, which is beside Eloth, on the shore of the Red Sea, in the land of Edom.
Solomoni ọba sì túnṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Geberi, tí ó wà ní ẹ̀bá Elati ní Edomu, létí Òkun Pupa.
27 And Hiram sent in the fleet his servants, shipmen that had knowledge of the sea, with the servants of Solomon;
Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni.
28 and they went to Ophir, and fetched thence gold, four hundred and twenty talents, and brought it to king Solomon.
Wọ́n sì dé Ofiri, wọ́n sì mú irinwó ó lé ogún tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba.