< 1 Chronicles 14 >
1 And Hiram king of Tyre sent messengers to David, and timber of cedars, with masons and carpenters, to build him a house.
Nísinsin yìí Hiramu àti ọba Tire rán oníṣẹ́ sí Dafidi, àti pẹ̀lú igi kedari pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un.
2 And David perceived that Jehovah had established him king over Israel, for his kingdom was highly exalted, because of his people Israel.
Dafidi sì mọ Israẹli àti pé Olúwa ti fi òun ṣe ọba lórí Israẹli àti pé ìjọba rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwọn ènìyàn rẹ̀.
3 And David took more wives at Jerusalem: and David begot more sons and daughters.
Ní Jerusalẹmu Dafidi mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di baba àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin.
4 And these are the names of the children which he had in Jerusalem: Shammua, and Shobab, Nathan, and Solomon,
Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣammua, Ṣobabu, Natani, Solomoni,
5 and Ibhar, and Elishua, and Elpelet,
Ibhari, Eliṣua, Elifeleti,
6 and Nogah, and Nepheg, and Japhia,
Noga, Nefegi, Jafia,
7 and Elishama, and Beeliada, and Eliphelet.
Eliṣama, Beeliada, àti Elifeleti.
8 And the Philistines heard that David was anointed king over all Israel, and all the Philistines went up to seek David; and David heard [of it], and went out against them.
Nígbà tí àwọn ará Filistini gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dafidi ní ọba lórí gbogbo Israẹli, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn.
9 And the Philistines came and spread themselves in the valley of Rephaim.
Nísinsin yìí àwọn ará Filistini ti wá láti gbógun ti àfonífojì Refaimu;
10 And David inquired of God saying, Shall I go up against the Philistines, and wilt thou give them into my hand? And Jehovah said to him, Go up; and I will give them into thy hand.
Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé, “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Filistini lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Olúwa sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”
11 And they came up to Baal-perazim, and David smote them there; and David said, God has broken in upon mine enemies by my hand, as the breaking forth of waters. Therefore they called the name of that place Baal-perazim.
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Perasimu, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n. Ó sí wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dafidi lórí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀lú ọwọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Perasimu.
12 And they left their gods there; and David commanded, and they were burned with fire.
Àwọn ará Filistini sì ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀. Dafidi sì pa á láṣẹ láti jó wọn nínú iná.
13 And the Philistines yet again spread themselves in the valley.
Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn ará Filistini gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì,
14 And David inquired again of God; and God said to him, Go not up after them; turn round them and come upon them opposite the mulberry-trees.
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì tún béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, “Má ṣe gòkè tààrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká, kí ẹ sì mú wọn níwájú igi muliberi.
15 And it shall be, when thou hearest the sound of marching in the tops of the mulberry-trees, that then thou shalt go out to battle; for God will have gone forth before thee to smite the army of the Philistines.
Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró ẹsẹ̀ ní orí òkè igi muliberi, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fihàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini.”
16 And David did as God commanded him; and they smote the army of the Philistines from Gibeon even to Gezer.
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini láti gbogbo ọ̀nà Gibeoni lọ sí Geseri.
17 And the fame of David went out into all lands; and Jehovah brought the fear of him upon all the nations.
Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dafidi tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, Olúwa sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè bẹ̀rù rẹ̀.