< Leviticus 17 >
1 And the Lord spoke to Moses, saying:
Olúwa sọ fún Mose pé,
2 Speak to Aaron and his sons, and to all the sons of Israel, saying to them: This is the word, which the Lord has commanded, saying:
“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: ‘Ohun tí Olúwa pàṣẹ nìyí,
3 Any man at all of the house of Israel, if he will have killed an ox, or a sheep, or a goat in the camp or beyond the camp,
bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Israẹli bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́-àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó
4 and not have presented it as an oblation to the Lord at the door of the tabernacle, he shall be guilty of blood. It is just as if he had shed blood; so then, he shall perish from the midst of his people.
tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa níwájú àgọ́ ìpàdé, ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
5 Therefore, the sons of Israel must offer to the priest their victims, which they kill in the field, so that they may be sanctified to the Lord before the door of the tabernacle of the testimony, and so that they may immolate them as peace offerings to the Lord.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Israẹli le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú Olúwa: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá síwájú àlùfáà àní sí Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa.
6 And the priest shall pour the blood upon the altar of the Lord, at the door of the tabernacle of the testimony, and he shall burn the fat as a sweet odor to the Lord.
Àlùfáà náà yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n ibi pẹpẹ Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, yóò sì sun ọ̀rá rẹ̀ ní òórùn dídùn sí Olúwa.
7 And they shall no longer immolate their victims to demons, with whom they have committed fornication. It shall be an everlasting ordinance for them and for their posterity.
Nítorí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbèrè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.’
8 And you shall say to them: The man of the house of Israel, or of the newcomers who sojourn with you, who offers a holocaust or a victim,
“Kí ó sọ fún wọn pé, ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Israẹli tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn tí ó bá rú ẹbọ sísun tàbí ṣe ẹbọ
9 and who does not bring it to the door of the tabernacle of the testimony, so that it may be offered to the Lord, shall pass away from his people.
tí kò sì mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
10 Any man at all of the house of Israel, or of the newcomers who sojourn among them, if he has eaten blood, I will harden my face against his soul, and I will drive him from his people.
“‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn, Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
11 For the life of the flesh is in the blood, and I have given it to you, so that you may atone with it upon the altar for your souls, and so that the blood may be for an expiation of the soul.
Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà, èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn.
12 For this reason, I have said to the sons of Israel: No soul among you shall eat blood, nor among the newcomers who sojourn with you.
Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ọ̀kankan nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àlejò kan tí ń ṣe àtìpó nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.
13 Any man at all from the sons of Israel, or from the newcomers who sojourn with you, whether by hunting or bird-catching, if he seizes a wild beast or a bird, which is lawful to eat, let him pour out its blood and cover the earth with it.
“‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé láàrín wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀.
14 For the life of all flesh is in the blood. Therefore, I said to the sons of Israel: You shall not eat the blood of any flesh at all, because the life of the flesh is in the blood, and whoever has eaten it shall perish.
Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan, torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.
15 The soul who eats what has died on its own, or what has been caught by a beast, whether he is native born or a newcomer, shall wash his clothes and himself with water, and he shall be contaminated until evening. And by this means he shall be made clean.
“‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnra rẹ̀, tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò, ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́.
16 But if he will not wash his clothes and his body, he shall bear his iniquity.
Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ̀ láti wẹ ara rẹ̀ tí kò sì fọ aṣọ rẹ̀ náà: ẹ̀bi rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀.’”