< Daniel 4 >
1 King Nabuchodonosor to all nations, tribes, and tongues, who dwell in all the earth; Peace be multiplied to you.
Nebukadnessari ọba, sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé. Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín. Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀!
2 It seemed good to me to declare to you the signs and wonders which the most high God has wrought with me,
Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ àmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá-Ògo ti ṣe fún mi hàn.
3 how great and mighty [they are]: his kingdom is an everlasting kingdom, and his power to all generations.
Báwo ni àmì rẹ̀ ti tóbi tó,
4 I Nabuchodonosor was thriving in my house, and prospering.
Èmi Nebukadnessari wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà.
5 I saw a vision, and it terrified me, and I was troubled on my bed, and the visions of my head troubled me.
Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rùbà mí.
6 And I made a decree to bring in before me all the wise men of Babylon, that they might make known to me the interpretation of the dream.
Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Babeli wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.
7 So the enchanters, magicians, soothsayers, [and] Chaldeans came in: and I told the dream before them; but they did not make known to me the interpretation thereof;
Nígbà tí àwọn apidán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.
8 until Daniel came, whose name is Baltasar, according to the name of my God, who has within him the Holy Spirit of God; to whom I said,
Ní ìkẹyìn Daniẹli wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún. (Ẹni tí à ń pè ní Belṣassari gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ̀.)
9 O Baltasar, chief of the enchanters, of whom I know that the Holy Spirit of God is in thee, and no mystery is too hard for thee, hear the vision of my dream which I had, and tell me the interpretation of it.
Mo wí pé, “Belṣassari, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì ṣí àṣírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi.
10 I had a vision upon my bed; and behold a tree in the midst of the earth, and its height was great.
Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrín ayé, igi náà ga gidigidi.
11 The tree grew large and strong, and its height reached to the sky, and its extent to the extremity of the whole earth:
Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé.
12 its leaves were fair, and its fruit abundant, and in it was meat for all; and under it the wild beasts of the field took shelter, and the birds of the sky lodged in the branches of it, and all flesh was fed of it.
Ewé rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ka rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.
13 I beheld in the night vision upon my bed, and, behold, a watcher and an holy one came down from heaven, and cried aloud, and thus he said,
“Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró síwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run
14 Cut down the tree, and pluck off its branches, and shake off its leaves, and scatter its fruit: let the wild beasts be removed from under it, and the birds from its branches.
ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èso rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.
15 Only leave the stump of its roots in the earth, and [bind it] with an iron and brass band; and it shall lie in the grass that is without and in the dew of heaven, and its portion [shall be] with the wild beasts in the grass of the field.
Ṣùgbọ́n fi kùkùté àti gbòǹgbò rẹ̀ tí a fi irin àti idẹ dè ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ àti sí orí koríko igbó. “‘Jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i lára, kí ó sì jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó láàrín ilẹ̀ ayé.
16 His heart shall be changed from that of man, and the heart of a wild beast shall be given to him; and seven times shall pass over him.
Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.
17 The matter is by the decree of the watcher, and the demand is a word of the holy ones; that the living may know that the Lord is most high [over] the kingdom of men, and he will give it to whomsoever he shall please, and will set up over it that which is set at nought of men.
“‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’
18 This is the vision which I king Nabuchodonosor saw: and do thou, Baltasar, declare the interpretation, for none of the wise men of my kingdom are able to shew me the interpretation of it: but thou, Daniel, art able; for the Holy Spirit of God is in thee.
“Èyí ni àlá tí èmi Nebukadnessari ọba lá. Ní ìsinsin yìí ìwọ Belṣassari, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú rẹ.”
19 Then Daniel, whose name is Baltasar, was amazed about one hour, and his thoughts troubled him. And Baltasar answered and said, [My] lord, let the dream be to them that hate thee, and the interpretation of it to thine enemies.
Nígbà náà ni Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Belṣassari, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rùbà ọ́.” Belṣassari sì dáhùn wí pé, “Olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí.
20 The tree which thou sawest, that grew large and strong, whose height reached to the sky and its extent to all the earth;
Igi tí ìwọ rí, tí ó dàgbà, tí ó sì lágbára, tí orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run, tí ó lẹ́wà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso, tí ó ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn, tí ó ṣe ààbò lórí ẹranko igbó àti èyí tí ẹ̀ka rẹ̀ pèsè ààyè fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
21 and whose leaves were flourishing, and its fruit abundant, (and it was meat for all; under it the wild beasts lodged, and the birds of the sky took shelter in its branches: )
Èyí tí ewé e rẹ̀ lẹ́wà, tí èso rẹ̀ si pọ̀, nínú èyí tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko igbó ń gbé, lórí ẹ̀ka èyí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní ibùgbé wọn.
22 is thyself, O king; for thou art grown great and powerful, and thy greatness has increased and reached to heaven, and thy dominion to the ends of the earth.
Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.
23 And whereas the king saw a watcher and a holy one coming down from heaven, and he said, Strip the tree, and destroy it; only leave the stump of its roots in the ground, and [bind it] with a band of iron and brass; and it shall lie in the grass that is without, and in the dew of heaven, and its portion shall be with wild beasts, until seven times have passed over it;
“Ìwọ ọba, rí ìránṣẹ́ ẹni mímọ́ kan, tí ó ń bọ̀ láti ọ̀run ó sì sọ pé, ‘Gé igi náà kí o sì run ún, ṣùgbọ́n fi kùkùté rẹ tí a dè pẹ̀lú irin àti idẹ sílẹ̀ nínú koríko igbó, nígbà tí gbòǹgbò rẹ̀ sì wà nínú ilẹ̀ kí o sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sórí i rẹ̀, jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà láàrín ẹranko búburú títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.’
24 this is the interpretation of it, O king, and it is a decree of the Most High, which has come upon my lord the king.
“Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ ọba àti àṣẹ tí Ọ̀gá-ògo mú wá sórí ọba olúwa mi.
25 And they shall drive thee forth from men, and thy dwelling shall be with wild beasts, and they shall feed thee with grass as an ox, and thou shalt have thy lodging under the dew of heaven, and seven times shall pass over thee, until thou know that the Most High is Lord of the kingdom of men, and will give it to whom he shall please.
A ó lé ọ jáde kúrò láàrín ènìyàn, ìwọ yóò sì máa gbé láàrín ẹranko búburú, ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run yóò sì sẹ̀ sára rẹ. Ìgbà méje yóò sì kọjá lórí rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.
26 And whereas they said, Leave the stumps of the roots of the tree; thy kingdom abides [sure] to thee from the time that thou shalt know the power of the heavens.
Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jẹ ọba.
27 Therefore, O king, let my counsel please thee, and atone for thy sins by alms, and [thine] iniquities by compassion on the poor: it may be God will be long-suffering to thy trespasses.
Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn tálákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”
28 All these things came upon king Nabuchodonosor.
Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí Nebukadnessari ọba.
29 After a twelvemonth, as he walked in his palace in Babylon,
Lẹ́yìn oṣù kejìlá, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Babeli,
30 the king answered and said, Is not this great Babylon, which I have built for a royal residence, by the might of my power, for the honour of my glory?
ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Babeli ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”
31 While the word was yet in the king’s mouth, there came a voice from heaven, [saying], To thee, king Nabuchodonosor, they say, The kingdom has departed from thee.
Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run, “Ìwọ Nebukadnessari ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.
32 And they [shall] drive thee from men, and thy dwelling shall be with the wild beasts of the field, and they shall feed thee with grass as an ox: and seven times shall pass over thee, until thou know that the Most High is Lord of the kingdom of men, and he will give it to whomsoever he shall please.
A ó lé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárín àwọn ẹranko igbó; ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.”
33 In the same hour the word was fulfilled upon Nabuchodonosor: and he was driven forth from men, and he ate grass as an ox, and his body was bathed with the dew of heaven, until his hairs were grown like lions’ [hairs], and his nails as birds’ [claws].
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadnessari ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ.
34 And at the end of the time I Nabuchodonosor lifted up mine eyes to heaven, and my reason returned to me, and I blessed the Most High, and praised him that lives for ever, and gave [him] glory; for his dominion is an everlasting dominion, and his kingdom [lasts] to all generations:
Ní òpin ìgbà náà, èmi, Nebukadnessari gbé ojú mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀gá-ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé.
35 and all the inhabitants of the earth are reputed as nothing: and he does according to his will in the army of heaven, and among the inhabitants of the earth: and there is none who shall withstand his power, and say to him, What hast thou done?
Gbogbo àwọn ènìyàn ayé
36 At the same time my reason returned to me, and I came to the honour of my kingdom; and my [natural] form returned to me, and my princes, and my nobles, sought me, and I was established in my kingdom, and more abundant majesty was added to me.
Ní àkókò kan náà, iyè mi padà, ọlá àti ògo dídán mi padà tọ̀ mí wá fún ògo ìjọba mi. Àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn ọlọ́lá mi, wá mi rí, wọ́n sì dá mi padà sórí ìjọba mi, mo sì di alágbára ju ti ìṣáájú lọ.
37 Now therefore I Nabuchodonosor praise and greatly exalt and glorify the King of heaven; for all his works are true, and his paths are judgment: and all that walk in pride he is able to abase.
Báyìí, èmi, Nebukadnessari fi ọpẹ́, mo sì gbé Ọlọ́run ga, mo sì fi ògo fún ọba ọ̀run, nítorí pé gbogbo nǹkan tí ó ṣe ló dára, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì tọ́. Gbogbo àwọn tó sì ń rìn ní ìgbéraga ni ó le rẹ̀ sílẹ̀.