< Leviticus 11 >

1 And the Lord said to Moses and Aaron,
Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
2 Say to the children of Israel: These are the living things which you may have for food among all the beasts on the earth.
“Ẹ sọ fún àwọn ara Israẹli pé, ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ.
3 You may have as food any beast which has a division in the horn of its foot, and whose food comes back into its mouth to be crushed again.
Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.
4 But, at the same time, of those beasts, you may not take for food the camel, because its food comes back but the horn of its foot is not parted in two; it is unclean to you.
“‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátákò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbákasẹ ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátákò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́.
5 And the rock-badger, for the same reason, is unclean to you.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gara (ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta) ń jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.
6 And the hare, because the horn of its foot is not parted in two, is unclean to you.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátákò ẹsẹ̀; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.
7 And the pig is unclean to you, because though the horn of its foot is parted, its food does not come back.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́dẹ̀ ya pátákò ẹsẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.
8 Their flesh may not be used for food, and their dead bodies may not even be touched; they are unclean to you.
Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn. Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.
9 These you may have for food of all things living in the water: anything living in the water, in the seas or rivers, which has special parts for swimming and skin formed of thin plates, may be used for food.
“‘Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá tí ń gbé inú omi Òkun, àti nínú odò: èyíkéyìí tí ó bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ́.
10 All other things living and moving in the water, in the sea or in the rivers, are a disgusting thing to you;
Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrín gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra.
11 They may not be used for food, and their dead bodies are disgusting to you.
Nígbà tí ẹ ti kórìíra wọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn: ẹ gbọdọ̀ kórìíra òkú wọn.
12 Anything in the water which has no special parts for swimming and no thin plates on its skin is disgusting to you.
Ohunkóhun tí ń gbé inú omi tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́ gbọdọ̀ jásí ìríra fún yín.
13 And among birds these are to be disgusting to you, and not to be used for food: the eagle and the gier-eagle and the ospray;
“‘Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n: idì, oríṣìíríṣìí igún,
14 And the kite and the falcon, and birds of that sort;
àwòdì àti onírúurú àṣá,
15 Every raven, and birds of that sort;
onírúurú ẹyẹ ìwò,
16 And the ostrich and the night-hawk and the sea-hawk, and birds of that sort;
Òwìwí, onírúurú ògòǹgò, onírúurú ẹ̀lúùlú, onírúurú àwòdì,
17 And the little owl and the cormorant and the great owl;
Òwìwí kéékèèké, onírúurú òwìwí,
18 And the water-hen and the pelican and the vulture;
Òwìwí funfun àti òwìwí ilẹ̀ pápá, àti àkàlà,
19 The stork and the heron, and birds of that sort, and the hoopoe and the bat.
àkọ̀, onírúurú òòdẹ̀, atọ́ka àti àdán.
20 Every winged four-footed thing which goes on the earth is disgusting to you;
“‘Gbogbo kòkòrò tí ń fò tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn ni wọ́n jẹ́ ìríra fún yín,
21 But of the winged four-footed things, those which have long legs for jumping on the earth you may have for food;
irú àwọn kòkòrò oniyẹ̀ẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le jẹ nìyí, àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìṣẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀.
22 Such as all the different sorts of locust.
Nínú àwọn wọ̀nyí ni ẹ lè jẹ onírúurú eṣú, onírúurú ìrẹ̀ àti onírúurú tata.
23 But all other winged four-footed things which go on the earth are disgusting to you.
Ṣùgbọ́n gbogbo ohun ìyókù tí ń fò, tí ń rákò, tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin, òun ni kí ẹ̀yin kí ó kà sí ìríra fún yín.
24 By these you will be made unclean; anyone touching their dead bodies will be unclean till evening:
“‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
25 Whoever takes away the dead body of one of them is to have his clothing washed, and will be unclean till evening.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
26 Every beast, in the horn of whose foot there is not a complete division, and whose food does not come back, is unclean to you: anyone touching one of these will be unclean.
“‘Àwọn ẹranko tí pátákò wọn kò là tan tàbí tí wọn kò jẹ àpọ̀jẹ jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyìí nínú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́.
27 Any four-footed beast which goes on the ball of its foot, is unclean to you: anyone touching the dead body of one of these will be unclean till evening.
Nínú gbogbo ẹranko tí ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí ń fi èékánná wọn rìn jẹ́ aláìmọ́ fún yín, ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
28 Anyone who takes away the dead body of one of these is to have his clothing washed and be unclean till evening.
Ẹni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Wọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín.
29 And these are unclean to you among things which go low down on the earth; the weasel and the mouse and the great lizard, and animals of that sort;
“‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń rìn lórí ilẹ̀ ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ àìmọ́ fún yín: Asé, eku àti oríṣìíríṣìí aláǹgbá,
30 And the ferret and the land crocodile and the lizard and the sand-lizard and the chameleon.
Ọmọnílé, alágẹmọ, aláǹgbá, ìgbín àti ọ̀gà.
31 All these are unclean to you: anyone touching them when they are dead will be unclean till evening.
Nínú gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ìwọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
32 The dead body of any of these, falling on anything, will make that thing unclean; if it is any vessel of wood, or clothing, or skin, or bag, whatever it is, if it is used for any purpose, it will have to be put into water, and will be unclean till evening; after that it will be clean.
Bí ọ̀kan nínú wọn bá kú tí wọ́n sì bọ́ sórí nǹkan kan, bí ó ti wù kí irú ohun náà wúlò tó, yóò di aláìmọ́ yálà aṣọ ni a fi ṣe é ni tàbí igi, irun aṣọ tàbí àpò, ẹ sọ ọ́ sínú omi yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn náà ni yóò tó di mímọ́.
33 And if one of them gets into any vessel of earth, whatever is in the vessel will be unclean and the vessel will have to be broken.
Bí èyíkéyìí nínú wọn bá bọ́ sínú ìkòkò amọ̀, gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ti di àìmọ́. Ẹ gbọdọ̀ fọ ìkòkò náà.
34 Any food in it, and anything on which water from it comes, will be unclean: any drink taken from such a vessel will be unclean.
Bí omi inú ìkòkò náà bá dà sórí èyíkéyìí nínú oúnjẹ tí ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ náà di aláìmọ́. Gbogbo ohun mímu tí a lè mú jáde láti inú rẹ̀ di àìmọ́.
35 Any part of the dead body of one of these, falling on anything, will make it unclean; if it is an oven or a cooking-pot it will have to be broken: they are unclean and will be unclean to you.
Gbogbo ohun tí èyíkéyìí nínú òkú wọn bá já lé lórí di àìmọ́. Yálà ààrò ni tàbí ìkòkò ìdáná wọn gbọdọ̀ di fífọ́. Wọ́n jẹ́ àìmọ́. Ẹ sì gbọdọ̀ kà wọ́n sí àìmọ́.
36 But at the same time a fountain or a place where water is stored for use will be clean; but anyone touching their dead bodies will be unclean.
Bí òkú wọn bá bọ́ sínú omi tàbí kànga tó ní omi nínú, omi náà kò di aláìmọ́ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá yọ òkú wọn jáde tí ó fi ọwọ́ kàn án yóò di aláìmọ́.
37 If any part of the dead body of one of these gets on to any seed for planting, it is clean;
Bí òkú ẹranko wọ̀nyí bá bọ́ sórí ohun ọ̀gbìn tí ẹ fẹ́ gbìn wọ́n sì jẹ́ mímọ́.
38 But if water is put on the seed, and any part of the dead body gets on to it, it will be unclean to you.
Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ti da omi sí ohun ọ̀gbìn náà tí òkú wọn sì bọ́ sí orí rẹ̀ àìmọ́ ni èyí fún un yín.
39 And if any beast which may be used for food comes to a natural death, anyone touching its dead body will be unclean till evening.
“‘Bí ẹran kan bá kú nínú àwọn tí ẹ lè jẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú rẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
40 And he who makes use of any part of its body for food is to have his clothing washed and be unclean till evening; and anyone taking away its body is to have his clothing washed and be unclean till evening.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èyíkéyìí nínú òkú ẹranko náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú ẹranko yóò fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wà ní àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
41 Everything which goes flat on its body on the earth is disgusting, and is not to be used for food.
“‘Ìríra ni gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n.
42 Whatever goes on its stomach or on four feet or has a great number of feet, even all those going flat on the earth, may not be used for food, for they are disgusting.
Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ń rìn ká orí ilẹ̀ yálà ó ń fàyàfà tàbí ó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, tàbí ó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ̀ rìn ìríra ni èyí.
43 You are not to make yourselves disgusting with anything which goes about flat on the earth; you may not make yourselves unclean with them, in such a way that you are not holy to me.
Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi ohun kan tí ń rákò, sọ ara yín di ìríra, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi wọ́n sọ ara yín di aláìmọ́, tí ẹ̀yin yóò fi ti ipa wọn di eléèérí.
44 For I am the Lord your God: for this reason, make and keep yourselves holy, for I am holy; you are not to make yourselves unclean with any sort of thing which goes about flat on the earth.
Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀.
45 For I am the Lord, who took you out of the land of Egypt, to be your God; so be you holy, for I am holy.
Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.
46 This is the law about beasts and birds and every living thing moving in the waters, and every living thing which goes flat on the earth:
“‘Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹranko, ẹyẹ, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi àti àwọn ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀.
47 Marking out the unclean from the clean, and the living thing which may be used for food from that which may not.
Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín àìmọ́ àti mímọ́ láàrín ẹ̀dá alààyè, tí ẹ le jẹ àti èyí tí ẹ kò le jẹ.’”

< Leviticus 11 >