< Psalms 64 >
1 For the choirmaster. A Psalm of David. Hear, O God, my voice of complaint; preserve my life from dread of the enemy.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.
2 Hide me from the scheming of the wicked, from the mob of workers of iniquity,
Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
3 who sharpen their tongues like swords and aim their bitter words like arrows,
Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà, wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
4 ambushing the innocent in seclusion, shooting suddenly, without fear.
Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀: wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.
5 They hold fast to their evil purpose; they speak of hiding their snares. “Who will see them?” they say.
Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú, wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
6 They devise injustice and say, “We have perfected a secret plan.” For the inner man and the heart are mysterious.
Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé, “A wa ti parí èrò tí a gbà tán!” Lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.
7 But God will shoot them with arrows; suddenly they will be wounded.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà; wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
8 They will be made to stumble, their own tongues turned against them. All who see will shake their heads.
Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n, gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
9 Then all mankind will fear and proclaim the work of God; so they will ponder what He has done.
Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.
10 Let the righteous rejoice in the LORD and take refuge in Him; let all the upright in heart exult.
Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀. Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.